Naira Marley jẹri nílé ejọ̀ lórí ikú Mohbad

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola, ẹni ti ọpọ mọ si Naira Marley ti jẹri niwaju ile ẹjọ Magistrate to n jokoo niluu Ikorodu nipa ohun to ṣẹlẹ laarin rẹ ati ọmọ ẹgbẹ orin rẹ tẹlẹ to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad.
Naira Marley darapọ mọ igbẹjọ naa lati ori oju opo ayelujara lọjọ Ẹti, to si sọ fun ile ẹjọ nipa ohun sẹlẹ nipa iku Mohbad.
Naira Marley bẹrẹ ọrọ rẹ niwaju Onidajọ Adedayo Shotobi pe ohun mu Mohbad wọ ẹgbẹ orin rẹ, Marlians Music pe ko gbe awo orin mẹrin sita ṣugbọn titi Mohbad fi kuro ni abẹ rẹ, ko gbe orin naa sita nitori ede ayede to wa laarin rẹ ati mọnija rẹ nigba naa, Opere Babatunde.
Bakan naa ni Naira Marley jẹ ko di mimọ pe oun ko fi igba kankan ṣe ikọlu si Mohbad, to si fi iwe lati ọwọ ileeṣẹ silẹ gẹgẹ bii ẹri.
O ni gbogbo ọrọ ti awọn kan n sọrọ kiri pe oun ṣekọlu si Mohbad lo jẹ ete, to si jẹ iro to jina si otitọ.
Nigba ti wọn bi nipa fọnran kan ti oloogbe gbe sita, nibi to ni ti oun ba ku, ki wọn di Naira Marley ati ileeṣẹ orin rẹ mu.
Naira Marley ni Mohbad ati awọn obi rẹ wa bẹ oun lẹyin iṣẹlẹ naa nitori oloogbe gbe fọnran naa sita lẹyin to lo oogun oloro.
O tẹnu mọ pe oun ko ni ede ayede kan pẹlu oloogbe naa rara.
O ni koda oun ko si ni orilẹede Naijiria lasiko iku Mohbad, to si jẹ ọdun kan sẹyin ni oun ti foju kan Mohbad ko to di pe o jade laye.
Ẹlẹri keji to jẹri ni ile ẹjọ ni agbẹjọro fun oloogbe Mohbad, Oluwasanmi Falade ni irọ ni Naira Marley n pa pe ko si ede ayede laaarin oun pẹlu Mohbad.
Agbẹjọro sọ fun ile ẹjọ pe ija wa laaarin Mohabd ati ileeṣẹ orin Naira Marley lori ọrọ owo to tọ si onikaluku.
O ni ọpọ igba ni Oloogbe kọ iwe si ileeṣẹ orin Naira Marley, ti wọn ko si fun lesi.
Falade tun sọ fun ile ẹjọ pe Sam Larry ṣekọlu si oloogbe naa ni Lekki Beach, ti oloogbe fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
Lẹyin ti ile ẹjọ gbọ atotonu lati ẹnu awọn mejeeji, Shotobi kesi Sam Larry pe ki oun naa wa wi tẹnu rẹ nigba ti ile ẹjọ ba tun jokoo lori ọrọ naa.
Ile ẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkanla oṣu kẹrin ọdun 2025.















