Igbó ló máa ń fún mi ní ìmísí láti kọ ìtàn, mò ń mu igbó gan ni – Ijoba Lande

Ijoba Lande

Oríṣun àwòrán, Ijoba Lande

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ oṣere to tun maa n ṣe awada ori ayelujara, Kehinde Ganiyu, ti ọpọ mọ si Ijoba Lande, ti sọ pe oun maa n fa igbo ati pe igbo ọhun lo maa n fun oun ni imisi lati kọ awada ori ayelujara.

Lande lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan lori eto Oyinmomo.

Ọrọ yii lo jade lasiko ti atọkun bere lọwọ rẹ boya o ti fi igbo mimu silẹ, to si ṣalaye anfani ti igbo n ṣe fun oun.

"Ti mo ba mu igbo tan, ti iyawo mi ba fẹ gba ogun miliọnu naira, mo maa fun ni owo naa tori inu mi maa n dun ni"

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ti fi igbo silẹ lasiko kan, amọ oun tun ti pada bẹrẹ si n mu igbo naa latari bo ṣe maa n fun oun ni imisi.

O ni "Igbo lo maa n fun ni imisi lati ṣe awọn ohun ti mo n ṣe, ere ti mo fẹ ẹ le sọ pe o jẹ ki ẹyin gan mọ mi, igbo ni... Mo n mu igbo ni tootọ ni.

"Mi o gba awọn eeyan nimọran lati maa mu igbo... mi o ki n fi pamọ, mo maa n jẹ ki gbogbo eeyan mọ pe mo n mu igbo."

Lande sọ pe oun kii dibọn fun awọn eeyan pe oun n mu igbo, oun si maa n jẹ ki awọn to sunmọ tete irufẹ ti oun jẹ, ko si si nnkan babara kankan nibẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Lande kii ṣiṣe to ba mu igbo tan, bẹẹ ni kii hu iwa ẹni ri ori rẹ yi lẹyin naa.

O tẹsiwaju pe "Ti mo ba mu igbo tan, ti iyawo mi ba fẹ gba ogun miliọnu naira lọwọ mi, mo maa fun ni owo naa nitori inu mi a maa dun ni."

Bo tilẹ jẹ pe o ni igbo le yi awọn eeyan kan lori ti wọn ba mu u tan, kaka ko ṣe oun bẹẹ, niṣe ni igbo maa n fun oun layọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹnu ọjọ mẹta yii ni Ijoba Lande bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara lẹyin to fẹsun kan iyawo rẹ pe o ba ọkunrin mọkanlelogun ni ibalopọ.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu Biola Bayo, iyawo rẹ ọhun, Darasimi, sọ pe oun naa maa n mu igbo, koda oun oun ati Ijoba Lande ni wọn jọ maa n mu igbo naa ti wọn ba fẹ da inu ara dun ninu ile.