Ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa òṣèré, Allwell Ademola tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Allwell Ademola
Ana ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2025 ni Allwell Ademola dagbere faye niluu Eko.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ atawọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata lo ti bẹrẹ si n ṣedaro ẹni ọdun mọkandinlaadọta naa.
Iwọnyii ni awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa oloogbe ọhun.
- Ọdun 1976 ni wọn bi Allwell niluu Eko sinu idile alade kan lati Abeokuta, nipinlẹ Ogun
- Ọdun 1986 lo kọkọ bẹrẹ iṣẹ tiata gẹgẹ bi oṣeremọde lori eto "Animal Games" ti ọpọ n gbadun lori ẹrọ tẹlifiṣọn NTA lọdun naa lọhun
- Oloogbe naa tun maa n kọ orin, oun lo da ẹgbẹ akọrin "Allwell and Company," silẹ lọdun 2002, ti ẹgbẹ naa si gbe awo orin kan jade lọdun 2006
- Ademola ti gba oniruru ami ẹyẹ, lara rẹ ni ipa to ko ninu ere "Hakunde" lọdun 2016
- Lara awọn fiimu ti oun funra ti gbe jade ni "You or I" (2013), "Omo Emi" (2017), ati "Ile Wa" (2018)
- Ademola kekọọ nipa ere ṣiṣẹ, iyẹn, Dramatic Arts ni fasiti Obafemi Awolowo to wa niluu Ile Ife, ipinlẹ Osun
- Yatọ si iṣẹ tiata, oloogbe naa tun jẹ oloju aanu to maa n bu ẹnu atẹ lu awọn nnkan ti ko yẹ lawujọ ni Naijiria
- Ipa ti Allwell ti ni lara iṣẹ tiata ni Naijiria ko kere rara, awọn ohun to ti ṣẹ sẹyin ko si ni ṣe e fọwọ rọ sẹyin
- Ọrọ to gbe jade kẹyin ni fidio to fi soju opo Instagram tẹ, nibi to ti n kọ orin pe oun yoo ri opin ọdun 2025 yii lai mọ pe ọjọ keji rẹ loun yoo dagbere faye
Àwọn òṣèré tíátà ń ṣèdárò Allwell Ademola tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 49

Oríṣun àwòrán, Mr Latin/Instagram
Iku o dọjọ, arun o doṣu, lati ana ọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kejila yii ti gbgbajumọ oṣere, Allwell Ademola, ti jade laye lawọn akẹgbẹ rẹ ti n ṣe idaro rẹ.
Iroyin iku Allwell mi ori ayelujara titi tori ojiji lo ba ọpọ eeyan to gbọ iroyin naa.
Ohun to ya ọpọ lẹnu ni pe gbajumọ oṣere naa si ṣe fidio kan ninu eyi to ti kọrin wi pe oun yoo la ọdun yi ja ni bii ọjọ kan si asiko iku rẹ.
Orin Baba Ara pẹlu akọle ''Bi a ba n joyin, bi a ba n jadun; Ka ma gbagbe pe ajeji la jẹ laye'' ni Odunlade Adelade fi bẹrẹ idaro tiẹ loju opo Instagram rẹ.
Odunlade pariwo ori oun, o si lo aworan to n ṣapujuwe pe inu oun bajẹ, ọkan oun si gọgbẹ gidi gan an loju opo rẹ.
Adekola wa gbadura pe ki Eledua tẹ Allwell si afẹfẹ rere.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Ademola Amusan, ti ọpọ mọ si Mr Latin sọ pe ọkan oun wuwo nigba toun gbọ nipa iku Allwell.
Mr Latin ni ''a ti padanu Allwell Ademola, akọṣẹmọṣẹ olootu ere, adari ere ati akọrin.
Allwell ti fi ipa ti ko le parẹ lelẹ ninu aye gbogbo eeyan to mọ ọ.
Allwell, o wa saye, o ṣe ọpọ nnkan, o si jẹ iwuri fun ọpọ eeyan.
A o le gbagbe rẹ lailai, sun re o.''
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ibeere ni Iyabo Ojo fi bẹrẹ idaro tiẹ nigba to sọ pe ''Ọlọrun, kilode tawọn eeyan rere ṣe n ku ni rewe rewe?
Iyabo ni kayeefi ni iku Allwell jẹ fun oun, amọ, o sọ pe ko ṣeni to le ba Ọlọrun ro ẹjọ.
Gbajumọ oṣere naa wa gbadura wi pe ki Allwell maa sinmi laya Olugbala rẹ.
Muyiwa Ademola ni tiẹ sọ pe iroyin iku Allwell jẹ ọkan lara iroyin to ba oun ninu jẹ julọ.
Agba oṣere naa ni ''mi o tiẹ mọ nnkan ti mo le kọ.
Ṣugbọn ti mo ba ṣẹ ọ lọna kọna, forijin mi.
Ẹ jẹ ka maa ranti pe, ọjọ kan n bọ bayii ti gbogbo wa naa yoo ku.
Ọkan mi gbọgbẹ, mo si fẹ ko fuyẹ.
Emi naa ti darijin ẹnikẹni to ba ṣẹ mi lọkan mi.
Ẹ jẹ ka maa lepa alaafia tori kosi nnkan kan ninu aye yii.
Sun re o Allwell Ademola.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Femi Adebayo naa ko gbẹyin ninu awọn oṣere to n ṣedaro Allwell, o sọ loju opo Instagram rẹ pe iku Allwell ba oun ninu jẹ.
O ni iku to jẹ ẹdun ọkan fun ọpọ eeyan ni tori lojiji lo ṣẹlẹ.
Adebayo wa kẹdun pẹlu ẹbi, ọrẹ ati gbogbo eeyan ti iku Allwell kan.
O gbadura pe ki Eledua tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
Gbajúmọ̀ òṣèré, Allwell Ademola jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Allwell Ademola
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Allwell Ademola ti dagere faye.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, ọgbẹni Bolaji 'Mr Latin' Amusan, lo fidi iroyin iku oloogbe naa mulẹ fun BBC Yoruba
Alẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2025 yii iroyin gbode pe gbajumọ oṣerebinrin naa fi aye silẹ.
Iroyin ni ile iwosan Ancilla, to wa lagbegbe Agege, niluu Eko ni oṣerebinrin ọhun dakẹ si.
Ileeṣẹ iroyin abẹle The Nation jabọ pe alabagbe rẹ kan lo gbe digbadigba lọ sile iwosan naa ki ẹni ọdun mẹtalelogji ọhun to dakẹ lọjọ Abamẹta.
Awọn iroyin to n lọ lori ayelujra amọ ti a ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe ṣadede ni ọkan rẹ dede kọṣẹ lasiko to wa ninu ile.
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, pupọ ninu awọn ojugba rẹ nidi iṣẹ tiata lo ti n kẹdun ipapoda rẹ ọhun.
Allwell Ademola jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ọmọ Adetokunbo Ademola, to jẹ gbajumọ agbẹjọro ati adajọ agba.
Ọpọlọpọ fiimu ni Allwell Ademola ti kopa ninu rẹ.
Yatọ si pe o jẹ oṣere, o tun maa n kọ ere funra rẹ.
Wakati mẹrinlelogun ṣaaju iroyin iku rẹ yii ṣi ni Allwell fi fidio kan lede loju Instagram rẹ pẹlu orin kan to sọ pe "Lorukọ Jesu, mo maa ri opin ọdun yii, ọdun yii ko ni ri opin mi."
Ọpọ awọn ololufẹ Allwell atawọn oṣere tiata mii lo ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ loju opo ayelujara wọn.
Lara awọn to ti n ṣedaro rẹ bayii ni Faithia Balogun, Damola Olatunji, ati bẹẹ bẹẹ lọ.















