Kóòtù fagilé ẹjọ́ Oriyomi àti Naomi, wọ́n kò lẹ́jọ́ jẹ́ mọ́

Oríṣun àwòrán, Naomi, Oriyomi/ Facebook
Ile-ẹjọ ti da ẹsun mejidinlogun ti wọn fi kan Olori tẹlẹ ni aafin ilu ile ifẹ, Naomi Silẹkunọla, ati gbajumọ sọrọsọrọ ori redio niluu Ibadan, Oriyọmi Hamzat, nu.
Bakan naa ni kootu fagile ẹjọ ti ọga ile ẹkọ Islamic High School to wa ni Bashorun; Fasasi Abdulahi naa n jẹ pẹlu.
Adajọ agba Ladiran Akintola, ti ilẹ giga ipinlẹ Oyo lo wọgile awọn ẹsun naa nibi igbẹjọ to waye l'Ọjọbọ, ọgunjọ oṣu Kẹta ọdun 2025.
Agbẹnusọ ijọba Ipinlẹ Oyo lori ẹjọ naa, Abiodun Aikomo, sọ fun kootu pe gbogbo awọn obi ti iṣẹlẹ to pa ọmọ marundinlogoji n'Ibadan naa kan ni wọn ti san owo gba mabinu fun.
Aikomo fi kun un pe niwọn igba ti awọn olujẹjọ ti tẹle ìlànà ile ẹjọ, ko si idi kankan fun igbejọ naa lati maa tesiwaju mọ.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Ladiran Akintola ni bo tile jẹ pe iṣẹlẹ naa bani ninu jẹ, awọn to gbe eto naa kalẹ ti kọ ẹkọ to yẹ ki wọn kọ.
Fun idi eyi, Adajọ ni oun tu awọn olujẹjọ mẹta naa silẹ, ki wọn maa lọ layọ ati alaafia
''Ẹ ma tori ohun to ṣẹlẹ da oore ṣiṣe duro''

Nigba to n gba awọn olujẹjọ nimọran, Adajọ agba Ladiran Akintola, sọ pe ki wọn ma tori ohun ti oju wọn ri latari oore ṣiṣẹ ki wọn lawọn ko ni i ṣe oore mọ.
Ọ pasẹ pe ki wọn da iwe irinna (international passport) awọn eeyan naa pada fun wọn ni kia. Ki wọn le rin irin ajo lọ sibikibi ti wọn ba fẹẹ lọ.
Ninu ọrọ rẹ, Oriyomi Hamzat ni iṣẹlẹ naa mu ki ohun kogbọn si i.
Hamzat ni igba akọkọ ti oun yoo gbe eto ẹlomiran sori ree.
O tesiwaju pe iriri oun nibi igbejọ yii ko ni i mu oun dawọ oore ṣiṣe duro.
Oriyomi sọ pe gbogbo eto toun yoo ba maa kopa ninu rẹ bayii ni ipalemo rẹ yoo muna doko, lati dẹ́kun iru iṣẹlẹ to bani ninu jẹ to ṣẹlẹ ọhun.
Te o ba gbagbe, ọmọde marundinlogoji lo ku nibi eto ti Naomi Silekunola gbe kalẹ lati ṣe iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ, iyẹn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024.
Ọpọ eeyan to ya sibudo naa lo fa itẹra-ẹni pa, ọrọ naa lo gbe Naomi, Oriyomi ati Fasaasi; ọga ileewe de kootu, ki wọn too gba ominira lẹyin oṣu kẹta.















