Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ikú èèyàn mẹ́ta tí wọ́n rí láì ní orí nínú odò kan l'Ondo

Awọn oṣiṣẹ alaabo to n gbe oku

Oríṣun àwòrán, Environmental Health Officers Alliance

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo si n tẹsiwaju lori oku eeyan mẹta ti wọn ri ninu odo kan laarin ilu Ore ati Odigbo eyi ti ko si ori lara wọn mọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣee ṣe ko jẹ wi pe lati ibomiran lawọn eeyan kan ti gbe oku awọn eeyan naa wa ju sinu odo nipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ yii ti mu ibẹru ba awọn olugbe agbegbe ti wọn ti ri oku awọn eeyan mẹta naa.

Ninu atẹjade ti o fi sita, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Olayinka Alayande, sọ pe lati igba tawọn ti ri awọn oku naa, ko si ẹni to tii wa sọ fawọn ọlọpaa pe eeyan awọn kankan sọnu.

Bakan naa ni Ọgbẹni Alayande sọ pe ko si ẹni to tii wa si agọ ọlọpaa fun idanimọ awọn oku naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣalaye pe awọn ti ranṣẹ pe awọn olori awujọ wi pe ki wọn ṣe iranwọ lori idanimọ oku awọn eeyan naa, amọ, wọn o da ọkankan ninu awọn oku ọhun mọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ko awọn oku naa kurọ ninu odo ti wọn wa, wọn si ti ko wọn lọ ile igbokusi ni ile iwosan ijọba to wa ni Ore.

''Ọga ọlọpaa DPO kepe awọn olori awujọ kaakiri ati oniruuru ẹgbẹ lati le ṣe iranwọ lori idanimọ awọn oku eeyan naa.

DPO tun ni ki ẹnikẹni to ba mọ ohun kan tabi omiran nipa iṣẹlẹ naa lọ wo wọn nile igbokusi ti wọn wa.

Amọ, a o tii ri i ki ẹnikankan wa fun idanimọ oku awọn eeyan mẹta ọhun.

Eyi lo jẹ ki awa ọlọpaa gbagbọ pe o ṣee sẹ ko jẹ wi pe awọn eeyan kan lati ibomiran ni wọn wa ju oku awọn eeyan naa sinu odo nipinlẹ Ondo

O si tun ṣee ṣe ko jẹ wi pe omi lo gbe awọn oku naa sinu odo nipinlẹ Ondo,'' alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye.

Ayẹwo si n lọ lọwọ awọn oku mẹta naa - ileeṣẹ ọlọpaa

Aworan Wildred Afolabi

Oríṣun àwòrán, Ondo Police Command/Facebook

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni iṣẹ iwadii ati ayẹwo si n lọ lọwọ awọn oku naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa tun wa rọ araalu papaa julọ ẹnikẹni to ba mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa lati ran ọlọpaa lọwọ pẹlu ohun ti wọn ba mọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ajọ ọlọpaa ko ni kaarẹ nipa pipese abo to peye fawọn eeyan ipinlẹ Ondo.

O fi da araalu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tuṣu de isalẹ koko lori iṣẹlẹ naa.

Ninu ọrọ tiẹ, olori ọdọ kan to pe ara rẹ ni Shileola ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii nnkan to buru jai.

O ni iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun gbọ, eyi lo si jẹ ki oun lọ si sibi tawọn oku naa wa.

Amọ, Shileola ni oun ko da ẹnikankan mọ ninu awọn oku ọhun nigba ti oun de ibẹ.

Awọn iroyin iṣekupani, paapaa lati ọwọ awọn afurasi darandaran, n jade lemọ-lemọ lati ipinlẹ Ondo.

Eyi si mu ki awọn araalu ṣe iwọde lọ si ọfiisi gomina Lucky Aiyedatiwa niluu Akure.