"Tí mi ò bá rí ògùn rà fún ọmọ mi, á máa gé ara rẹ̀ jẹ títí ẹ̀jẹ̀ yóò fi máa ṣàn"
Ọjọ keji osu kẹrin ọdọọdun ni awujọ agbaye ya sọtọ gẹgẹ bii ọjọ pipe akiyesi ara ẹni si arun aidape ọpọlọ ti wọn n pe ni Autism.
Ọna lati pe akiyesi awọn eeyan si aisan yii lo mu ki BBC Yoruba ba mama ọmọ kan to ni aisan naa sọrọ, eyi to nii se pẹlu ọpọlọ.
A fẹ mọ awọn ami to maa n jẹyọ lara iru awọn ọmọ to ba ni aisan Autism yii, ihuwasi wọn, bi wọn se n lọ sile ẹkọ ati isoro nla to n koju awọn iya to n tọju awọn ọmọ yii.
Bakan naa, a fẹ mọ bo se n ri owo ra oogun ati itọju to n fun ọmọ naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Rashidat Aderonke Olatunji ti ọmọ rẹ obinrin, Faizat, ti se ọmọ ọdun mọkanlelogun ni aisan Autism salaye ohun ti oju rẹ n ri.
O salaye pe isoro ti oun n koju buru debi pe ọpọ eniyan lo ti gba oun nimọran lati pa ọmọ naa, ki oun le maa gbe igbe aye oun lọ bo se yẹ.
"Aimoye eeyan lo ti pe mi pe, oo le maa ba igbesi aye ẹ lọ bayii, o ma ṣi ma lọkọ mii..., o jẹ yaa wa nkan ṣe sọ̀rọ̀ ọmọ yii, koo jẹ ko lọ sinmi".
Amọ, abiyamọ o ku ọrọ ọmọ lero ati ọrọ ti yoo kọkọ tu jade bi eeyan ba ri iya ti iya Faizat n jẹ lati moju to ilera ọmọbinrin rẹ to ni ipenija ara yii.
Iya ọmọ ọhun ni ọpọlọpọ ilana ibilẹ ni wọn ti gba lati tọju rẹ ki awọn dokita to ri nkan to n ṣe e gangan.
"Ti mo ba mu ọmọ yẹn jade, awọn eeyan a maa wo mi bi iran tori ẹ o ti ri i lara ẹ pe nkan n ṣe e.
Ninu ile, yoo maa pariwo ni ti ko ba ti lo oogun rẹ, yoo yagbẹ sara nile ẹkọ, to ba n se nnkan osu, emi naa ni maa ba yanju rẹ."
Iya Faizat Akanke ko le sọ gbogbo nkan toju wọn ti ri nipa itọju ọmọ naa tan.
Ṣe ti ko maa dede fọwọ kan ero inu ọkọ titi wọn yoo fi sa bọ silẹ ni abi kawọn onimọto kọ lati gbe wọn tori arun to n se ọmọ naa.
Ipele ipele ni iṣoro naa wọle si i lara.
"O jokoo titi to fi pe ọdun meji ni ko dide rara, igba to ya, a o tun gbọ ohun kankan lẹnu rẹ fun ọdun bii meji mẹta to fi rin".
Ọrun rẹ ko duro, koda, a maa yagbẹ sara."
Gbogbo awọn aleebu ara Faizat yii ni iya rẹ ro papọ ti wọn fi gbe e lọ fun ayẹwo ọpọlọ.
Airi owo ogun ra gẹgẹ bi awọn dokita ṣe ni ki wọn maa ṣe gan, lo maa n fa iṣoro ju ti gbogbo adugbo a maa binu tori ariwo rẹ.
Iṣẹlẹ yii ti sọ iya Faizat di ẹni to n tọrọ owo ko to jẹun, to si ti ko ara rẹ sinu ironu, koda o ni akoko kan wa, ti oun fẹ gba ẹmi ara oun.
"Ile aye su mi, n ko ri owo na, isẹ awọn n san ifun ẹran nu ni mo n se lati tọju Faisal ati aburo rẹ meji .
Mo bẹrẹ si ronu, koda, mo fẹ pa ara mi sugbọn mo tete ke sita lori ayelujara, ti iranwọ fi dide fun mi."

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ arábinrin Rasheedat Olatunji ni ilé ìwòsàn tó n wo àwọn alárùn ọ̀pọlọ ni wọ́n ti fi idi rẹ̀ múlẹ̀ pé Faizat ni ìpèníjà ọ̀pọ̀lọ "Asperger's syndrome" ní àsìkò tó wà ni ọmọ ọdun mẹjọ.
Olatunji ni kéte ti ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ni wàhálà dé nítori bàbá rẹ̀ tó ti di olóògbé nisinyi da ẹbi ọ̀rọ̀ náà le òun lórí.
Gẹ́gẹ́ bi ìyá Faizat ṣe sọ, kò pé púpọ̀ ni bábá rẹ̀ náà fi ayésilẹ̀ tó lọ, ẹrù ìtójú ọmọ náà si di ti òun nìkàn soso.
" Oríṣiriṣi ìgbà ni ojú mi ti ri àwọn ǹkan ìbànujẹ lórí ọmọ yìí, ṣe ti ọjọ ti àwọn onílé dà wá síta ni tàbí ọjọ́ tí àwọn onímọ́tò já wa sílẹ̀ láárin ọ̀nà"
Ìyá Faizat fi kun pé tí òun kò bá rí owó ra òògún nítori iru iṣẹ́ ti òun ṣe tí kò ní àsìkò pàtó tó le mu owó wọlé, àìrówó rà òògun tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹrinlá Nàírà(#14,000) lóṣoosu yìí, ariwo ni yóò maa pa si gbogbo ile, fún ìdí èyí ọ̀pọ̀ àwọn oníle ló ti lé òun jáde.
"Iṣẹ́ àgbàṣe ni ká ba àwọn ènìyàn fọ ilé, fọ ilẹ̀ tàbi nígbà míràn kí n tẹ̀lé àwọn ẹlẹ́ràn láti lọ maa yọ ìfun ẹràn, no mo fí n tọjú òun àti àwọn àbúrò rẹ̀."
Ìyá Faizat ní títí tí ọmọ oun fi pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún yìí, kò lé ṣe ohunkóhun fun ara rẹ̀, tó fi mọ tó bá n ṣe ǹkan oṣù.
Ó ní ni ọ̀pọ̀ ìgbà tí ó bá n ṣe ǹkan ṣun lẹyin "tí mo bá ràn lọ́wọ́ láti lo ilédi, ó le fàá yọ ti yọ."
"Lásìkò tí ó bá bẹ̀rẹ̀ nígbà míràn, má ni láti di lọ́wọ́-dìí lẹ́sẹ̀ àti ẹnu kí o má bá pariwo sí ará ilé, tí mo bá ṣe èyí tán, má wá bú sẹ́kun"
Arábinrin Olatunji tún fi àsìkò yìí rọ àwọn òbí tó bá ni irú ọmọ yiì pe kí wọn máa ni sùúrù, kí wọn si mase dé wọ́n mọ́lé, kí wọ́n jẹ́ kí àwọn náà máa jáde síta.


