Kókó mẹ́fà nípa Bashir Ojulari ti Tinubu yan bíi adarí ìgbìmọ̀ alákòsóo tuntun fún àjọ NNPC

Bashir Ojulari

Oríṣun àwòrán, Bashir Ojulari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti yọ alaga ajọ NNPC, Pius Akinyelure ati ọga agba ajọ naa, Mallam Mele Kyari, nipo.

Agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan lorumọju Ọjọru.

Yatọ si awọn adari NNPC meji yii, Tinubu tun yọ gbogbo awọn igbimọ alabaṣiṣẹ wọn ti bẹrẹ iṣẹ papọ ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2023.

Tinubu kede Bashir Ojulari bii adari fun igbimọ alakoso tuntun fun NNPC

Ileeṣẹ Aarẹ ti wa kede awọn adari tuntun fun ajọ naa bayii, ti Bashir Ojulari yoo jẹ adari wọn nigba ti Ahmadu Kida yoo jẹ alaga.

Yatọ si awọn meji yii, Tunubu tun yan awọn aṣoju kaakiri ẹkun to wa ni Naijiria ti yoo maa ba awọn eeyan naa ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọmọ igbimọ.

Awọn ọmọ igbimọ naa ni Bello Rabiu, Yusuf Usman, ati Babs Omotowa ti gbogbo wọn wa lati iha ariwa.

Aarẹ tun kede orukọ Austin Avuru, David Ige, Henry Obih ati Lydia Shehu Jafiya, ti wọn wa lati iha ila oorun ati iwọ oorun.

Lati akoko yii lọ, Aminu Ahmed ni yoo maa ṣoju ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo rọbi ni Naijiiria.

Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe sọ, oni, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 ni awọn eeyan naa yoo bẹrẹ iṣẹ ni ọọfisi ti Aarẹ yan wọn si.

Lati ọdun 2023 ni Aarẹ Tinubu ti n gbe awọn igbesẹ ti yoo mu NNPC pa owo wọle siwaju si fun Naijiria.

Lọdun to kọja, idokowo to le ni biliọnu mẹtadinlogun dọla ni NNPC ṣe.

Ileesẹ Aarẹ ni afojusun oun ni lati maa fọ miliọnu meji agba epo loojọ titi ọdun 2027 ati miliọnu mẹta agba epo loojọ ti yoo ba fi di ọdun 2030.

Koko mẹfa pataki nipa aseyọri Ojulari lẹka epo rọbi

Ojulari ti lo ọdun to le ni mẹrinlelogoji lẹka epo rọbi ati afẹfẹ gaasi, lara awọn agbọn to si ti sisẹ ni akoso ati akojọ awọn ohun elo ati irinsẹ fun ipese epo rọbi.

  • Ojulari ni imọ nipa idokowo lẹka epo rọbi, wiwa epo rọbi, mimu idagbasoke ba ẹka epo rọbi akoso ipese epo rọbi ati awọn ẹka miran
  • Iyansipo rẹ bii alakoso agba fun ileesẹ NNPC ni yoo fun ileesẹ naa ni anfaani lati se amusẹ ipese ẹgbẹrun meji agba epo rọbi lojumọ ati sise agbega eto ọrọ aje Naijiria
  • Ojulari lo jẹ Oludari agba fun ẹka ipese epo rọbi ati wiwa rẹ labẹ ileesẹ ifọpo Shell ti wọn n pe ni SNEPCo laarin ọdun 2015 si 2021
  • Nigba ti Ojulari n sisẹ nileesẹ ifọpo Shell, oun lo n sakoso awọn ohun eelo to wọn n lo labẹ omi lati wa epo rọbi, ti wọn si n wa agba epo to le ni ẹgbẹrun lọna okoolelọọdunrun ni ojumọ, ti owona wọn si n to biliọnu kan dọla
  • Labẹ akoso Ojulari, aseyọri lo ba ileesẹ ifọpo Shell to fi mọ alekun ida ogun ninu ọgọrun ipese epo rọbi, mimu adinku bii ida ọgbọn ba owona wọn nidi akoso ati mimu adinku ida ogoji ba owo ti wọn n na lati sisẹ
  • Wọn fun Ojulari ni ami ẹyẹ Bonga Asset award lọdun 2016, to si tun lo awọn ọgbọn atinuda rẹ nidi fifi ọwọ si eto adehun to nii se pẹlu isẹ agbase nidi pinpin eroja epo rọbi ati yiyanju aawọ pẹlu OML-118, eyi to mu ki wọn dawọle isẹ agabse fun idagbasoke ti owo rẹ to biliọnu mẹfa si mẹjọ Dọla.

Lara awọn ipenija to wa niwaju ileesẹ NNPC ti Ojulari yoo koju ni iwa biba ọpa epo jẹ, jiji epo rọbi wa ati ipe araalu pe ki wọn siju idokowo Naijiria kuro ni ẹka epo rọbi nikan.