Ladoja lahùn lórí ìkéde ìlú ò fararọ ní Rivers tí ààrẹ Tinubu kéde, gba Wike àti Fubara ní ìmọ̀ràn

Oríṣun àwòrán, Rashidi Ladoja
Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Sẹnẹtọ Rasidi Ladoja, ti sọ pe ikede ilu o fara rọ nipinlẹ Rivers ko le ṣe ipalara fun eto ijọba awarawa.
Sẹnẹtọ Ladoja to sọrọ yii di mimọ fawọn akọroyin nile rẹ niluu Ibadan ṣalaye pe o ni nnkan ti Aarẹ Bola Tinubu ri, ki o to kede ilu o fara rọ ni Rivers.
Yatọ si nnkan ti ọpọ eeyan n sọ wi pe kikede ilu o fara rọ ni Rivers le mu ewu dani fun ijọba awarawa, Ladoja ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.
"Wike ati Gomina Fubara gbọdọ joko papọ, sọ asọyepọ lori ọrọ ipinlẹ Rivers"
Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Oyo sọ pe asiko ti to fun Minisita olu ilu Naijiria, Abuja, Nyesom Wike ati Gomina Siminalayi Fubara, ti aarẹ ni ko lọ rọkun nle, jokoo papọ, ki wọn si jọ sọ asọyepọ lori ọrọ ipinlẹ Rivers.
O ni awọn mejeeji ni lati yanju ohun to n fa aawọ laarin wọn.
Ọtun Olubadan ti ilẹ Ibadan sọ pe ''ikede ilu o fararọ ni Rivers ko le mu ewu kankan dani fun ijọba awarawa.
Ikilọ lo jẹ fawọn gomina mii lorilẹede Naijiria lati jara mọ iṣẹ wọn.
Ni bayii, alaafia ti n jọba nipinlẹ Rivers diẹ diẹ, mo si ni igbagbọ wi pe alaafia yoo tubọ jọba daadaa ki oṣu mẹfa to pe.
Wike ati Fubara ni lati sọ asọyepọ, ati pe ki ni a n ja fun gan an?
O yẹ ki Wike ati Fubara lo asiko ti Aarẹ Tinubu kede ilu o fara rọ ni Rivers yii lati yanju aawọ to wa laarin wọn.
Yiyan ọgagun fẹyinti sipo alakoṣo ipinlẹ Rivers ku diẹ kaato
Ẹwẹ, minisita eto ọgbin tẹlẹ ni Naijiria, Oloye Audu Ogbe ti bu ẹnu ẹtẹ lu bi Aarẹ Tinubu ṣe yan ọgagun fẹyinti sipo alakoṣo ipinlẹ Rivers lẹyin to ni ki Gomina Fubara lọ rọkun nle foṣu mẹfa.
Oloye Ogbe ni igbesẹ yii n ṣapejuwe wi pe awọn ọmọ Naijiria si tun nifẹẹ ijoba ologun ni.
Minisita eto ọgbin tẹlẹ ri fidi ọrọ yii mulẹ lori eto ''Politics Today'' nileeṣẹ Channels tẹlifisan.
Ogbe ni ko dara to bi Tinubu ti ni ki Fubara lọ rọkun nle, ti aarẹ ko si da Wike duro lẹnu iṣẹ.
Oloye Ogbe sọ ko yẹ ko ri bẹẹ tori awọn mejeeji ni aawọ to n ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers da le lori.
Minisita eto ọgbin tẹlẹ to tun ti figba kan ri jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe ko yẹ ki ijọba apapọ kede ilu o fara rọ rara in Rivers tori o lewu pupọ.












