Bí o ṣe lè tánràn ààwẹ̀ tí o bá dín nínú Ramadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dandan ni gbigba aawẹ Ramadan jẹ fun ẹlẹsin Islam to ba ti wa ni alaafia, ṣugbọn ti eeyan ba waa din aawẹ naa fun awọn idi kan, yoo san an pada.
Eyi wa fun awọn eeyan to ba jẹ pe ki i ṣe pe wọn mọ-ọn-mọ ja aawẹ naa.
Bi eeyan ba mọ-ọn-mọ jẹun ni ọsan aawẹ, ijiya wa fun eyi , bo tilẹ jẹ pe ọna to ṣi le gba san aawẹ naa pada wa, gẹgẹ bi awọn olori ẹsin ṣe sọ.
Àwọn nǹkan wo ló ń fa kí èèyàn tánràn ààwẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sheikh Abu Qatada Muhammad, ọkan lara awọn imaamu mọṣalaṣi Usman bin Affa, ni Gadon Qaya, Kano, sọ pe ọna ti Allah fi n wẹ ẹru rẹ to ba ṣẹ mọ, ni.
"A n pe kinni kan ni 'Kaffara', to tumọ si pe ki eeyan tan ọran to ba da.
Ninu aawẹ, o tumọ si pe eeyan ti ja aawẹ, o si gbọdọ tan an.''
Àwọn nnkan bii:
- Ki eeyan mọ-ọn-mọ jẹun tabi mu omi lasiko to n gba aawẹ lọwọ.
- Ki eeyan ni ibalopọ lọsan-an aawẹ
- Ki eeyan mọ-ọn-mọ ki ọwọ bọ ọfun ko si bì
- Ki eeyan maa fi oju ara rẹ ṣere nilana ere ifẹ lati tẹ ara rẹ lọrun.
Báwo ni wọ́n ṣe ń tánran ààwẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi awọn onimọ ẹsin Isilaamu ṣe wi, ohun to ba fa a ti aawẹ fi ja naa ni yoo sọ ọna ti eeyan yoo gba tan ọran naa.
Fun ẹni to ni ibalopọ lọsan-an aawẹ, Sheikh Murtadha Muhammad Gusau, Imaamu agba fun mọṣalaṣi Okene, ṣalaye pe, ẹni naa yoo ni lati tu ẹrubinrin kan silẹ, yoo jẹ ko maa lọ lominira.
Bi eyi ko ba ṣee ṣe, ẹni naa yoo gba aawẹ fun ọgọta ọjọ (60 days) lati fi tanran aawẹ ọjọ kan ṣoṣo to din.
Biyẹn naa ko ba tun ṣee ṣe, o gbọdọ bọ ọgọta alaini, gẹgẹ bo ṣe wa ninu hadith kan.
''Ẹnikẹni to ba mọ-ọn-mọ ja aawẹ rẹ lọsan-an Ramadan, ẹlẹṣẹ ni.
''Yoo gba aawẹ fun ọgọta ọjọ tẹle ara wọn lai sinmi rara lati tan ọran aawẹ to da naa. "
Bẹẹ ni Imam Okene ṣalaye.
Awọn ti yoo bọ alaini
Abu Qatada Muhammad ṣalaye pe awọn agbalagba ni eyi wa fun, ti wọn ti gbo lai ni agbara lati gbaawẹ mọ.
Bakan naa lo ri fun alaarẹ ti ireti ko si fun mọ, wọn yoo maa ba a bọ awọn alaini lati tan ọran aawẹ ti ko le gba.
Fun awọn obinrin to loyun ati awọn to n fun ọmọ lọmu, Abu Qatada sọ pe ohun ti ẹsin Islam sọ ni pe wọn le san an pada lẹyin aawẹ.
Wọn le maa bọ alaawẹ lojoojumọ lasiko ti Ramadan ba n lọ lọwọ pẹlu.
Bakan naa ni ẹsin Isilaamu faaye gba ẹni to ba n rin irinajo to nira lati fi aawẹ silẹ, ko si san an pada lẹyin ti aawẹ ba tan.













