Kò dín ní èèyàn 124 tó ti kú, lẹ́yìn tí òrùlé ilé ìgbafẹ́ Jet Set Club, já lulẹ̀
- Author, Vanessa Buschschlüter
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ogunlọgọ awọn oṣiṣẹ pajawiri ni wọn ti ko si iṣẹ lati wa awọn to ṣe e ṣe ki wọn ma ti i ku ninu iṣẹlẹ orule ile faaji alẹ kan to ya lulẹ ni Dominican Republic, eyi to pa ọpọ eeyan ti wọn tun ni onka awọn oku naa si n pọ si i.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni iṣẹlẹ naa waye ni ile faaji ọhun ti wọn pe ni Jet Set club, to wa ni olu-ilu orilẹ-ede naa, Santo Domingo.
O kere tan, eeyan mẹrinlelọgọfa (124) ni awọn alaṣẹ sọ pe o ti ku ninu ijamba yii.
Aadọjọ eeyan (150) ni wọn lo tun farapa nigba ti orule ile faaji alẹ naa ya ni nnkan bii aago mẹfa idaji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olori ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, Juan Manuel Méndez, sọ pe awọn ko ni ju wakati mẹrinlelogun si mẹtadinlogoji lọ lati wa awọn to ṣee ṣe ki wọn ṣi wa labẹ ile naa.
Nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ, o le lọgọrun-un eeyan to n ṣe faaji lọwọ ninu gbajugbaja ile ọti naa, elere merengue kan ti wọn pe ni Rubby Pérez lo n ṣere fun wọn lọwọ.
Wọ́n ti kéde ikú àwọn èèyàn kan
Lára awọn eeyan ti wọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ti ku ninu iṣẹlẹ yii ni Pérez, Octavio Dotel to jẹ gbajugbaja agbabọọlu ọlọwọ nigba kan ati Tony Blanco, bakan naa ni wọn kede iku gomina ẹkun kan.
Ninu fidio kan ti wọn fi foonu ya ninu ile faaji naa, eyi ti BBC fidi ẹ mulẹ, ni a ti ri Pérez lori itage to n kọrin,nigba ti ọkunrin to n ya fidio naa n ṣorọ.
"Nnkan kan jabọ lati ori aja", ọkunrin to n ya fidio naa lo n sọ bẹẹ, o si n naka si ori orule naa.
Bakan naa la ri Pérez toun naa n wo apa ibi ti ọkunrin naa n tọka si .
Ko to iṣẹju aaya ọgbọn si asiko naa ti wọn fi gbọ ariwo nla kan, bẹẹ ni fidio ti ọkunrin naa n ka silẹ pari lojiji. Lẹyin eyi ni a gbọ ohun obinrin kan to n sọ pe "Baba, ki lo ṣẹlẹ si yin?".
Àwọn ẹbí ń káyà sókè láti gbọ́ nípa àwón èèyan wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ẹbi ti eeyan wọn ti di awati lẹyin iṣẹlẹ yii ko kuro nibẹ, wọn n ṣe iṣọ oru nibẹ pẹlu ibanujẹ ni.
Lara awọn eeyan naa ni ọmọbinrin Pérez', Zulinka, ẹni to n gbe orin lẹyin baba rẹ ṣiwaju ijamba yii.
O ṣalaye pe oun wa lori itage lọwọ, oun n kọrin pẹlu baba oun ni ki orule too da wo lulẹ
Zulinka sọ pe ọkọ oun lo gba oun naa silẹ, ọkunrin naa lo ni o fi ara rẹ bo oun mọlẹ. O lo sọ foun pe oun ko gbọdọ ku, koun le wa laye lati maa tọju ọmọkunrin tawọn bi.
Zulinka loun dọgbọn jade labẹ orule naa, ọkọ oun naa si jade laaye.
Ṣugbọn baba rẹ, ẹni ọdun mọkandinlaadọrin, wa labẹ orule to wo naa fun ọpọlọpọ wakati.
Gẹgẹ bi alaye Zulinka, o ni baba oun ko ku lẹsẹkẹsẹ.
"Wọn ba a to n kọrin lọwọ ni, o bẹrẹ si i kọrin ki wọn le gbọ ọ ki wọn si mọ ibi to wa"
Zulinka lo ṣalaye bẹẹ fun ẹka iroyin abẹle kan.
Ṣugbọn ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ, wọn pe Zulinka pe baba rẹ ti ku ki wọn too ri i gbe jade.
Maneja rẹ naa pada fidi iku olorin, Rubby Pérez, mulẹ.
Ko ti i ṣee sọ pato pe iye eeyan bayii lo wa ninu ile faaji yii lasiko ti ijamba naa ṣẹlẹ, ṣugbọn onka ti wọn foju sun wa laaarin ẹẹdẹgbẹta si ẹgbẹrun kan eeyan( 500-1,000).
Akọwe ijọba US, Marco Rubio, fidi ẹ mulẹ loju opo X, pe o kere tan, ọmọ ilẹ America kan ati awọn olugbe ilu naa to ti ni iwe igbeluu titi lae, wa ninu awọn to ku ninu ijamba orule naa.
O ni oun ati iyawo oun, Jeanette, ti bẹrẹ si i gbadura, orilẹede America si ti ṣetan lati ti awọn Dominican lẹyin lasiko iṣoro yii.
Ni bayii, awọn oṣiṣẹ alaabo ti wo apa kan ile faaji naa, ki wọn le raye ri awọn ti orule ọhun ya bo mọlẹ.
Kò tí ì sẹ́ni tó mọ ohun tó fa òrùlé tó ya náà

Oríṣun àwòrán, Shutterstock
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ ohun to fa orule ile faaji to wo le awọn eeyan lori naa.
Tẹlẹ, ilee fiimu ti wọn ti n wo sinima ni wọn fi ibẹ ṣe, ki wọn too yi i pada silee faaji ti awọn eeyan maa n jo nibẹ ni gbogbo alẹ ọjọ Mọnde.
Awọn olorin to wa n kọrin nibẹ yii maa n mu ọpọ eeyan wa sibẹ, lọjọ ti orule ya yii, ọpọ elere idaraya, alafẹ ati awọn oloṣelu ni wọn kun ibẹ.
Lati daro iku awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, Aarẹ Abinader, ti kede akoko ikẹdun ọlọjọ mẹta kaakiri ilu naa.















