Trump kéde owó orí tuntun, Naijiria, South Afrika, China àti EU fara gbá a

Oríṣun àwòrán, The White House
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Senior Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump, ti ṣe afikun iye owo ori ti awọn eeyan yoo maa san lori ọja ti wọn ba n ko wọ orilẹede naa bayii.
Ọpọ orilẹede kaakiri agbaye lo fara gba ninu igbesẹ tuntun naa, to fi mọ awọn orilẹede nilẹ adulawọ, lai yọ orilẹede Naijiriasilẹ .
Gẹgẹ bii ikede Trump, gbogbo orilẹede to ba n ko ọja wọ Amẹrika gbọdọ san owo ori ti iye rẹ jẹt kere tan ida 10% iye owo ọja naa.
Trump tun kede afikun owo ori mii ni fun ogun orilẹede ni Afrika lẹyin to fẹsun kan wọn pe wọn ko ṣe daadaa si Amẹrika.
Eyii n tumọ si pe yatọ ti 10% owo ori yii, Naijiria yoo san afikun owo ori 14%, Lesotho yoo san afikun owo ori 50%, Madagascar yoo san afikun owo ori 47%, Mauritius yoo san afikun owo ori 40% nigba ti Bostwana yoo san afikun owo ori 37%.
Kenya, Ghana, Ethiopia, Tanzania, Uganda, Senegal ati Liberia wa lara awọn orilẹede ti owo ori ti wọn yoo maa san ko ni kọja 10% lọ.
Trump ni awọn orilẹede to ku ti owo ori wọn le ni 10% wa lara awọn orilẹede to wu iwa ti ko daa si ilẹ Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, The White House
O ni nitori naa loun ṣe fikun owo ti wọn ki awọn naa le jere iwa ti wọn n wu si Amẹrika.
Nigba to n sọrọ nile ijọba, White House lọjọru, o ni ọpọ awọn ọmọ ilẹ okere lo ti lu Amẹrika ni jibiti eyii ti ijọba oun ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.
Trump ni "O ti le ni aadọta ọdun ti wọn ti n lu awọn eeyan wa to n san owo ori ni jibiti, opin ti de ba irufẹ nnkan bẹẹ bayii."
Nigba to n ṣafihan akọle ti iye owo onikaluku orilẹede yoo jẹ, Trump ni akoko ti to ki ilẹ Amẹrika gba ominira ọrọ aje rẹ kuro lọwọ awọn orilẹede to n jẹ ẹ run.
Lara awọn orilẹede ti Trump sọ pe ko ṣe daadaa si Amẹrika julọ ni South Afrika, China, Japan ati European Union wa.
Gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe awọn orilẹede to ṣẹ Amẹrika, ida 60% ni South Afrika n gba lori ọja to ba wọ ilẹ naa lati Amẹrika.















