Àjẹ́ Kérésì, kíkó ìgbálẹ̀ pamọ́, àti àwọ̀n àṣà mìí tí o kò gbọ́ rí nípa Kérésìmesì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọna ti awọn orilẹ-ede kọọkan ni agbaye n gba ṣe ajọyọ ọdun Keresimesi ṣọtọọtọ.
Bi ẹbi rẹ ṣe ni awọn nnkan ti ẹ ma n ṣe lasiko ọdun, eyi to ṣeeṣe ko wọpọ ni awọn orilẹede kan, bẹẹ naa ni awọn orilẹ-ede kan wa to ni awọn aṣa ati iṣe to yatọ si ti gbogbo eniyan lasiko ọdun.
Ẹ jẹ ka wo diẹ lara awọn aṣa naa.
Awọn ọmọde ma n ko bata wọn si ẹgbẹ ina ni Netherlands

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni orilẹ-ede Netherlands, to ba ti ku ọjọ diẹ ṣaaju ọjọ Keresimesi, tii ṣe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, awọn ọmọde ma n ko bata wọn si ẹgbẹ ina ara, pẹlu ireti pe baba keresi, yoo ko awọn ẹbun kekeeke ati ipanu sinu wọn laarin oru.
Awọn ọmọ naa ma n fi ‘carrot’ sinu awọn bata naa, gẹgẹ bi ẹbun fun Baba Keresi.
Wọn ma n ko igbalẹ pamọ ni Norway nitori awọn ajẹ
Ni orilẹ-ede Norway, itan abalaye sọ pe ni alẹ ọjọ aisun Keresi, ni awọn ẹmi airi ati awọn ajẹ ma n gbakoso oju ofurufu lati ṣiṣẹ ibi. Igbagbọ wọn ni pe igbalẹ ni awọn ajẹ ma n lo gẹgẹ bi ọkọ̀.
Nitori naa, lasiko ọdun Keresi, awọn eniyan orilẹ-ede Norway ma n ko gbogbo igbalẹ to wa ninu ile wọn pamọ, sibi ti awọn ajẹ ‘ko ti le rina ri’ lati fi fo loju ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baba Keresi buruku
Ohun to wọpọ ni ọpọ orilẹ-ede to ma n ṣe ọdun Keresi ni Baba Keresi, ti awọn elede Gẹẹsi n pe ni Santa Claus. Amọ, ni orilẹ-ede Austria, iyatọ wa. Igbagbọ wọn ni pe ẹda kan to ma n mura bi oku, eyi ti wọn n pe ni Krampus, ma n lọ kaakiri igboro ilu lati ba awọn ọmọ alaigbọran wi.
Ninu oṣu Kejila, awọn eeyan kan ma n mura ni ọna to ba ni lẹru pupọ, pẹlu iboju, wọn si ma n rin kiri lati dẹru ba agbalagba ati ọmọde.
Iru aṣa yii naa wa ni orilẹ-ede Italy, nibi ti àjẹ́ Keresimesi, La Befana, ti ma n lọ kaakiri lati fun awọn ọmọde ni ẹbun - to ba jẹ pe wọn ko hu iwa aigbọran ninu ọdun to n pari lọ.
Eeyan kan lo ma n wọ ẹku naa.
Itan kan sọ pe ajẹ naa tẹle awọn amoye mẹta to lọ ọ ki Jesu Kristi nigba ti wọn bi si ibujẹ ẹran.
Irawọ Keresimesi
Lootọ ni itan ibi Jesu Kristi ninu bibeli sọ pe, irawọ nla kan yọ ni ọrun lasiko ti wọn bi Jesu si ibujẹ-ẹran. Amọ ni orilẹ-ede Poland, irawọ lo ma n ṣe atọna igba ti wọn yoo jẹun lasiko ọdun Keresimesi.
Ni orilẹ-ede yii, to ba di alẹ ọjọ aisun ọdun Keresimesi, ko si bi ebi ṣe le ma pa ọ to, o di igba ti ẹbi rẹ ba to ri ami gba lati ọrun pe asiko ti to lati jẹun.
Nnkan ti eyi tumọ si ni pe awọn ẹbi to jẹ ọmọ orilẹ-ede Poland, kii jẹ ounjẹ alẹ wọn titi di igba ti ẹnikan lara wọn ba kọkọ ri irawọ akọkọ to yọ loju ọrun.
Iru aṣa yii na wa ni orilẹ-ede Ukraine. Ni orilẹ-ede mejeeji, bakan naa ni wọn kii tu ẹbun Keresi wọn wo titi di igba ti wọn ba ri irawọ naa.
Ti irawọ ko ba wa yọ lasiko, ẹnikan yoo mu aba wa pe ki gbogbo ẹbi o jẹun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ethiopia kii ṣe Keresimesi ti wọn ni oṣu Kejila
Aṣa yii le jẹ iyalẹnu pupọ. Botilẹ jẹ pe ni ilẹ Africa ni orilẹ-ede Ethiopia wa, ninu oṣu Kinni ọdun ni awọn ma n ṣe ajọyọ ọdun Keresi ti wọn.
Ọjọ keje, ninu oṣu Kinni ni wọn ma n ṣe e .
Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe kalẹnda to n ṣe onka oṣu ati ọjọ, Julian, ni awọn ara Ethiopia n lo.
Lasiko ọdun Keresimesi, aṣọ funfun ni awọn eeyan ma n wọ, pupọ ninu wọn si ma n wọ aṣọ ibilẹ wọn. Netela. Aṣọ yii jẹ ibori funfun ti wọn fi owu ṣe, amọ o ma n ni ila tẹẹrẹ ti wọn fi oriṣiriṣi awọ ṣe ni isalẹ














