Kí ló kàn lẹ́yìn Ààwẹ̀ Ramadan, ààwẹ̀ Shawwal mẹ́fà ni àbí sísan ààwẹ̀ tí o dín padà?

Bi aawẹ Ramadan ba pari, awọn aawẹ mi-in tun wa ti eeyan le gba lati gba laada.
Lara wọn ni aawẹ mẹfa ti a maa n gba loṣu Shawwal to tẹle Ramadan.
Ọrọ Anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla n bẹ fun, sọ pe ẹni to ba gba aawẹ mẹfa ninu oṣu Shawwal, yoo ni laada ẹni to fi ọdun kan gba aawẹ ni.
Eyi maa n mu ki awọn Musulumi gbiyanju lati gba aawẹ mẹfa yii ki oṣu Shawwal too pari, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe dandan,
Ṣugbọn ki i ye awọn mi-in, wọn maa n ro o pe ṣe aawẹ to ṣee ṣe kawọn ti din lasiko Ramadan fun idi kan, lo yẹ kawọn kọkọ san pada ni, tabi kawọn bẹrẹ aawẹ Shawwal ti ko pọn dandan ṣugbọn to ni laada aawẹ ọdun kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Èrò àwọn onímọ̀ ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Sheikh Sulaiman Datti, Imaamu agba ni mọṣalaṣi Jimọ to wa ni Sunna, Birnin Kudu, nipinlẹ Jigawa, sọ pe ero awọn aafaa ṣọtọọtọ lori eyi to yẹ ko ṣaaju ninu awọn aawẹ yii.
" Awọn kan wa ti wọn gbagbọ pe aawẹ Ramadan ti eeyan din lo yẹ ko kọkọ san pada.
Bẹẹ la ri awọn ti wọn ni ti Shawwal ni ko ṣiwaju."
Imaamu Datti sọ pe kaluku wọn lo ni idi ti wọn fi gbe ero wọn kalẹ lori awọn aawẹ naa.
O ni awọn kan gba pe aawẹ Ramadan to jẹ ọran-an-yan lo yẹ ki eeyan kọkọ san pada na, ṣiwaju ko too ronu kan aawẹ Shawwal ti ko pọn dandan.
Sheikh Sulaiman Datti sọ pe awọn to gba eyi gbọ tẹle ọrọ Anọbi to ni ki eeyan tete san gbese to ba jẹ Allah ni.
Fun idi eyi, wọn gbagbọ pe aawẹ Shawwal ki i ṣe gbese, adipele ẹsan leeyan fi n wa.
Ṣugbọn aawẹ Ramadan ko ṣee ma san pada, o si yẹ keeyan san ṣiwaju ko too maa gba Shawwal.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'Àwọn kan gbàgbọ́ pé o lè máa gba Shawwal, kó o sì san Ramadan pada to ba yá'
Sheikh Sulaiman Datti tẹsiwaju pe awọn onimọ ẹsin Islam kan naa wa ti wọn gba pe eeyan le maa gba aawẹ Shawwal, ko si pada san Ramadan to ba ya.
"Awọn to gba eyi gbọ sọ pe ara ẹsin naa ni aawẹ mẹfa yii, ati pe 'zawatul asbab', ni wọn n pe e.
Eyi tumọ si ijọsin to ni idi ti eeyan fi n ṣe e lasiko ẹ"
"Fun apẹẹrẹ, bi Shawwal ko ba de, a ki i gba aawẹ rẹ. O ni asiko tiẹ. "
" Ọpọ awọn aafaa lo gba eyi gbọ, pe eeyan le gba aawẹ mẹfa ninu Shawwal na, ko si san Ramadan rẹ to ba ya."
Imaamu Datti lo ṣalaye bẹẹ.
O ni awijare awọn wọnyi ni pe ẹni to gba Shawwal mẹfa yoo ni lada gẹgẹ bii ẹni to gba aawẹ fun ọdun kan
Imaamu Datti sọ pe eyi ni ọpọ aafaa n tẹle ju lọ.














