Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìwọ́de tako agbẹjọ́rò àgbà l'Ondo, wọ́n ló fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́

Ariwo sọ niluu Akure nibi ti awọn akẹkọọ nipinlẹ Ondo labẹ iṣakoso ẹgbẹ NANS ti ṣe ifehonuhan tako Kọmisọna feto idajọ ni ipinlẹ naa, Kayode Ajulo, lori ẹsun pe o ju akẹgbẹ wọn mẹta sẹwọn.
Awọn oluwọde naa kọkọ lọ si ofiisi Kọmisọna ọhun nibi ti wọn ti kọ oniruuru orin lati fẹhonu han pe iwa ko tọ ni amofinAjulo hu si awọn ọdọ naa.
Awọn olufehonuhan naa ni wọn wa lati gbogbo awọn ile-ekọ giga mẹsan to wa ni Ipinlẹ Ondo to fi mọ okan o jọkan ẹgbẹ awọn ọdọ nipinlẹ naa.
Awọn akẹkọọ naa sọ pe wọn ko ni kuro nibi iwọde naa titi ti Ajulo yoo fi tu awọn eniyan naa silẹ.
Awọn akẹkọọ mẹta ti wọn ti mọ ọgba ewọn naa ni Blessing Akeju, Yaya Oluwabusolami, ati Adeniran Adesunloye.
Lasiko to n ba awọn ọdọ naa sọrọ, Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Wilfred Afolabi, ṣe ileri pe wọn yoo tu awọn ọdọ naa silẹ laipẹ.
Kọmisọna naa seleri pe oun yoo ri daju pe gbogbo ohun ti awọn akẹkọọ ọhun n beere fun ni yoo wa si imuṣẹ.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Ọkan lara awọn igbimọ to n sakoso ẹgbẹ awọn ọdọ agbegbe Akoko, Oladimeji Adewumi, sọ fun BBC Yoruba pe, ẹgbẹ naa nilo lati se eto kan lagbegbeọhun lo jẹ ki wọn kan si Kayode Ajulo fun iranlọwọ.
O salaye pe wọn gbe eto naa kalẹ lati se eto ironi l'agbara fun awọn ọdọ agbegbe naa lati le se iranwọ fun awọn to ku diẹ kato fun un.
Adewumi sọ pe lasiko ti wọn de ọdọ Ajulo fun iranwọ, ṣe ni o tabuku awọn to si pe wọn ni onijibiti to fẹ wa gba owo lọwọ ohun lọna aitọ.


O salaye siwaju si i pe ọrọ naa ba ẹgbẹ wọn lorukọ jẹ, idi rẹ lo si jẹ ki wọn gbe igbesẹ lati salaye lori ẹrọ ayelujara pe orukọ ti kọmisọna eto idajọ pe wọn jẹ eyi to tabuku orukọ wọn.
O ni lẹyin eyi ni Ajulo fi ajọ DSS mu awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ko to di pe awọn ọlọpaa tan wọn wa siluu Akure lati gbe wọn lọ si ile-ẹjọ.
Adewumi sọ pe ile-ẹjọ naa kede pe ki wọn ko awọn mẹtẹẹta lọ si ọgba ewọn olokuta titi di ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹrin, eyi to jẹ ọjọ ijoko miran.















