Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ lórí ìwọ́de láti yọ ààrẹ ilẹ̀ Zimbabwe torí pé ìlú le

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọrọ ti bẹyin yọ lori iwọde to yẹ ko waye yika orilẹede Zimbabwe eyi ti wọn fi n wa eekanna mọ aarẹ orilẹede naa, Emmerson Mnangagwa lọrun, pe ko kọwe fipo silẹ.
Nibayii, se ni ọpọ ọmọ orilẹede naa gba lati joko sile dipo ki wọn bọ soju popo lati se iwọde naa, tori bi awọn agbofinro ti oju wọn ko rẹrin se kun igboro.
Ẹtahoro awọn oluwọde lo kopa ninu iwọde ti wọn n gbero yika orilẹede naa, eyi ti ẹgbẹ awọn ajagunfẹyinti tinu n bi kede rẹ.
Awọn Ajagunfẹyinti naa lo n naka aleebu si aarẹ Mnangagwa pe o n jẹ ajẹbanu, to si tun fẹ fi tipa di ipo agbara mu fun igba pipẹ.
"Ọpọ fidio kun nipa bawọn ọlọpaa se n lo afẹfẹ tajutaju lati tu awọn ero to n se iwọde ka"
Amọ awọn Ọlọpaa lo tu wọn ka nibi iwọde naa.
Aarẹ Mnangagwa lo di aarẹ orilẹede Zimbabwe lọdun 2017 lẹyin iditẹ gbajọba ti wọn fi rọ aarẹ Robert Mugabe loye, saa keji rẹ nipo sir ee.
Geza, ẹni to fẹ ki igbakeji aarẹ, Constantine Chiwenga rọpo aarẹ Mnangagwa, lo ti saaju ke sawọn ọmọ ilẹ Zimbabwe lati tu jade sawọn oju popo lọna ati fi tipa mu ki aarẹ yẹba lori aleefa.
Ọpọlọpọ fidio si lo kun ori ayelujara ni gbogbo ana, ọkan ninu wọn lo n safihan bawọn ọlọpaa se n lo afẹfẹ tajutaju lati tu awọn ero to pejọ si ikorita Robert Mugabe ka nilu Harare.

Oríṣun àwòrán, AFP
"Ẹni ọdun mẹtalelọgọta ni mi, igbe aye le koko mọ mi, mo n tọju awọn ọmọ ọmọ mi nitori awọn ọmọ mi ko lagbara lati tọju wọn"
Ninu fidio miran ni obinrin kan ti n salaye igbesẹ tawọn ọlọpaa n gbe lati doju iwọde alaafia ti wọn n se bolẹ.
Obinrin naa wa seleri pe awọn ko ni lọ sibi kankan, ibi ti awọn way ii gan, ni awọn maa duro si.
"Ẹni ọdun mẹtalelọgọta ni mi, igbe aye le koko mọ mi, mo n tọju awọn ọmọ ọmọ mi nitori awọn ọmọ mi ko lagbara lati tọju wọn."
Bakan naa, oluwọde kan to n lo ọpa lati rin sọ fun ileesẹ iroyin abẹle nilẹ naa pe:
"A n fẹ ki ọgagun Constantine Chiwenga gba akoso ijọba ni orilẹede yii."















