Wo àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́wàá láti yọ gómìnà nípò

Gómìnà Fubara

Oríṣun àwòrán, Siminalayi Fubara/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kìí ṣe ohun tuntun láti yọ gómìnà tàbí àwọn tí wọ́n bá yàn sípò òṣèlú ní Nàìjíríà.

Yíyọ gómìnà nípò wà ní ìbámu lábẹ́ òfin Nàìjíríà àmọ́ tó ní àwọn ìgbésẹ̀ tó rọ̀ mọ láti ri dájú pé wọn kò máa ṣe é lọ́nà tí kò tọ́.

Àmọ́ síbẹ̀, àwọn olóṣèlú máa ń kó ipa tó lóòrìn lórí yíyọ gómìnà nípò.

Gẹ́gẹ́ bí abala 188 ìwé òfin Nàìjíríà ṣe sọ, ìgbésẹ̀ láti yọ gómìnà kan nípò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá buwọ́lu ẹ̀sùn pé gómìnà ṣe aṣemáṣe tí wọ́n sì gbe é síwájú olórí ilé aṣòfin láti fi ṣọwọ́ sí gómìnà.

Gómìnà ní ẹ̀tọ́ láti fèsì sí ẹ̀sùn tàbí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n bá fi kàn-án kó tó di pé ilé aṣòfin yóò dìbò bóyá láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbésẹ̀ láti yọ gómìnà náà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin fi ààyè gbà láti yọ gómìnà nípò, ipa kékeré kọ́ ni ipò àwọn olóṣèlú máa ń ní lórí ètò ìdìbò.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ ni ilé ẹjọ́ tún le yí ìyọnípò gómìnà padà tí wọn kò bá tẹ̀lé ìlànà àti ìgbésẹ̀ tó yẹ láti yọ ọ́ nípò.

Àwọn ìgbésẹ̀ yìí ni ìlànà láti yọ gómìnà nípò ní Nàìjíríà:

  • Bíbuwọ́lu ìwé ẹ̀sùn

Ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ kọ̀wé, kí wọ́n sì buwọ́lùú láti fẹ̀sùn kan gómìnà lórí àwọn ìwà aṣemáṣe.

  • Ìwé ẹ̀sùn yìí ni wọ́n máa gbé fún olórí ilé aṣòfin.
  • Fífi ìwé ẹ̀sùn ránṣẹ́
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹ́yìn táwọn aṣòfin bá ti gbé ìwé ẹ̀sùn náà kalẹ̀ fún olórí ilé ni ó máa fi ẹ̀dà rẹ̀ ṣọwọ́ sí gómìnà àtàwọn aṣòfin kọ̀ọ̀kan láàárín ọjọ́ méje.

  • Èsì gómìnà

Gómìnà ní àǹfàní lábẹ́ òfin láti fèsì sáwọn ẹ̀sùn tí wọ́n bá fi kàn án, ó sì le má fèsì tí kò bá wù ú.

Gbogbo èsì tó bá fọ̀ ni wọ́n máa fi ránṣẹ́ sáwọn sí gbogbo àwọn ọmọ ilé aṣòfin.

  • Ìdìbò àwọn aṣòfin

Láàárín ọjọ́ mẹ́rìnlá tí wọ́n bá ti fi ìwé ẹ̀sùn ránṣẹ́ sí gómìnà, ilé aṣòfin gbọ́dọ̀ gbé àbá kan kalẹ̀, láì jíròrò le lórí bóyá kí wọ́n ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn náà.

Kí èyí tó le kẹ́sẹ járí, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta àwọn ṣòfin náà gbọdọ̀ ṣe àtìlẹyìn pé kí àbá náà tẹ̀síwájú.

  • Ṣíṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ olùwádìí

Tí ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta àwọn aṣòfin kò bá buwọ́lu àbá láti ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n bá fi kan gómìnà, ètò yíyọ gómìnà yóò parí síbẹ̀ lẹ́ṣẹ̀kẹsẹ̀.

Àmọ́ tó bá kẹ́sẹ járí, olórí ilé aṣòfin náà, láàárín ọjọ́ méje tí wọ́n bá buwọ́lu àbá náà yóò sọ fún adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti ṣàgbédìde ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje tó máa ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan gómìnà.

Àwọn tó máa wà nínú ìgbìmọ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ àwọn tó ṣe é fi ọkàn tán, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba, ọmọ ilẹ aṣòfin tàbí jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan.

  • Ìwádìí àti èsì gómìnà

Ìgbìmọ̀ náà gbọdọ̀ parí ìwádìí, kí wọ́n sì gbé èsì ìjábọ̀ wọn kalẹ̀ láàárín oṣù mẹ́ta tí wọ́n bá yàn wọ́n.

Lásìkò ìwádìí yìí, gómìnà ní àǹfàní láti wí àwíjàre tirẹ̀ náà, tó sì lè rán àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ láti ṣojú rẹ̀.

  • Ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí

Ìgbìmọ̀ olùwádìí ní àṣẹ láti ṣe ìwádìí rẹ̀ lọ́nà tí ilé aṣòfin bá là kalẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìwádìí, pọn dandan fún wọn láti gbé àbọ̀ ìwádìí wọn kalẹ̀ fún ilé aṣòfin láàárín oṣù mẹ́ta.

  • Àgbéyẹ̀wò ìjábọ̀

Tí ìwádìí ìgbìmọ̀ náà bá ṣàwárí rẹ̀ pé gómìnà kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, ìgbésẹ̀ ìyọnípò náà máa parí síbẹ̀ nìyẹn.

Ṣùgbọ́n tí ìgbìmọ̀ náà bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ẹ̀sùn náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ilé aṣòfin yóò gba ìjábọ̀ náà wọlé, tí wọ́n yóò sì gbé yẹ̀wò fún ìtẹ̀síwájú rẹ̀.

  • Ìbò ìkẹyìn láti yọ ọ́ nípò

Kí wọ́n tó lè gbà ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí náà wọlé, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta àwọn ọmọ ilé gbọdọ̀ fẹnukò le lórí. Tí wọ́n bá ti fẹnukò le lórí, ó túmọ̀ sí pé wọ́n ti yọ gómìnà nípò nìyẹn láti ọjọ́ náà.

  • Fífi òfin de

Ìgbésẹ̀ àti ìlànà ìgbìmọ̀ olùwádìí tàbí ti ilé aṣòfin lórí ìyọnípò gómìnà kò lè jẹ́ ohun tí wọ́n le gbé lọ sílé ẹjọ́ tàbí ṣàgbéyẹ̀wò nílé ẹjọ́ kankan.