Kehinde Subair, ọmọ ilé ìgbìmọ̀-aṣòfin Oyo tẹ́lẹ̀ jáde láyé

Aworan Hon Kehinde Subair

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọju tẹlẹri nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, Kehinde Subair jade laye.

Sẹnẹtọ to n soju aarin gbungbun Oyo ni ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnẹtọ Yunus Akintunde lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi lede fun awọn akọroyin.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni, Subair jade laye niluu London ni aṣalẹ Ọjọbọ, Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2025.

Ninu atẹjade naa, Akintunde ṣapejuwe iku Subair Kehinde gẹgẹ bii ajalu nla fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress nipinlẹ Oyo ati orilẹede Naijiria.

"Iroyin iku yii ba mi lojiji ni owurọ oni nigba ti mo gbọ pe Hon Kehinde Subair, ọrẹ mi, to tun jẹ ọmọ oṣelu APC jade laye.

"Iku rẹ fi aye nla silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu wa, ti yoo si nira fun ẹnikẹni lati rọpo ipo olori to nifẹẹ alaafia to dimu.

"Mo n ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi to fi silẹ ati gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo to fi tọkantọkan sisẹ fun ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu lapapọ."

Ninu ọrọ rẹ, Ṣẹnetọ Sharafadeen Alli ti ba awọn mọlẹbi ati ẹgbẹ oṣelu APC kẹdun lori iku Kehinde Subair.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Akeem Abass fi lede fun awọn akọroyin, o ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ ọrẹ timọtimọ.

"Eyi ba ni lọkan jẹ pupọ. Mo padanu ọrẹ mi to sunmọ mi. Ajalu nla ree fun ẹgbẹ oṣelu APC ati ipinlẹ Oyo"

Ta ni Kehinde Subair?

Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹta ọdun 1965 ni wọn bi Subair Kehinde Hassan niluu Ibadan.

O lọ si ile ẹkọ Ibadan City Council, ile ẹkọ alakọbẹrẹ Oke Oluokun ni to ti gba iwe ẹri ni ọdun 1976.

O tẹsiwaju lọ si Ibadan City Academy Eleta, Ibadan to si jade ni ọdun1983.

O ni iyawo to si bimọ pẹlu.

Kehinde Subair jẹ eeyan kan to fẹran lati ma ka iwe, to si tun ni imọ nipa ere bọọlu.