Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ikú ọkùnrin tí wọ́n gún pa níbi àdúrà Tahajjud

Mosque

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan mejila lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu ikọlu kan to yọri si iku ẹnikan to n gbadura ninu mọṣalaṣi nipinlẹ Kaduna.

Eyii n waye lẹyin ti wọn gun ọkunrin kan pa lagbegbe Wada to wa ni ijọba ibilẹ Guusu nipinlẹ naa.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Mansir Hassan, lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan.

O ni awọn kọlọrọsi kan lati agbegbe Malalin Gabas, Tudun Was, Rafin Guza ati Unguwar Baduko yabo awọn Musulumi nibi ti wọn ti n ṣe adura Tahajjud lọwọ, ni Layin Bliyaa to wa ni Rigasa, ti wọn si gun eeyan kan pa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ki awọn ọlọpaa to de agbegbe naa, awọn kọlọrọsi ọhun ti gun Usman Mohammed, ti ẹmi si ti bọ lẹnu rẹ.

Kete lẹyin naa ni ọlọpaa fi ṣikun ofin mu eeyan mejila, ti awọn afurasi naa si ti jẹwọ pe lootọ lawọn lọwọ ninu ikọlu naa, ọlọpaa ni awọn tun gba oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn.

Ọlọpa ni iwadiii ti bẹrẹ lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa ikọlu naa ki idajọ ododo le waye.

Ileeṣẹ ọlọpaa Kaduna sọ pe oun ti fi awọn ẹṣẹ alaabo ṣọwọ si awọn mọṣlaṣi kaakiri ipinlẹ ọhun lati maa pese aabo fun awọn eeyan lasiko irufẹ adura bẹẹ.

Lẹyin naa lo ke si awon araalu lati maa bun ọlọpaa gbọ ni gbogbo igba ti wọn ba ti keefin iwa ọdaran lagbegbe wọn.

O tun rọ awọn eeyan ipinlẹ ọhun ki wọn ṣọra, ki wọn si tun jawọ ninu gbogbo ohun to ba farajọ iwa ọdaran.