Àpapọ̀ ilé aṣòfin buwọ́lu ìgbésẹ̀ Tinubu lórí ìlú ò fararọ tó kéde ní Rivers

Oríṣun àwòrán, @NASS
Ilé aṣòfin àgbà ti buwọ́lu ìgbésẹ̀ Ààrẹ Bola Tinubu bí ó ṣe kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers àti bó ṣe fòfin de Gómìnà ìpínlẹ̀ náà fún oṣù mẹ́fà.
Lábẹ́ ìwé òfin Nàìjíríà ọdún 1999, ààrẹ ní àǹfàní láti kéde ìlú ò fararọ nígbà tí wàhálà bá ń wáyé ní ìpínlẹ̀ kan.
Ṣáájú ni ilé aṣojúṣòfin ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ ti kọ́kọ́ kéde ìbuwọ́lù ìgbésẹ̀ ààrẹ náà.
Tinubu, lọ́jọ́rú kọ̀wé sí àpapọ̀ ilé aṣòfin níbi tó ti ń bèèrè fún àtìlẹyìn àwọn aṣòfin lórí òfin ìlú ò fararọ tó kéde ní ìpínlẹ̀ Rivers.
Lẹ́yìn tí ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Sẹ́nétọ̀ Godswill Akpabio ka lẹ́tà ààrẹ náà ni àwọn aṣòfin náà lọ fún ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ láti jíròrò lórí rẹ̀.
Àpapọ̀ ilé aṣòfin ti wá gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti máa ṣe àmójútó àkóso ìpínlẹ̀ Rivers lásìkò yìí.
Ilé aṣòfin àgbà tún gbé ìgbìmọ̀ kan dìde, èyí àwọn èèkàn ọmọ Nàìjíríà wà nínú rẹ̀ láti dá sí làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé ní Rivers.
Bákan náà ni àwọn aṣòfin nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin fẹnukò lórí ìgbésẹ̀ ààrẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Rivers.
Nígbà tí wọ́n dìbò pẹ̀lú òun ẹnu, gbogbo àwọn ọmọ ilé tó wà níkàlẹ̀ ní àwọn faramọ́ ìgbésẹ̀ ààrẹ.
Olórí ilé aṣojúṣòfin, Tajudeen Abbas sọ pé àwọn aṣòfin 243 ló wà ní ìjòkó tí ìpinnu náà ti wáyé.
Ki ni ìtumọ̀ ìkéde ìlú ò fararọ, ìgbà wo sì ní ààrẹ le kéde rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Others
Ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kejidinlogun osu Kẹta ọdun 2025 yii ni Aare Bola Tinubu kede ilu o fararọ ni ipinlẹ Rivers nitori laasigbo oṣelu to n waye nibẹ.
Ninu ọrọ ti aarẹ bawọn ọmọ orilẹ ede Naijiria sọ nirọlẹ ọjọ yii lo ti kede pe ki gomina Fubara, igbakeji rẹ ati awọn ọmọ ile asofin ipinlẹ naa lọ rọọkun nile na fun osu mẹfa gbako.
Tinubu ni laasigbo oṣelu to n waye ni ipinlẹ naa lati bii oṣu meloo kan sẹyin n kọ oun lominu, gbogbo igbiyanju oun lati ri pe ifanfa naa wa sopin, lo ja si pabo.
Amọ ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọdọ ni ikede ilu ko fararọ ko ye ati itumọ rẹ.
Idi ree ti BBC fi se atupalẹ iroyin yii lati salaye ohun ti ikede ilu ko fararọ ni ipinlẹ kan tumọ si, igba ti aarẹ orilẹede kan le kede rẹ.
Bakan naa la fẹ mọ boya ikede ilu ko fararọ ti aarẹ Bola Tinubu se nipinlẹ Rivers bofin mu tabi bẹẹ kọ.
"Òfin Naijiria ko fun aarẹ ni agbara lati yọ ẹnikẹni ti wọn dibo yan sipo tabi ko wọgile ile igbimọ aṣofin ipinlẹ kan"
BBC News Yoruba ba Amofin Opatola Victor sọrọ lori ohun ti ofin sọ nipa kikede ilu o fararọ nipinlẹ kan ni orilẹede Naijiria.
Opatola ṣalaye pe labẹ iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999, ni abala 305, o fun aarẹ ni agbara lati kede ilu o fararọ labẹ awọn iṣẹlẹ kọkan.
Sugbọn o ni ofin ko fun aarẹ ni agbara lati yọ ẹnikẹni ti wọn dibo yan wọle sipo tabi ko wọgile ile igbimọ aṣofin.
Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, Opatola ni kikede ilu o fararọ labẹ ofin Naijiria tumọ si idaduro ofin, ti wọn yoo si fi ofin ti ileeṣẹ ologun rọpo rẹ lati jẹ ki alaafia jọba ni awọn agbegbe ti rogbodiyan ba ti bẹ silẹ.
"Ilu o fararọ jẹ igbesẹ pataki to fun aarẹ ni agbara lati gbe awọn igbesẹ kan lori awọn iṣẹlẹ kan to ba waye.
Ko ki n se gbogbo igba ni Aarẹ ni anfani lati lo ikede Ilu o fararọ.
"Ti ẹ ba wo isọri 305 ninu iwe ofin orilẹede wa, o sọ igba ti Aarẹ le lo ikede ilu o fararọ ati bo ṣe le lo."
Igba wo ni Aarẹ le lo ikede Ilu o fararọ?
Opatola ni aaye fun aarẹ lati lo ikede ilu o fararọ lasiko ti orilẹede rẹ ba wa loju ogun jija.
"Bakan naa ni aarẹ tun le lo ikede to ba jẹ pe awọn eeyan kan fẹ wa ko ogun ba orilẹede rẹ.
"Aarẹ le lo ikede ilu ko fara rọ to ba jẹ pe jagidijagan ba bẹ silẹ ni apa ibi kan lorilẹede rẹ, to si fẹ ki alaafia jọba lẹyin ti wọn ti tapa si ofin.
Amọ o si gbọdọ jẹ pe titapa si ofin yii jẹ ohun to lagbara pupọ, to si le da ilu ru."
Opatola ni ohun to ṣe koko ni ọrọ bawo ni aarẹ ṣe le lo ilu o fararọ yii nitori agbara ti ofin fun Aarẹ ni pe o gbọdọ ri pe oun siṣẹ pẹlu ohun ti ofin sọ pẹlu ilana rẹ ti ko si gbọdọ si agbara ofin lo.
"Bayii ni ilu o fararọ ṣe ma n sisẹ? Ni akọkọ, a ni lati bẹrẹ pẹlu pe ta ni o n ṣe alakoso ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ Ologun?
Aarẹ lo n dari awọn mejeeji, ti itapa ofin nla ba waye ni agbegbe kan, ẹni to ni agbara lati kesi ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ Ologun, ni o le kesi wọn lati mu alaafia jọba.
"Gomina kọ lo n dari awọn ẹsọ alaabo, ti wọn si le ma gbọ ọrọ si lẹnu nitori aarẹ ni ọga agba fun wọn."
Opatola ni bi aarẹ se ni agbara lati kede ilu o fararọ yii, ni ko tun ni agbara lati yọ gomina, tabi wọgile ile igbimọ aṣofin ti wọn fi ibo gbe wọle gẹgẹ bii ohun ti ofin sọ.
"Ki i ṣe yiyọ nikan, koda ko ni agbara lati da wọn duro fun igba diẹ.
Ṣugbọn o le se e, ti Gomina ma wa lori ijokoo, ti aarẹ yoo si maa lo agbara ti ofin fun un."
"Ẹ ko si le fi iya jẹ Gomina pe ilu o fararọ nitori ko ni agbara lori awọn ẹsọ alabo"
Opatola tun tọka si iwe ofin ọdun 1999, abala 305 nibi to ti ni irufẹ iṣẹlẹ bayii nilo ajọsepọ Aarẹ ati Gomina lati koju iṣoro naa.
"Ti Gomina ba ri pe wahala naa fẹ pọ ju agbara rẹ lọ, o le kọ iwe si Aarẹ pe ko kede ilu o fararọ nipinlẹ rẹ, ohun ti ofin sọ niyẹn, ofin ko ni aarẹ le da gomina duro fun igba diẹ.
"Iwe ofin wa ṣalaye ọna ti a le gbegba ti a ba fẹ yọ Gomina tabi Igbakeji rẹ nipo, ati ti a ba fẹ yọ ọmọ ile igbimọ aṣofin nipo.
"Aarẹ ko ni agbara kankan lati yọ ẹnikẹni ti wọn dibo yan yọ nipo, ẹ ko si le fi iya jẹ Gomina pe ilu o fararọ nitori ko ni agbara lori awọn ẹsọ alabo.
"Aarẹ ko se ẹtọ rẹ lati lo ẹsọ alaabo koju awọn iṣoro to n ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers."
Labẹ ofin, nibo ni agbara alakoso ti aarẹ Tinubu yan nipinlẹ Rivers ti bẹrẹ, to si pari si?
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu kede ọgagun Ibokette Ibas, gẹgẹ bii ẹni ti yoo maa ṣakoso ipinlẹ Rivers fun oṣu mẹfa gbako.
Ṣugbọn ki ni ofin sọ nipa ohun ti Ọgagun yii le ṣe ati eyi ti ko le ṣe lasiko to n mojuto ijọba ipinlẹ naa?
Opatola ni akọkọ, Ọgagun yii ni ofin ko fi aye gba rara nitori ofin ko fun aarẹ ni agbara lati yọ Gomina naa.
"Itapa ofin gba ni eeyan ti Tinubu yan nitori Gomina si wa lori ijoko, Aarẹ o le yọ Gomina rara."
Opatola ni ohun to yẹ ki aarẹ Tinubu ṣe ni ko ba Gomina ati ọmọ ile igbimọ aṣofin ṣiṣẹ papọ, ko si ran awọn ọlọpaa ologun wa si ipinlẹ naa
Gomina ipinlẹ Rivers ti aarẹ Bola Tinubu da duro fun oṣu mẹfa, Siminalayi Fubara ti ba awọn araalu lori igbesẹ Aarẹ lati da oun, igbakeji ati awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin duro fun oṣu mẹfa.
Fubara ninu atẹjade to fi lede dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Rivers, to si jẹ ko di mimọ pe gbogbo igbesẹ ti oun ti gbe lati igba to di Gomina ipinlẹ naa lo wa ni ilana ofin orilẹede Naijiria.
O ni ijọba oun ri daju pe o daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, ti ilọsiwaju si n de ba ipinlẹ Rivers.
"Pẹlu bi a se ni kudiẹkudiẹ nipa iṣelu, a ri daju pe a siṣẹ pẹlu ilana ofin , ti a si fi awọn eeyan wa siwaju.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Gomina Fubara tsiwaju pe "Nitori ẹ ni lẹsẹkẹsẹ ti Aarẹ gbe igbesẹ lati mu alaafia jọba, a ko duro lati tẹwọgba ohun ti aarẹ fẹ pẹlu erongba rere.
"A gba awọn kọmisana to fi ọwọ ara wọn kọwe fipo silẹ. Bakan naa ni a tun tẹwọ gba idajọ ile ẹjọ.
"Gbogbo awọn igbesẹ ni ko jẹ fun imọraẹni nikan ṣugbọn lati ri pe alaafia jọba nipinlẹ wa.
"O ṣeni laanu pe gbogbo ipa wa lo ja si pabo lati ọwọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, ti wọn ko fi aye silẹ fun alaafia lati jọba.
Fubara ni otitọ ni pe ija oṣelu wa ṣugbọn ijọba rere n tẹsiwaju , ti awọn si n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ deede pẹlu ọpọ iṣẹ a kan se kaakiri ipinlẹ naa.
"Lori gbogbo ẹ, Alaafia ni ipinlẹ Rivers wa labẹ ijọba wa.
"Lọwọ yii, mo n rọ awọn eeyan ipinlẹ Rivers lati tẹsiwaju pẹlu igbe alaafia, ki wọn si ma tẹle ofin.
A o ri pe a ba awọn eeyan ti ọrọ kan sọrọ lati ri pe ijọba awarawa duro digbi nipinlẹ Rivers."
Bẹẹ ba gbagbe, Aare Bola Tinubu kede ilu o fararọ ni ipinlẹ Rivers nitori laasigbo oṣelu to n waye nibẹ.
Nibi ọrọ ti aarẹ bawọn ọmọ orilẹ ede Naijiria sọ ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kẹta lo ti sọrọ naa.
Tinubu ni laasigbo oṣelu to n waye ni ipinlẹ naa lati bii oṣu meloo kan sẹyin n kọ oun lominu.
O ni gbogbo igbiyanju oun lati ri pe ifanfa naa wa sopin lo ja si pabo.
















