Ọkùnrin tí ìdá 95% ojú rẹ̀ jẹ́ kìkì irun gba àmì ẹ̀yẹ
Ọkunrin ọmọ orilẹede India kan, Lalit Patidar, ti gba ami ẹyẹ Guiness World Records gẹgẹ bii ẹni to ni irun loju julọ ni gbogbo agbaye.
Bo tilẹ jẹ ọpọ igba lawọn akẹgbẹ rẹ nile ẹkọ maa n fi ṣe ẹlẹya nigba ti wọn kọkọ pade rẹ latari bi oju rẹ ṣe ri, o ni oun ko jẹ ki iwa wọn ba oun ninu jẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, Patidar sọ pe awọn akẹgbẹ oun nile ẹkọ ko kọkọ tẹwọ gba oun amọ wọn pada ri oun gẹgẹ bii ọkan lara wọn bo tilẹ jẹ pe oun yatọ.

Oríṣun àwòrán, Guinness World Records
O ni "Awọn ọjọ akọkọ nile ẹkọ ko dara pupọ nitori awọn eeyan; awọn ọmọ mii n bẹru mi.
"Amọ nigba ti wọn bẹrẹ si n mọ mi, nigba ti wọn bẹrẹ si n ba mi sọrọ, wọn mọ pe mi o yatọ si wọn.
"Wọn tun ri pe ita ni mo ti yatọ, mi o yatọ ninu."
Awọn onimọ sọ pe arun naa ko wọnpọ rara latari pe nnkan bii aadọta eeyan pere lo ni arun naa ninu itan.
Orukọ aisan to n ṣe Patidar ni awọn onimọ pe ni "hypertrichosis" tabi "Werewolf Syndrome," eyii to maa n jẹ ki irun to pọ ju hu lara eeyan.






