Ṣé Donald Trump le ṣe ààrẹ Amẹ́ríkà fún sáà Kẹta?

Àwòrán ààrẹ Donald Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Graeme Baker
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Donald Trump ti ní ọ̀rọ̀ àwàdà kọ́ ni pé ó wu òun láti ṣe ààrẹ Amẹ́ríkà fún sáà kẹta.

Ìwé òfin US sọ pé "kò sí ẹnikẹ́ni… tí wọ́n máa dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ jù ẹ̀èmèjì lọ," ṣùgbọ́n àwọn alátìlẹyìn Trump kan sọ pé ó yẹ kí ọ̀nà wà láti gbé e gbà.

Ṣé Trump ń fẹ́ sáà kẹta?

Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó sẹ pẹ̀lú NBC pé ṣé ó ṣeéṣe kí ó wá ipò ààrẹ fún ìgbà kẹta, Trump sọ pé "àwọn ọ̀nà wà láti gbé e gbà."

"Mi ò ṣe àwàdà… ọ̀pọ̀ èèyàn ń fẹ́ kí n ṣé," ó fi kun. "Àmọ́ mó máa ń sọ fún wọn pé ọ̀nà tí à ṣi ń lọ jìnà, ó ti yá jù láti máa sọ̀rọ̀ sáà kẹta báyìí."

Nígbà tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ Trump, tó máa pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin nígbà tó bá fi máa parí sáà kejì tó ń ṣe lọ́wọ́, pé ó wù ú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ṣíṣe iṣẹ́ tó lè jú ní orílẹ̀ èdè, ó fèsì pé "mo fẹ́ràn láti máa ṣiṣẹ́."

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí Trump ń sọ̀rọ̀ yìí. Ní oṣù Kìíní, ó sọ fún àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ pé ohun ìwúrí àti ìyìn ló máa jẹ́ fún òun tí òun bá ní àǹfàní láti sin àwọn èèyàn Amẹ́ríkà láì kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan, ẹ̀ẹmèjì, ẹ̀ẹ̀mẹta tàbí ẹ̀ẹ̀mẹrin.

Ṣùgbọ́n ó ní àwàdà ni òun fi ọ̀rọ̀ náà ṣe fáwọn iléeṣẹ́ tó máa ń gbé ìròyìn òfégè.

Kí ni ìwé òfin Amẹ́ríkà sọ?

Ìwé òfin Amẹ́ríkà kò fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti ṣe ààrẹ ju ẹ̀ẹmèjì lọ. Àtúnṣe kejìlélógún sí ìwé òfin náà sọ pé:

"Wọn kò lè dìbò yan ẹnikẹ́ni sípò ààrẹ ju ẹ̀ẹmèjì lọ, àti pé ẹni tó bá ti wà nípò ààrẹ tàbí ṣe adelé ààrẹ ju ọdún méjì lọ ní sáà kan ìṣèjọba ààrẹ kan ni wọn kò lè yàn sípò ààrẹ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ mọ́."

Láti ṣe àyípadà ìwé òfin nílò ìbuwọ́lù ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta àwọn aṣòfin nílé aṣòfin àgbà àti aṣojúṣòfin àti ìbuwọ́lù ìdá mẹ́ta nínú ìdá mẹ́rin àwọn ìjọba ìpínlẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣòfin ẹgbẹ́ òṣèlú Republican, tó jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Trump ló ní àwọn aṣòfin tó pọ̀ jùlọ nílé aṣòfin, síbẹ̀, wọ́n kò ní iye aṣòfin tó le ṣe àyípadà ìwé òfin.

Bákan náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat, tó jẹ́ alátakò ń ṣe àkóso ìpínlẹ̀ méjìdínlógún nínú àwọn ìpínlẹ̀ àádọ́ta tó wà ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Báwo ni Trump ṣe le gba ipò ààrẹ fún sáà kẹta?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn alátìlẹyìn Trump ń sọ pé àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan wà nínú ìwé òfin náà.

Wọ́n ní àtúnṣe kejìlélógún náà fòfin de ẹni tí wọ́n bá ti dìbò yàn sípò ààrẹ ní ẹ̀ẹmèjì àmọ́ tí kò sọ ohunkóhun lórí ẹni tó bá gba ipò ẹnìkan.

Lábẹ́ èyí, Trump le ṣe igbákejì ààrẹ fún ẹlòmíràn – bí i igbákejì rẹ̀ báyìí, JD Vance níbi ètò ìdìbò 2028.

Tí wọ́n bá wọlé, tí wọ́n sì búra fún wọn tán, onítọ̀hún le kọ̀wé fipò sílẹ̀, tí Trump yóò sì tún gba ibẹ̀ di ààrẹ.

Steve Bannon, tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti olùbádámọ̀ràn Trump ní òun gbàgbọ́ pé Trump yóò díje yóò sì tún wọlé àti pé àwọn ọ̀nà láti jẹ́ kí èyí ni àwọn ti ń gbé yẹ̀wò.

Andy Ogles, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin gbé àbá kan dìde nínú oṣù Kìíní níbi tó ti ń bèèrè fún àtúnṣe sí ìwé òfin láti fààyè gba ààrẹ láti máa lò sáà mẹ́ta nígbà tí wọn kò bá ti ṣe é léra wọn.

Èyí túmọ̀ sí pé Trump nìkan, nínú àwọn tó ti ṣe ààrẹ Amẹ́ríkà rí tó ṣì wà láyé ni yóò lè jẹ àǹfàní yìí nítorí Barrack Obama, Bill Clinton àti George W Bush ṣe sáà méjì tẹ̀lé ara wọn ni.

Trump nìkan ló kọ́kọ́ ṣe ààrẹ tó sì fìdí rẹmi ní sáà tó tẹ̀le kó tó di pé ó tún wọlé lọ́dún 2024.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ìlànà tí àtúnṣe ìwé òfin máa ń tẹ̀lé jẹ́ kí àwọn nǹkan Ogles ń pè fún kò ní jẹ́ kó yá kíákíá, síbẹ̀, ó fa ọ̀pọ̀ awuyewuye dání.

Ta lo ń tako àbá Trump láti lọ fún sáà kẹta?

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat ti tako ìgbésẹ̀ yìí.

Daniel Goldman, aṣòfin tó ń ṣojú New York tó léwájú láti yọ Trump nípò ní sáà àkọ́kọ́ sọ pé "ìgbésẹ̀ Trump yìí jẹ́ ìgbìyànjú láti gbàkóso ìjọba kó sì da ojú ìjọba àwaarawa délẹ̀."

"Táwọn aṣòfin ọmọ ẹgbẹ́ Republican bá gbàgbọ́ nínú ìwé òfin, wọ́n gbọdọ̀ tako àbá Trump láti ṣe ààrẹ fún sáà kẹta."

Àwọn mìíràn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Trump náà rò pé ìgbésẹ̀ tí kò dára ni Trump fẹ́ gbé.

Sẹ́nétọ̀ Markwayne Mullin láti Oklahoma sọ nínú oṣù Kejì pé òun kò ní ṣe àtìléyìn fún èrò láti dá Trump padà sí ilé ààrẹ fún sáà míì.

Mullin sọ fún NBC pé òun kò ní gbìyànjú láti yí ìwé òfin padà àyàfi táwọn ọmọ Amẹ́ríkà bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.

Kí ni àwọn onímọ̀ nípa òfin sọ?

Derek Muller, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ òfin ètò ìdìbò ní ilé ẹ̀kọ́ University of Notre Dame sọ pé àtúnṣe ìwé òfin kejìlá sọ pé "ẹnikẹ́ni tí kò bá ti lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin sí ipò ààrẹ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ sípò igbákejì ààrẹ Amẹ́ríkà."

Ó ní èyí túmọ̀ sí pé ẹni tó bá ti lo sáà méjì nípò ààrẹ Amẹ́ríkà kò lè díje dupò igbákejì ààrẹ.

Jeremy Paul, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìwé òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Northeastern University, Boston sọ pé kò sí ohunkóhun, lábẹ́ òfin, tí ẹnikẹ́ni le fi gbé pípè fún sáà kẹta lẹ́sẹ̀.

Ṣé ààrẹ kankan ti lò ju sáà méjì lọ ní Amẹ́ríkà?

Àwòrán Franklin Delano Roosevelt

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Roosevelt nìkan ni ààrẹ Amẹ́ríkà tó lò ju sáà méjì lọ

Ẹ̀ẹmẹ̀rin ni wọ́n dìbò yan Franklin Delano Roosevelt sípò ààrẹ. Ìgbà tó ku oṣù mẹ́ta tó máa bẹ̀rẹ̀ sáà kẹrin ló jáde láyé lọ́dún 1945.

Oogun àgbáyé kejì wà lára nǹkan tó mú kí Roosevelt pẹ́ ní ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.

Lásìkò ìgbà náà sì rèé, wọn ò tíì sọ gbèdéke lílo sáà méjì lórí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ní Amẹ́ríkà di òfin tí wọ́n kọ sílẹ̀ - ṣùgbọ́n tó jẹ́ àṣà tí wọ́n ń tẹ̀lé lẹ́yìn tí George Washington kọ̀ láti ṣe sáà kẹta lọ́dún 1796.

Bí Roosevelt ṣe pẹ́ lórí ipò ló jẹ́ kí wọ́n padà sọ àṣà lílo sáà méjì lórí ipò ààrẹ di òfin nígbà tí wọ́n ṣe àtúnṣe kejìlélógún ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950