Gáàsì CNG gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà l'Abuja, 25 farapa yánayàna

O kere ran, eeyan mejila lo ti jade laye lagbegbe Karu, niluu Abuja lẹyin ibugbamu kan to waye nibẹ.
Iroyin ni nnkan bii aago meje alẹ lawọn eeyan bẹrẹ si n gbọ oniruru ibugbamu ti pupọ ninu wọn si lero pe awọn ọmọ ogun Boko Haram lo n ṣọṣẹ.
Agbegbe naa ko fi bẹẹ jina si ibudokọ Nyanya ti Boko Haram ti fi ado oloro gbẹmi eeyan mọkandinlogun lọdun 2014.
Ọkọ ajagbe ileeṣẹ Dangote to gbe simẹnti lo ṣokunfa ibugbamu tuntun yii gẹgẹ bii ohun ti ijọba sọ.
Alaga kansu agbegbe Nyanya, Mathew Danjuma, sọ fun BBC pe ọkọ ajagbe naa kọ lati duro fun awọn oṣiṣẹ ajọ to n yẹ ọkọ wo, VIO, latari pe ko yẹ ki awọn ọkọ nla wa loju popo laarin aago mẹrin irọlẹ si mẹsan an alẹ.
O ni "Asiko to n gbiyanju lati bọ mọ wọn lọwọ lo bẹrẹ si n kọlu awọn ọkọ to wa ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ, lẹyin naa lo gbina.
"Afẹfẹ gaasi CNG ni ọkọ ajagbe naa n lo, fun idi eyii, bi ọkọ naa ṣe gbana naa ni awọn silinda afẹfẹ gaasi rẹ bẹrẹ si n bu gbamu, silinda marun un lo bu gbamu.
Ileesẹ ọlọpaa ni eeyan mẹfa lo ku, nigba ti ajọ FRSC sọ pe eeyan marundinlọgbọn mii lo farapa nibẹ.
A kọkọ gbagbọ pe ado oloro ni – Oṣojumikoro
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn kọkọ ro pe ado oloro lo n dun ki wọn to mọ pe gaasi CNG ni.
Ẹnikan ninu wọn ni "Ni kete ti mo pe ajo panana ni wọn tete de lai fi akoko kankan ṣofo, bẹẹ naa ni awọn ọlọpaa to wa ni Karu naa tun de, awọn ọlọpaa Nyanya naa tun tete de pẹlu."
O ṣalaye pe apapọ awọn oṣiṣẹ panapana, ajọ FRSC, NEMA, ọlọpaa ati Red Cross lo doola awọn eeyan nibẹ.
O fi kun pe ọkọ ajagbe naa ṣi wa lẹba ọna nibẹ, bo tilẹ jẹ pe simẹnti towa ninu rẹ ti jo gurugu.
Èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ọkọ̀ ní Abuja wọ ọgbọ̀n

Kò dín ní ọgbọ̀n èèyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ńlá tó kó sìmẹ́ǹtì Dangote tó gbiná ní agbègbè Karu, òpópónà márosẹ̀ Abuja sí Keffi tó wáyé lálẹ́ ọjọ́rú.
Shehu Dalhatu, tó jẹ́ alákòso ikọ̀ Vehicle Inspection Organization, VIO, Kubo sọ pé èèyàn ọgbọ̀n ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tọ́pọ̀lọpọ̀ sì wà nílé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ f;un BBC pé nǹkan bíi aago méje àbọ̀ àṣálẹ́ ọjọ́rú ni ìjàmbá náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ ńlá tó kó sìmẹ́ǹtì Dangote pàdánù ìjánu ọkọ̀ rẹ̀ tó sì lọ kọlu àwọn ọkọ̀ tó wà nínú súnkẹrẹ fàkẹrẹ.
Wọ́n ní kò dín ọkọ̀ ogún tí ìjàmbá náà ṣàkóbá fún.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, awakọ̀ ńlá náà ń sá nítorí kò fẹ́ dúró nígbà tí wọ́n ń da dúró.
Káhúnsílọ̀ Nyanya, Danjuma Yare ní kò ì tíì tó àsìkò táwọn ọkọ̀ ńlá le wọ ìlú Abuja tí ọkọ̀ náà fi fẹ́ wọ inú Abuja ni kò ṣe dúró lásìkò tí wọ́n ń da dúró.
Yare ní èyí ló fi lọ ṣàkóbá fáwọn ọkọ̀ mìíràn tó wà lójú pópó lásìkò ọ̀hún.
Ó sọ pé èèyàn mẹ́jọ ló dágbére fáyé lójú ẹsẹ̀ nínú àwọn tí àwọn kọ́kọ́ rí yọ níbi ìjàmbá ná]a àti pé àwọn mẹ́rin mìíràn ni wọ́n jóná gidigidi tí wọ́n sì ti wà nílé ìwòsàn.
Gẹ́gẹ́ bí òfin, ọkọ̀ ńlá kò lè wọ inú Abuja nígbà tí aago mẹ́wàá alẹ́ kò bá ì tíì lù.
Èèyàn mẹ́fà, ọkọ̀ mẹ́rìnlá jóná pátá bí tírélà Dangote ṣe sọ ìjánu rẹ̀ nù, kọlu ọ̀pọ̀ ọkọ̀, tó sì gbiná l'Abuja

Oríṣun àwòrán, X
Ṣaaju ni Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa niluu Abuja ti fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mẹfa pẹlu mọto mẹrinla lo ṣegbe sinu ijamba ina to bẹ silẹ lori afara Nyanya, l'Abuja, lalẹ Ọjọruu, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2025.
Alukoro olu ileeṣẹ ọlọpaa fun ilu Abuja,SP Josephine Adeh, fidi ijamba naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita lalẹ ọjọ iṣẹlẹ naa.
Ninu alaye rẹ lo ti ni tirela ileeṣẹ Dangote to kun fọfọ fun simẹnti lo ṣokunfa ina to ṣẹyọ ni nnkan bii aago meje alẹ ku iṣẹju meji naa.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Oríṣun àwòrán, X
Tirela n gun ori afara lo sọ ijanu ọkọ nu, to rọlu awọn mọto ti sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ ọkọ ti mu, ti wọn to tẹle ara wọn
SP Josephine Adeh, ṣalaye pe tirela ileeṣẹ Dangote kan lo ko ọpọlọpọ simẹnti, to si n bọ lati ibi kan ti a mọ si Aya, to fẹ kọja lorii biriji Nyanya.
Nibi ti tirela ọhun ti n gun ori biriiji naa lo ti padanu ijanu ọkọ, to si lọọ rọlu awọn mọto ti sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ ọkọ ti mu, ti wọn to tẹle ara wọn.
Alukoro ọlọpaa fun ilu Abuja sọ pe ikọlu yii lo fa ina nla to sọ lojiji, ti gbogbo agbegbe naa si kun fun ipayinkeke.
Awọn oṣiṣẹ alaabo sara debẹ gẹgẹ bo ti wi, wọn gba inu eefin kiki naa gbe eeyan mẹfa jade ninu awọn ti ina ti ba.
O ni wọn sare gbe wọn lọ sileewosan boya wọn yoo le doola ẹmi wọn, ṣugbọn dokita sọ pe wọn ti ku.
Ile igbokusi ọsibitu ijọba apapọ to wa ni Karu, l'Abuja ni wọn gbe awọn oku naa si bayii gẹgẹ bi Alukoro ṣe fidi ẹ mulẹ.
O fi kun un pe mọto mẹrinla ni ina ọhun fọwọ ba, ti wọn jona gburugburu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ba ẹbi awọn ti iṣẹlẹ yii kan kẹdun, wọn si ni iwadii kikun ti n lọ lati mọ idi iṣẹlẹ yii, ki wọn si le dena rẹ lọjọ iwaju.
Bakan naa ni wọn rọ araalu lati yee sare asapajude bi wọn ba n wa ọkọ.














