Ọmọbìnrin tó ń gbálẹ̀ pẹ̀lú ìyá rẹ̀ lójú pópó l'Eko rí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gbà lọ́wọ́ aláàánú dé fásitì

Aworan iya ati ọmọ to n gbalẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ori ti yoo gbeni, ni i gbeni ko alawoore, bayii ni ọrọ ṣe ri pẹlu ọmọdebinrin kan to n gbalẹ pẹlu iya rẹ niluu Eko eyi ti fidio rẹ ti lu ori ayelujara pa.

Fidio ọhun lori ayelujara lo ṣafihan obinrin kan ati ọmọdebinrin rẹ nibi ti wọn ti n gbalẹ ni idaji niwaju ile kan lagbegbe Ikoyi niluu Eko.

Ninu fidio naa, eyi ti gbajugbaja ajafẹtọọ n ni, Adetoun Onajobi fi lede lori itakun ayelujara, ni o ti n beere oniruuru ibeere lọwọ iya ọmọ yii nibi ti wọn ti n gbalẹ lati le r'ówó jẹun.

"Ọmọdebinrin yii le máa gbalẹ nílé ti wọn n gbe, ṣugbọn iwa mimu ọmọde sin ni ki o maa lọ gbalẹ nita pẹlu mama rẹ"

Níbẹ ni obìnrin naa ti ṣalaye pe lati agbegbe Iyana Oworo loun ati ọmọ oun ti máa n ji wa gbalẹ ni Ikoyi laaraarọ.

Bayii ni Adetoun kìlọ fun obinrin naa wí pe ko gbọdọ mu ọmọ rẹ lẹyin wa gbalẹ mọ tori o lodi sofin.

Adetoun ni ọmọdebinrin yii le máa gbalẹ nílé ti wọn n gbe, ṣugbọn iwa mimu ọmọde sin ni ki o maa lọ gbalẹ nita pẹlu mama rẹ.

Adetoun ko ṣe meni, ko ṣe meji, o ni ki ọmọ yii ju igbalẹ ọwọ rẹ sílẹ kí o si lọ jokoo.

Lati igba ti fidio naa ti dori itakun ayelujara lawọn eeyan ti n sọ ero wọn lori rẹ.

Mo ṣetan lati ran ọmọdebinrin to n gbalẹ lọ ile ẹkọ titi de fasiti - Tunde Onakoya

Lára awọn to ti sọ ero wọn lori fidio to ṣafihan bi ọmọdebinrin naa ṣe n gbalẹ pẹlu iya rẹ ni alẹnulọrọ lori ayelujara, Tunde Onakoya, wa.

Tunde Onakoya yii lo jẹ gbajumọ elere idaraya ati Olukọni fun ayo Chess, to si ti gba ami ẹyẹ ọlọwọ ayo Chess to dantọ julọ yika agbaye.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Tunde bu ẹnu ẹtẹ lu bi Adetoun Onajobi ṣe n beere oriṣiiriṣii ibeere lọwọ iya ọmọ yii, ti o si tun gbe fidio rẹ sori ayelujara.

O ni eyi jẹ nnkan to tabuku obinrin naa.

Ọgbẹni Onakoya wa ṣèlérí lati fun ọmọdebinrin yii ni eto ẹkọ ọfẹ titi ti yoo jade ni ile ẹkọ giga fasiti.

Tunde Onakoya ni oun ṣe eyi lati ran iya ọmọ naa lẹru ni nitori bi ìlú o ṣe fararọ lasiko yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

"O maa n dun mi pe n ko lowo ti mo le fun maami, kí o le da iṣẹ idọti to n ṣe duro"

Nígbà to n sọ iriri ti ara rẹ gan an, Tunde ni "iya mi naa maa n gbalẹ kaakiri tẹlẹ, koda, iya mi máa n ko gọta lọdun 2016.

O maa n dun mi nigba naa pe n ko lowo ti mo le fun maami kí o le da iṣẹ idọti to n ṣe naa duro.

Koda, ni gbogbo igba ni mo máa n ba mama mi lọ síbi iṣẹ ọhun lati le ràn an lọwọ kí iṣẹ naa maa ba pẹ ju, ki a si le tete pada sile ki ilẹ to mọ dáadáa.

N kii fẹ ki ẹnikẹni ri wa nibi ti a ti n ṣiṣẹ yii.

Ibanujẹ nla ni oṣi ati iṣẹ to mu ki eeyan maa sapamọ ninu okunkun jẹ."

Tunde ni loootọ, ko yẹ kí ọmọdebinrin naa maa ṣe iru iṣẹ bẹẹ, amọ, o sọ pe aanu ni ọmọ yii ati iya rẹ nilo kii ṣe bi ọpọ ṣe n tabuku obinrin naa.