Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ Yoruba Nation gbégi dínà, kọlu ọlọ́pàá lásìkò ọdún Kérésì, ọwọ́ tẹ mẹ́jọ lára wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́jọ kan fẹ́sùn pé wọ́n da omi àlááfíà ìlú rú, péjọ lọ́nà àìtọ́, dídá lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ dúró àti ṣíṣe ìkọlù sí ọlọ́pàá.
Àwọn afurasí náà ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Democratic Republic of the Yoruba ní agbègbè Sango Ota, ìpínlẹ̀ Ogun.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ni agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Oluseyi Babaseyi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ti kéde ọ̀rọ̀ náà.
Gẹ́gẹ́ bí Babaseyi ṣe ṣọ , ní oríta Temidire àti abẹ́ afárá Sango-Ota ni àwọn èèyàn náà ti gbégi dínà ojú ọ̀nà, tí wọ́n sì ṣèdíwọ́ fún lílọ bíbọ̀ ọkọ̀.
"Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Yoruba Nation gbégi dínà lọ́nà àìtọ́, dáná sí ojú ọ̀nà, ṣèdíwọ́ fún lílọ bíbọ̀ ọkọ̀, tí wọ́n sì ṣèkọlù sáwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ láti mójútó òfin orílẹ̀ èdè."
Babaseyi ní "Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Democratic Republic of the Yoruba gbégi dínà lọ́nà àìtọ́, dáná sí ojú ọ̀nà, ṣèdíwọ́ fún lílọ bíbọ̀ ọkọ̀, tí wọ́n sì ṣèkọlù sáwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ láti mójútó òfin orílẹ̀ èdè."
Ó ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá tètè dé agbègbè náà láti ri pé àlááfíà jọba níbẹ̀.
Ó ní bí àwọn ọlọ́pàá ṣe débẹ̀ ni wọ́n nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́jọ tó fi mọ́ Adewale Sosanya, Opeyemi Oladotun, Zara Gabriel, Ajoke Gabriel, Adewale Adebomojo, Yusuf Tanimowo, Olurotimi Ademola, àti Toyin Gabriel.
Bákan náà ló ní àwọn rí àwọn nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn tó fi mọ́ ọkọ̀ Toyota Dyna, tí wọ́n fi gbé àwọn afurasí náà, ẹ̀rọ gbohùngbohùn méjì, pálí tí àsíá orílẹ̀ èdè kún inú rẹ̀, àwọn aṣọ tí wọ́n kọ ẹ̀dùn ọkàn wọn sára rẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó fi kun pé ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni wọ́n máa gbé àwọn afurasí náà lọ sílé ẹjọ́.
Kọmísánà Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Ẹ̀wẹ̀, Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Lanre Ogunlowo sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé ètò ààbò tó péye wà káàkiri ìpínlẹ̀ Ogun.
Kọmíṣánnà náà ṣèkìlọ̀ pé àwọn kò ní fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti da omi àlááfíà ìlú náà rú, tó sì sọ pé gbogbo àwọn tó ṣe ìkọlù sí ọlọ́pàá ni wọ́n máa fojú winá òfin.
Bákan náà ló pàrọwà sáwọn èèyàn láti tètè máa fi ohun tí wọ́n bá ti ri pé ó ṣe àjòjì ní agbègbè wọn tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí.















