Wo àwọn ẹ̀sùn tí Ilé aṣòfin Rivers fi kan Gómìnà àti igbákejì rẹ̀ láti yọ wọ́n nípò

Martin Amaewhule àti Gómìnà Fubara
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Níṣe ni ìfaǹfà ọ̀rọ̀ òṣèlú tó ń lọ ní ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers ti bá ọ̀nà mìíràn yọ báwọn aṣòfin ṣe ń fẹ̀sùn kan Gómìnà Siminalayi Fubara àti igbákejì rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ngozi Odu fún ìwà àṣemáṣe.

Àwọn aṣòfin mẹ́rindínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ń fẹ̀sùn kan gómìnà àti igbákejì rẹ̀ ọ̀hún nínú ìwé àkọránṣẹ́ kan tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí olórí ilé aṣòfin, Martin Amaewhule lọ́jọ́ Ajé.

Àwọn aṣòfin náà ni ìgbésẹ̀ àwọn wà ní ìbámu pẹ̀lú abala 188 ìwé òfin Nàìjíríà àtàwọn ìwé òfin mìíràn tó pọn ọ́n ní dandan fún ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn aṣòfin láti buwọ́lu ìwé ẹ̀sùn tí wọ́n bá fi kan gómìnà bẹ́ẹ̀.

Níbi ìjòkó ilé tó wáyé lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni àwọn aṣòfin náà gbé ìwé ẹ̀sùn náà kalẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí òfin, olórí ilé gbọdọ̀ fi ìwé ẹ̀sùn náà ránṣẹ́ sáwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kan ọ̀hún àtàwọn aṣòfin tó kù láàárín ọjọ́ méje.

Àwọn ẹ̀sùn márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n fi kan gómìnà àti igbákejì rẹ̀.

Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan gómìnà Fubara nìyí:

Lẹ́tà tí olórí ilé aṣòfin fi ránṣẹ́ sí gómìnà Fubara
  • Níná owó ìlú lọ́nà àìtọ́
  • Dídènà ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers, tó jẹ́ ẹ̀ka ìjọba mìíràn láti ṣe ojúṣe rẹ̀
  • Yíyan àwọn èèyàn sípò ìjọba láì ṣe àyẹ̀wò àti ìwádìí tó yẹ nípa wọn
  • Kíkọ̀ láti san owó oṣù àti àjẹmọ́nú àwọn aṣòfin tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers
  • Kíkọ̀ láti san owó oṣù akọ̀wé ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers, Emeka Amadi

Gómìnà Fubara kò ì tíì sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn yìí.

Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan igbákejì Gómìnà Ngozi Odu

  • Lílẹ̀dí àpòpọ̀ àti ṣíṣe àtìlẹyìn fún Gómìnà Fubara láti yan àwọn èèyàn sípò ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers láì ṣe àyẹ̀wò àti ìbuwọ́lù tó yẹ.

Àwọn aṣòfin ń retí èsì Gómìnà Fubara

Lẹ́yìn tó gba ìwé ẹ̀sùn náà, olórí ilé aṣòfin, Amaewhule fi ẹ̀sùn náà ránṣẹ́ sí Gómìnà Fubara tó sì ní kí gómìnà fèsì sáwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án náà.

Amaewhule sọ pé gẹ́gẹ́ bí òfin,láàárín ọjọ́ mẹ́rìnlá ni ilé máa fẹnukò bóyá kí àwọn ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn náà tàbí kí àwọn má ṣe ìwádìí rẹ̀.

Èyí ló wà nínú ìwé àkọránṣẹ́ tí olórí ilé náà fi ránṣẹ́ sí gómìnà Fubara.

Bí Gómìnà Fubara àti igbákejì rẹ̀ yóò ṣe fèsì sáwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n yìí kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni.

Bákan náà ni àwọn aṣòfin náà tún ránṣẹ́ sí àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC láti ṣe ìwádìí akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers, Dókítà Tammy Danagogo fẹ́sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ lásìkò rẹ̀.