Ìjì líle kọlu Amẹrika, èèyàn 34 pàdánù ẹ̀mí wọn

US tornadoes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan mẹrinlelọgbọn lo ti jade laye nilẹ Amẹrika lẹyin iji lile to kọlu ilẹ naa.

Eyan mejila lo padanu ẹmi wọn ni Missouri nikan ṣoṣo nigba ti iji naa bẹrẹ si n gbe ọkọ ayọkẹlẹ to si n bi awọn ile gbigbe wo.

Ni Kansas, eeyan mẹjọ lo ku nigba ti ọkọ bii marunlelaadọta kọlu ara wọn nitori afẹfẹ to gba igboro kan.

A tun gbọ pe ile ti iye rẹ to 250,000 ni ko ni ina ijọba bayii ni ipinlẹ meje ọtọtọ ninu eyii ti Michigan, Missouri ati Illinois wa.

Awọn onimọ so pe oju ọjọ ti ko fararọ yoo tun tẹsiwaju nilẹ naa laarin ọjọ diẹ si asiko yii.

Ijọba awọn agbegbe bii Louisiana, Georgia, Tennessee ati Florida Panhandle ti kilọ pe o ṣeeṣe ki irufẹ iji lile naa kọlu apa ọdọ wọn.

Gomina Tate Reeves sọ pe ni Mississippi, eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn nigba ti iji naa kọlu agbegbe wọn.

Ni Mississippi, Louisiana, Tennessee, Alabama ati Arkansas, wọn ti kede pe o ṣeeṣe ki agbara omiyale kọlu awọn agbegbe kan nibẹ.

Ajọ National Weather Service (NWS) kilọ pe awọn omiyale naa le mu ẹmi lọ.

NWS sọ pe "Ti o ba n gbe lawọn agbegbe wọnyii, fi ara rẹ pamọ titi ti iji lile naa yoo fi pari."

Awọn aworan lati Amẹrika ṣafihan bi iji lile naa ṣe n fa awọn ile ya bii beba.