Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ajínigbé méjì tó ń ṣọṣẹ́ ní Kwara

Aworan ajinigbe meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ palaba ti segi fun awọn ọkunrin meji kan ti ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede yii mu nipinlẹ Kwara, fun pe wọn jẹ ogbologboo agbesunmọmi ati ajinigbe.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ṣe kede, ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kejila ọdun 2025 yii ni ọwọ ba Abubakar Usman, (Siddi) ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) ati Shehu Mohammadu, (Gide) ẹni ọgbọn ọdun.

Abubakar Usman yii ni awọn ọlọpaa sọ pe o fi ara rẹ han laipẹ yii lori ayelujara, nibi to ti ko obitibiti owo ati nnkan ija jọ.

Ilu Komen, labule Masallaci, eyi to wa nijọba ibilẹ, Kaiama nipinlẹ Kwara ni ọwọ ti ba wọn.

Oniruuru ikọlu to ti waye ni awọn ipinlẹ bii Katsina, Zamfara, Niger ati Kwara ni wọn ni awọn eeyan wọnyi lọwọ si.

Awọn ọlọpaa ẹka ọtẹlẹmuyẹ, pẹlu ifọwọsowọpọ ọlọpaa Kwara ni wọn jọ ṣiṣẹ naa bi wọn ṣe kede.

Wọnyi ni awọn ohun ti ọlọpaa ri gba lọwọ wọn

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Naijiria, Benjamin Hundeyin, fi sita lori awọn tọwọ ba yii, awọn ọlọpaa gba

ọkada tuntun kan, (Honda Ace 125) lọwọ awọn ajinigbe naa.

Iye owo ọkada ọhun bi wọn ṣe wi, to ₦1.85 million.

Awọn ọlọpaa ṣo pe owo ti wọn gba lati ibi ijinigbe ni wọn fi ra a.

Wọn tun ri owo to jẹ idaji miliọnu naira (₦500,000 cash) lọwọ awọn agbebọn naa.

Igbagbọ wa pe lara owo itusilẹ awọn eeyan ti wọn san fun wọn fun ijinigbe ni.

Bakan naa ni wọn tun gba ibọn AK-47 kan to ni ọta ogun (20) ti wọn ko ti I yin ninu lọwọ wọn.

Iwadii awọn ọlọpaa fi han, pe awọn meji yii jẹ ọmọ ẹgbẹ ajinigbe ati agbesunmọmi kan ti wọn buru pupọ.

Bakan naa ni wọn ni awọn yii kan naa ni wọn n pese nnkan ija fun awọn oniṣẹ ibi miran bii tiwọn.

Ṣaa, wọn ti wa ni ahamọ ijọba bayii, nibi ti wọn ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn ẹgbẹ wọn yoku mu.

Abubakar Usman

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police

Àkọlé àwòrán, Abubakar Usman
Abubakar Usman nigba to n ṣafihan owo rẹpẹtẹ lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police