Amosun wó iléeṣẹ́ símẹ́ńtì mi lẹ́ẹ̀mejì, Abiodun ló ń fẹ́ kí padà sí Ogun - Dangote

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Ileeṣẹ Dangote, Aliko Dangote ati Gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ni wọn ti bẹrẹ si ni sọko ọrọ si ara wọn lori ileeṣẹ simẹnti to wa ni itori.
Dangote fẹsun kan gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun pe o wo ileeṣẹ simẹniti rẹ meji to wa ni agbegbe Itori nijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ naa.
Dangote ni eyi lo fa ti oun fi mu idaduro ba okowo oun titi Gomina Dapo Abiodun fi gba ijọba.
Ọrọ yii lo jade lasiko ti Dangote se abẹwo si Gomina Dapo Abiodun niluu Abeokuta.
"Ileeṣẹ ti a n lọ yii lo wa ni Itori, to si jẹ pe nitori ọlọlajulọ ni a fi ni anfani lati pada wa.
Igba meji ni wọn da wo. A bẹrẹ si ni ma kọ, ti Gomina Amosun si tún da wo."
"NI igba keji ti a tun bẹrẹ si ni ma kọ, o tun dawo. Eyi lo jẹ ka kuro. Ṣugbọn bayii, a n pada nitori ọmọ iya mi, Dapo Abiodun.
Ileeṣẹ yii ni yoo sọ ipinlẹ Ogun di ipinlẹ ti wọn ti n pese simẹniti ju lorilẹede Naijiria pẹlu apapọ simẹti milọnu mẹfa lọdun.
Ẹ ni ki Dangote mu ẹri jade, iro lo n pa - Amosun fun un lesi
Nigba to fesi si ọrọ naa, Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti wọgile ọrọ ti Aarẹ ileeṣẹ Dangote, Aliko Dangote sọ pe o da ileeṣẹ simẹnti rẹ wo lasiko iṣejọba rẹ̀.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Lanre Akinwale buwọlu fun awọn akọroyin, Amosun ni to ba da Dangote loju pe otitọ ni ọrọ to n sọ, ko fi iwe aṣẹ ijọba lati kọ ileeṣẹ naa han sita fun araalu.
Amosun ni ijọba oun gbagbọ pe ko le si ijọba meji nipinlẹ kan, ati pe Dangote ko gbe igbesẹ to kọja ofin tabi ma sisẹ labẹ ofin miiran.
"Mo ma duro lati gbọ lẹnu rẹ, ṣugbọn mo nifẹ lati sọ pe ki i se gbogbo ọmọ Naijiria ni eeyan le dunkoko mọ."
Gomina tẹlẹ naa tun ranti ọrọ ti Dangote sọ lasiko to n si ileeṣẹ Simẹnti rẹ to wa ni Ibase.
O ni Dangote kan sanra si iṣejọba oun fun bi o ṣe jẹ ki ileeṣẹ naa waye, to si tun naka abuku si ijọba ana.















