Naijiria fi òfin de ọ̀ja 25 tó n wá láti America, ìjọba America figbe ta

Oríṣun àwòrán, Trump/Tinubu/Meta
Ajọ to n ri si ọrọ idokoowo nilẹ Amẹrika, United States Trade Representative, ti sọ pe inu ijọba ilẹ naa ko dun si bi ijọba Naijiria ṣe fofin de kiko awọn ọja wọle lati ilẹ ọhun.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti wọn fi lede ninu eyii ti wọn ti sọ pe igbesẹ naa ko tọna rara.
Ajọ USTR ni igbesẹ ijọba Naijiria lati fofin de odidi nnkan marundinlọgbọn yoo ṣakoba fun awọn oniṣowo ilẹ Amẹrika to n ko ọja wọ Naijiria.
Atẹjade ọhun ti wọn fi soju opo X ni "Igbesẹ tuntun yii ti bẹgi dina idokoowo fun awọn ileeṣẹ l'Amẹrika to n gbero lati maa taja ni Naijiria."
Awọn ọrọ yii lo n jade lẹyin ọjọ diẹ ti ijọba Amẹrika gbe owo lori iye owo ori awọn ọja to n wọ Amẹrika lati ilẹ okeere.
Kaakiri agbaye, orilẹede to le ni ọgọta ni afikun owo ori tuntun naa kan.
Awọn ọja ti Naijiria fofin de lati Amẹrika
Ijọba sọ pe lara awọn ọja ti Naijiria fofin de ni ohun jijẹ, oogun atawọn ohun mii bii ẹlẹrindodo ati ọtin.
Ṣaaju ni Naijiria ti kọkọ kede pe oun yoo mu adinku ba iye ọja ti wọn n ko wọle lati ilẹ okere latari bi wọn ṣe n ṣẹ owo lati ko awọn ọja naa wọle, eyii to n ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria.
O ni oun ti ni awọn alakalẹ ti yoo ran awọn oniṣowo ilẹ Naijiria lọwọ lati maa pese awọn ohun ti araalu nilo eyii ti yoo din ọja ti wọn n ko wọle ku.
Awọn ọja ti ijọba Naijiria gbẹsẹle lati ilẹ Amẹrika ree:
- Adiyẹ - yala aaye tabi eyii ti wọn ti pa
- Ẹran maalu ati ẹran ẹlẹdẹ
- Ẹyin
- Ṣuga
- Bọta ti wọn fi cocoa ṣe
- Spaghetti
- Tomato inu agolo
- Awọn ẹlẹrindodo ti wọn fi eso ṣe
- Omi inu igo tabi ike
- Simẹnti
- Oogun ilera
- Ajilẹ fun awọn agbẹ
- Ọṣẹ ati ipara
- Oogun ẹfọn
- Aloku taya ọkọ
- Awọn ohun ti wọn n tẹ silẹ ninu ile
- Aloku aṣọ
- Igo ti iwọn rẹ tobi ju 150ml lọ
- Ẹrọ amule tutu
- Ẹrọ amounjẹ tutu
- Aloku ọkọ ayọkẹlẹ ti ọjọ ori rẹ ti ju ọdun mejila lọ
- Kalamu ikọwe, ati bẹẹ lọ












