Iléejọ́, ẹ pàṣẹ fún EFCC pé kó gba dúkìá mi padà lọ́wọ́ àwọn tó tà wọn fún, kò lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin - Diezani Alison-Madueke

Diezani Alison-Madueke

Oríṣun àwòrán, @NigeriaStories

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita tẹlẹ fun ọrọ epo bẹntiro ni Naijiria, Diezani Alison-Madueke, ti rọ ile ẹjọ giga kan l'Abuja lati kan an nipa fun ajọ EFCC lati gba gbogbo dukia oun ti ajọ naa gbẹsẹle lọwọ awọn ti wọn ta a fun.

Ṣaaju ni EFC C ti kọkọ lu awọn dukia naa ni gbanjo lẹyin ti ajọ ọhun tu aṣiri bi Dieziani ṣe lu owo ilu ni ponpo.

Agbẹjọro obinrin naa, Mike Ozekhome (SAN), bẹ ile ẹjọ pe ko wọgile ikede EFCC lati ta awọn dukia naa laarin ọjọ kẹsan an, si ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2023.

Diezani sọ pe igbesẹ EFCC naa lodi si awọn ofin kan to sọ pe afurasi ni ẹtọ lati ṣalaye ti ẹnu rẹ ṣaaju igbese tabi idajọ idajọ kankan.

Ninu ipẹjọ rẹ to ni nọmba FHC/ABJ/CS/21/2023, Diezani ni lilu awọn dukia oun ni gbanjo ko ba ofin mu ati pe EFCC ko lagbara lati ṣe bẹẹ.

Ni bayii, o ti n bere aṣẹ lọwọ ile ẹjọ lati fofin de EFCC ko ma baa ta awọn dukia naa mọ.

Agbẹjọro rẹ sọ niwaju adajọ Inyang Ekwo pe awọn ti pe ẹjọ mii lori ọrọ naa, awon si ti fi iwe nipa ẹjọ ọhun ṣọwọ si EFCC.

Agbẹjọro naa wa bere pe ki adajọ sun igbẹjọ ti EFCC pe tako igbesẹ awọn siwaju.

Bo tilẹ jẹ pe adajọ gba lati ṣe bẹẹ, o jẹ ko ye awọn agbẹjọro ikọ mejeji pe wọn ko gbọdọ fi igbẹjọ ọhun falẹ rara nitori o ṣe pataki fun awọn ọmọ Naijiri lati ri ẹyhin rẹ.

Lasiko to n fesi, agbẹjọro EFCC sọ pe ki ile ẹjọ da ẹbẹ Dieziani nu.

EFCC sọ pe awọn laṣẹ lati lu awọn dukia naa ni gbanjo nitori awọn gbẹsẹle lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ rẹ lọdun 2019.

Agbẹjọro EFCC, Oyakhilome Ekienabor, sọ pe iwe aṣẹ ile ẹjọ to gbẹsẹle dukia naa ṣi wa ni ikawọ awọn, nitori naa awọn ko ru ofin kankan lati maa ta awọn dukia ọhun.

Ekienabor fi kunpe Dieziani funra rẹ wa ninu ile ẹjọ lọjọ ti adajọ gbẹsẹle awọn dukia naa.