Ìjà àgbà méjì bẹ̀rẹ̀ láàrin Abubakar Malami àti EFCC, bó ṣe ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn kíkó dúkìá tó tó N212bn lọ́nà èrú jọ

Amofin Agba Abubakar Malami

Oríṣun àwòrán, Abubakar Malami (SAN)

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ija agba meji to lagbara lo n waye lọwọ laaarin ileeṣẹ to n ri si ajẹbanu lorilẹede yii, EFCC ati Minisita eto idajọ tẹlẹ, Abubakar Malami (SAN).

Ko sohun to bẹrẹ ija naa ju awọn dukia mọkanlelogoji (41) ti owo rẹ to N212bn, ti EFCC fẹsun rẹ kan Malami, pe o fi eru ko jọ lasiko to wa nipo Olootu ati minisita eto idajọ Naijiria.

Awọn ile olowo nla ati ileeṣẹ to kuro ni wasa ni EFCC sọ pe Malami ko jọ ni ilu Abuja, Kano ati Kebbi.

Bakan naa ni wọn si tun fi ẹsun ajẹbanu ati fifi èrú boju kowo, kan akọbi rẹ, Abdul Azeez Malami.

Ni ti awọn dukia to wa ni Kebbi, wọn ṣi iye rẹ si N162,195,950,000, nigba ti wọn ṣi ti Kano si N16,011,800,000.

Owo to to N34,685,000,000 ni wọn ka dukia Malami to wa niluu Abuja si.

Apapọ owo ti wọn ni Abubakar Malami fi eru ko to fi fa dukia rẹpẹtẹ jọ naa jẹ N212bn bi EFCC ṣe sọ.

Lori awọn ẹsun yii ni Malami fi dero ahamọ EFCC lati ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila ọdun 2025, ti ọrọ naa ko si ti i yanju lẹyin aṣẹ kootu.

Tẹ o ba gbagbe, awọn ẹsun wọnyi ni Abubakar Malami ti tako ṣaaju, to ni EFCC n doju sọ oun nitori oun fẹsun aiṣododo kan alaga wọn, Ola Olukoyede.

Malami ni oun ṣetan lati farahan niwaju adajọ, koun si ṣalaye awọn ẹsun ti EFCC fi kan oun, pe ko ri bẹẹ.

Àṣẹ kootu ati idi ti EFCC ṣe kọ lati gba beeli Malami

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, ile ẹjọ giga ilu Abuja, fi aaye beeli silẹ fun Malami ninu idajọ to waye.

Sugbọn EFCC kọ lati fun minisita eto idajọ tẹlẹ naa ni beeli bi aṣẹ kootu.

Idajọ Adajọ Bello Kawu lati fun Malami ni beeli, wa ni ibamu pẹlu ohun ti EFCC ti kọkọ gbe kalẹ.

Alaye EFCC lọjọ kẹrinla ,oṣu Kejila yii ni pe Malami ko ri nnkan marun-un ti kootu ni ko ṣe ko too le lẹtọ si beeli ṣe, wọn ni idi niyẹn to fi wa lahamọ lati ọjọ kẹjọ oṣu kan naa.

Ṣugbọn l'Ọjọru ana, Akọwe iroyin Malami, Mohammed Doka, fẹsun kan EFCC pe wọn tako aṣẹ ile ẹjọ lati fi Malami silẹ lẹyin to ti ṣe ohun ti kootu pa a laṣẹ.

Ninu atẹjade kan ti Doka fi si oju opo Facebook Malami l'Ọjọru lo ti kọ ọ pe:

"Lẹyin aṣẹ ile ẹjọ giga ilu Abuja ti ko ruju, lọjọ kẹtalelogun oṣu Kejila ọdun 2025, to fi aaye silẹ fun Abubakar Malami (SAN) lati gba beeli, ti a si ti ṣe ohun to rọ mọ beeli naa, ti awọn EFCC naa si ti gba ẹ̀dà idajọ naa, wọn kọ lati gba lẹta ti kootu fi gbe aṣẹ rẹ lẹsẹ, wọn si n da Malami duro si ahamọ, eyi to lodi si ofin."

Atẹjade naa tun koro oju si bi Malami ṣe n pẹju ni ahamọ, wọn ni eyi tako ẹtọ rẹ bii ọmọniyan.

Bakan naa ni Malami feṣun kan EFCC pe wọn ko gbe oun lọ siwaju ile ẹjọ.

O ni wọn tun n lo awọn akọroyin lati sọ awọn ohun to wu wọn nipa oun.

Ninu alaye Malami ṣaaju lo ti ni lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla ni oun ti ṣeto beeli bi ile ẹjọ ṣe paṣẹ.

O ni EFCC lo yi aṣẹ naa pada.

Ṣugbọn EFCC paapaa tete da a pada, wọn ni loootọ ni wọn fun un ni beeli ranpẹ (Administrative bail) lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kọkanala, ṣugbọn ko ri koko marun-un to de beeli naa muṣẹ.

Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale, sọ pe o yẹ ki Malami yọju fun ifọrọwanilẹnuwo lọjọ kin-in-ni oṣu Kejila, ṣugbọn o bẹbẹ fun isunsiwaju rẹ nitori ailera.

O ni o ṣe eyi nipasẹ lẹta to kọ lọjọ kẹrin oṣu Kejila kan naa.

"Ajọ wa fi oju aanu gba ẹbẹ rẹ, koda nigba ti ko ti i ṣeto beeli naa."

Oyewale sọ pe Malami ko pada mu iwe kankan wa to le fi han pe o ni ailera kankan.

O ni lẹyin eyi ni awọn pe e lọjọ kẹjọ oṣu Kejila, fun iwadii siwaju, awọn si fi i si ahamọ nigba ti ko ri beeli rẹ ṣe.

"Nigba ti ajọ to n ri si iwa ibajẹ ba bẹrẹ si i tako ofin kootu, to n ti araalu mọle, to si n lo awọn oniroyin fun ohun to fẹ, ki i ṣe irinṣẹ idajọ ododo mọ, o ti di ohun to le koba ijọba awaarawa."

Agbẹnusọ Malami lo sọ bẹẹ.

O rọ ẹka idajọ lati tete ri si ọrọ yii.

"Laaarin ọdun 2015 si 2025 ni ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan Malami waye"

Tẹ o ba gbagbe, Abubakar Malami (SAN) ni Olootu ati Minisita eto idajọ lasiko iṣejọba aarẹ ana, Oloogbe Muhammadu Buhari.

O wa nipo naa lati 2015 titi di 2023.

Ojọ kẹtadinlogun oṣu Kejila yii ni EFCC yabo ọfiisi ati ile Malami ni Abuja ati Kebbi.

Diẹ lara awọn dukia ti wọn lo fi ipo rẹ ko jọ lọna èrú naa ree:

Ti ipinlẹ Kebbi ti apapọ owo rẹ jẹ: N162,195,950,000.00:

Rayhaan University and Education

Rayhaan University Permanent Site: N56,000,000,000.00

Rayhaan University Temporary Site: N37,800,000,000.00

Rayhaan University Third Site: N2,450,000,000.00

Rayhaan University Vice Chancellor House: N490,000,000.00

Rayhaan Model Academy: N11,200,000,000.00

Rayhaan Primary and Secondary School: N8,750,000,000.00

Rayhaan Agro Allied Factory & Commercial

Factory Buildings: N4,200,000,000.00

Factory Machines and Plants Units: N10,500,000,000.00

Factory Mosque: N2,450,000,000.00

Ati bẹẹ bẹẹ lọ

Ti ipinlẹ Kano ti apapọ owo rẹ jẹ: N16,011,800,000.00:

Zeennoor Hotel: N11,200,000,000.00

Zeennoor Mosque: N84,000,000.00

Zeennoor Old Hotel Building: N280,000,000.00

Rayhaan Hotel Kano: N2,240,000,000.00

Rayhaan Gym Kano: N1,225,000,000.00

Ile iyawo rẹ (Ahmadu Bello Way, Kano): N982,800,000.00

Abuja : N34,685,000,000.00

Duplex : Amazon Street, Maitama: N5,950,000,000.00

Meethaq Hotel (Jabi Branch): N8,400,000,000.00

Meethaq Hotel (Maitama Branch): N12,950,000,000.00

42 Units Bungalow ni Efab Estate: N385,000,000.00

Harmonia Hotels, Area 11 Garki: N7,000,000,000.00

Apapọ owo: N212,892,750,000