Ọkọ dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí owó tó ná lójú agbo lọ́jọ́ ìgbeyàwó rẹ̀

Abdullahi Musa Huseini, ọkọ iyawo to dero ewọn

Oríṣun àwòrán, OFFICIAL EFCC/X

Àkọlé àwòrán, Abdullahi Musa Huseini, ọkọ iyawo to dero ewọn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ohun to bẹrẹ pẹlu ayọ ti yọri si ibanujẹ fun ọkọ iyawo kan, Abdullahi Musa Huseini, ẹni ti ile-ẹjọ ti ju u sẹwọn oṣu mẹfa bayii, latari bo ṣe fabuku kan naira lọjọ ayẹyẹ igbeyawo rẹ.

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kano ni wọn ti gbọ ẹjọ Abdullahi laipẹ yii.

Adajọ S.M Shuaibu, beere lọwọ rẹ pe ṣe o jẹbi fifi abuku kan naira ti ajọ EFCC to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku fi kan an.

Nigba to n dahun ibeere naa, ọkọ iyawo to n ṣiṣẹ aṣaralọṣọọ (Makeup artist) sọ pe oun jẹbi.

Bẹẹ ni Adajọ ṣe ran an lẹwọn oṣu mẹfa lai fi aaye owo itanran silẹ fun un.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?

Ninu atẹjade kan ti ajọ EFCC fi sita lọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kẹrin 2025, wọn ṣalaye pe nigba ti Abdullahi Musa Huseini n ṣegbeyawo lọjọ kẹfa, oṣu Kejila ọdun 2024, o na naira lọna to lodi si ofin Naijiria.

Iwe ẹsun ti kootu ka si ọkọ iyawo naa lẹsẹ ka bayii pe:

"Iwọ, Abdullahi Musa Huseini, lọjọ kẹfa, oṣu Kejila ọdun 2024, nibudo ayẹyẹ Ali Jita to wa ni Kano, nigba to o n jo lasiko ayẹyẹ, tapa si ofin to de ofin Banki apapọ Naijiria nipa nina ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira ti ikọọkan re jẹ ẹgbẹrun kan. Fun idi eyi, o huha to tapa to si ni ijiya ninu si abala ofin kọkanlelogun ofin Banki Agba Naijiria ti wọn ṣe ni 2007"

Iroyin sọ pe ọwọ ba Abdullahi lẹyin ti olobo iṣẹlẹ naa ta EFCC pẹlu ẹri to daju.

"Iiwadii tun fidi ẹ mulẹ, pe yatọ si bi ọkọ iyawo yii ṣe nawo loju agbo, o tun mọ ọn mọ ba oju owo naa jẹ, lodi si ikede ati ikilọ EFCC"

EFCC lo kọ ọ bẹẹ loju opo X.

Aṣoju ijọba lori ẹjọ naa, Zarami Mohammed, fi awọn ẹri ọrọ yii mulẹ niwaju Adajọ Shuaibu.

Nigba ti olujẹjọ paapaa n fesi, o ni oun jẹbi.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Shuaibu sọ pe Abdullahi Musa Huseini jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o paṣẹ pe ko lọọ ṣe ẹwọn oṣu mẹfa.

Adajọ ko fi aaye owo itanran kankan silẹ fun un.

Wo àwọn èèyàn ńlá tí wọ́n ti jẹ́jọ́ nípa ṣíṣe náírà báṣubá̀ṣu

Simi Gold, Bobrisky ati Cubana Chief Priest ti wọn ti jẹjọ lorii ṣiṣe fifi abuku kan naira

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Awọn ti wọn ti jẹjọ lori ṣiṣe naira baṣubasu ni Naijiria
  • Oluwadarasimi Omoseyin

Oṣere tiata ni obinrin yii, Simi Gold ni wọn mọ ọn si lagbo oṣere.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu Keji ọdun 2024 ni kootu ju u si ẹwọn osu mẹfa.

Ẹsun ti won fi kan an ni pe o na naira loju agbo o si tun tẹ awọn owo naa mọlẹ lode ariya kan nipinlẹ Eko.

  • Bobrisky

Idris Okuneye gan-an lorukọ ẹ, bo tilẹ jẹ pe Bobrisky ni gbogbo aye mọ ọn si.

Ọkunrin to maa n ṣe bii obinrin yii, bọ sọwọ ofin Naijiria lọjọ kejila, oṣu Kẹrin ọdun 2024.

Ijọba fi ẹsun kan an pe o ṣe owo naira baṣubaṣu lode ariya, ẹwọn oṣu mẹfa ti ko ni owo itanran ninu lo si pada gbẹyin ọrọ naa fun un.

  • Cubana Chief Priest

Jayejaye ati oniṣowo nla ni Cubana Chief Priest ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Pascal Okechukwu.

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin ọdun 2024, o di ero kootu lori ẹsun pe o da owo naira si afẹfẹ lode ariya.

Ṣugbọn Cubana loun ko jẹbi ẹsun naa, Adajọ si fun ni beeli pẹlu miliọnu mẹwaa naira ati oniduuro meji niye kan naa.