Mọ̀ nípa àṣà Gada níbi tí kábíèsí kìí tí lò ju ọdún mẹ́jọ lọ

Awọn to n ṣe ọdun Gada
    • Author, Amensisa Ifa
    • Role, BBC News, Arda Jila Badhasa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n péjọ sí ẹkùn gúúsù orílẹ̀ èdè Ethiopia láti kópa níbi ètò ayẹyẹ àṣà kan tó gbilẹ̀ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ọjọ́ Àìkú ni ayẹyẹ Gada, tó máa ń wáyé fún ọ̀sẹ̀ kan, wá sópin pẹ̀lú gbígbé agbára fún ẹni tó ń gba ipò - èyí tó máa ń wáyé ní ọdún mẹ́jọ-mẹ́jọ.

Láti ọdún pípẹ́ ni àwọn èèyàn Borana ti máa ń ṣe ayẹyẹ yíyan Abbaa Gadaa tuntun ní ọdún mẹ́jọ-mẹ́jọ - níbi tí gbogbo wọn ti máa péjọ sí Arda Jila Badhasa tó wà ní ẹ̀bá ìlú Arero, Ethiopia.

Ó jẹ́ àsìkò láti ṣe ayẹyẹ àkànṣe ètò ìṣèjọba àwaarawa ti wọn àti láti gbé àṣà wọn lárugẹ.

Àwọn tó bá wà ní ààrin ọjọ́ orí kan máa ń wọ aṣọ kan náà, tí ìmúrà sì máa ń yàtọ̀ bí wọ́n bá ṣe ju ara wọn lọ sí.

Ní ọjọ́ tí ó bá ku ọ̀la tí Abbaa Gadaa yóò gba ipò ni wọ́n máa ń ṣe àfihàn àwọn ìmúra tó jojú nígbèsè níbi ti àwọn ilé ti máa ń mú ọ̀pá kan tí wọ́n ń pè ní "siinqee" dání.

Àwọn obìnrin mú igi tí wọ́n gbẹ́ dání, tí wọ́n sì ń yíde pẹ̀lú aṣọ pupa.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Young men wear ostrich feathers on their heads.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Igi tí wọ́n gbẹ́ yìí ní ìtumọ̀ dídá ààbò bo àwọn obìnrin tó máa ń lò wọ́n nígbà tí èdè àìyedè bá wáyé.

Tí ìyàwó ilé kan bá fi ju igi sílẹ̀ láàárín èèyàn méjì tó bá ń jà, ó túmọ̀ sí pé ìjà náà gbọdọ̀ dópin ní kíákíá.

Lásìkò tí wọ́n bá ń yíde níbi ayẹyẹ Gada, àwọn omidan ló máa ń ṣíwájú, táwọn ìyàwó ilé yóò sì máa tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Àwọ̀ aṣọ tí wọ́n bá wọ̀ jẹ́ ohun tó máa ń yà wọ́n sọ́tọ̀.

Àwọn omidan ṣaájú àwọn obìnrin tó kù. Wọn kò wọ aṣọ pupa tàbí mú igi dání bíi ti àwọn ìyàwọ ilé.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Ní àwùjọ yìí, obìnrin kìí jẹ́ ipò Abbaa Gadaa, tàbí wà ní ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà tàbí ní àǹfààní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ náà ní kékeré.

Àmọ́ ipa àwọn obìnrin níbi ètò yẹyẹ náà kò kéré rárá, bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn ni wọ́n máa kọ́ ibùgbé táwọn àlejò tó máa kópa níbi ayẹyẹ náà fún ọ̀sẹ̀ kan máa gbé, tí wọ́n sì tún máa ṣètò oúnjẹ.

Bákan náà ni ètò ìṣèjọba Gadaa, tí ẹ̀ka àṣà àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN fi kún ètò rẹ̀ lọ́dun 2016 fi ààyè gba àwọn obìnrin láti máa kópa níbi àwọn ìpàdé ìlú àti láti máa fi ìpinnu wọn hàn sí Abbaa Gadaa.

Àwọn Borana ń kọ́ ilé pẹ̀lú igi àti ams.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Àwọn ọmọ ọkùnrin tí bàbá wọn ti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Gada tẹ́lẹ̀ nìkan ló lè darapọ̀ mọ́ Gada - wọ́n máa fa irun wọn láàárín orí láti fi ipò wọn hàn.

Bí irun náà bá ṣe kéré sí ni ipò wọn ṣe ga sí.

Ẹni tó fa irun láàárín orí

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ àjọ UNESCO kan ṣe sọ, àwọn òǹpìtàn àtẹnudẹ́nu máa ń kọ́ àwọn èwe nípa ìtàn, òfin, ìṣe, ètùtù, àti gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́ ètò ìṣejọba Gada.

Láti ìgbà tí àwọn ọmọkùnrin bá ti wà ní ọdún mẹ́jọ ni wọ́n ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún wọn.

Tí wọ́n bá ṣe ń dàgbà si ni wọ́n máa ṣe ìdánwò fún wọn láti mọ ẹni tí yóò jẹ olórí lọ́jọ́ iwájú.

Àwọn àgbà máa ń wọ fìlà, tí wọ́n sì máa ń kó àwọn nǹkan tó fi ipò wọn hàn dání.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà, lára àwọn ìdánwò tí wọ́n máa ṣe ni rínrin ọ̀nà jíjìn láì wọ bàtà, pípa ẹran àti ṣíṣe dáadáa sáwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn.

Àwọn ọmọdé tó ṣì ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ máa ń wọ fílà tí wọ́n fi owó ẹyọ ṣe. Àwọn obìnrin tó ti dàgbà ni wọ́n tún ní àǹfààní láti wọ irú fílà náà.

Obìnrin tó ń dé fìlà tí wọ́n fi owó ẹyọ ṣe fún ọmọ rẹ̀ lásìkò ayẹyẹ.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Àwọn ọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni èèyàn le fi ìyẹ́ ti wọ́n máa ń fi sórí dámọ̀. "Baalli" ni wọ́n máa ń pè é ní èdè Afaan Oromo.

Ìkópa wọn lásìkò ayẹyẹ Gada máa ń jẹ́ àǹfàní láti kẹ́kọ̀ọ́, gbáradì àti ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán nítorí àwọn tó wà ní ọjọ́ orí yìí ni wọ́n ti máa ń mọ ẹni tó máa jẹ Abbaa Gadaa lọ́dún 2033.

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa wọ ìyẹ́ sí irun wọn láti fi ipò wọn hàn.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Kókó ohun tó wáyé níbi ayẹyẹ Gada tó kọjá yìí ni gbígbé oyè Abbaa Gadaa sílẹ̀ fún ẹni tó kàn.

Ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri, tó fi mọ́ láti Kenya àti olú-ìlú orílẹ̀ èdè Ethiopia, Addis Ababa, ló ṣe ìrìnàjò láti kópa níbi ayẹyẹ náà. Gómìnà ẹkùn Marsabi wà lára àwọn àlejò pàtàkì.

Guyo Boru Guyo, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì ni wọ́n wà láti jẹ́ Abbaa Gadaa fún ọdún mẹ́jọ nítorí bó ṣe fakọyọ láti ìgbà tó ti wà ní kékeré.

Ọkùnrin tó fi aṣọ funfun pa kájà, tó sì mú ọkọ̀ dání.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa / BBC

Òun ni Abbaa Gadaa kejìléláàádọ́rin (72nd) tó máa jẹ, tí yóò sì máa darí àwọn èèyàn Borana tó ń gbé ní ẹkùn gúúsù Ethiopia àti ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Kenya.

Bákan náà ni yóò máa parí aáwọ̀ tó bá wáyé ní ìlú náà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn.

Lára àwọn nǹkan tó máa ń fa aáwọ̀ ní agbègbè náà ni dída ẹran àti ọ̀rọ̀ omi nítorí ọ̀gbẹlẹ̀ tó máa ń wáyé ní agbègbè náà.

Lásìkò tí òun fi ń ṣe ìjọba yìí, ẹni tí yóò gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ yóò máa parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti tẹ̀síwájú níbi tí òun bá bá iṣẹ́ dé nígbà tí ọdún mẹ́jọ rẹ̀ yóò wá sópin, láti tẹ̀síwájí pẹ̀lú àṣà ọdún pípẹ́ yìí.

Àfikún ìròyìn látọwọ́ Natasha Booty.