Nítorí àìsí owó, àwọn ọdọ́ 50 yìí gbà láti ṣe ìgbéyàwó wọ́n pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbeyawo ọlọpọ ero lo ti waye laarin aadọta ọkunrin ati awọn iyawo wọn lẹẹkan naa lorilẹede Afganistan.
Irufẹ igbeyawo yii lo wọpọ lorilẹede naa latari bi awọn ololufẹ ti agbara wọn ko gbe afẹfẹyẹyẹ ati inawo igbeyawo ṣe n wa ọna lati ṣee bi wọn ṣe mọ.
Iroyin fi yeni pe awọn alarede naa ni wọn ko si aaye ọtọ ti ko si farahan titi di igba ti awọn alejo fi jẹun tan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ ẹlẹyinju aanu kanlo ṣe agbatẹru ayẹyẹ naa nilu Kabul ni rẹ, ti wọn si tun fun awon mọlẹbi tuntun naa lawọn ohun elo ile diẹ lati bẹrẹ igbesi aye wọn.
Kika ayọka lati inu Kurani n lo waye lẹyin ti oṣiṣẹ ileeṣẹ to n moju to igbelaruge iwa rere ati didẹkun iwa ibajẹ ba awọn ọkunrin naa sọrọ, amọ ko si orin ati ijo leyi ti ijọba Taliban ti fofin de.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan lara awọn ọkọyawo tuntun naa, Roohullah Rezayi, ọmọ ọdun mejidinlogun wi pe ko si bi oun ṣe lee rowo lati da ṣe igbayawo nitori yoo na oun to ẹgbaalelẹgbẹrin si ẹgbẹun mẹta o le ẹgbẹta dollar.
Ọdọmọkunrin naa to wa lati ẹkun Ghor, ti owo to n ri nibi iṣẹ oojọ rẹ ko ju dollar marun lọ wi pe igbeyawo alasopọ yii ko naa awọn ju dollar mejilelogoje si mẹrinlelẹwaalenigba.
Roohulah wi pe “awọn marundinlogoji pere ni awa majeeji pe sibi ayẹyẹ naa, amọ yoo to ọọdunrun si irinwo eeyan to ba jẹ wi pe a daa ṣe ni”.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun awọn kan ninu awọn ọkọyawo tuntun naa, ọjọ igbeyawo ọhun ni wọn ti n foju sọna si tipẹ, gẹgẹ bi wọn ti ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin AFP.
Samiullah Zamani to je agbẹ, ẹni ọdun mẹtalelogun lati ẹkun Kabul, wi pe “lati ọdun mẹta sẹyin ni mo ti n duro de ọjọ oni, n ko si lee duro lati ri aya mi”.
Awọn iyawo alarede naa atawọn ọkọ wọn ni ọkọ ti wọn fi okun tẹẹrẹ alawọ ewe ati ododo pupa ṣẹṣọ rẹ gbe lọkọọkan ejeeji kuro loriko igbeyawo naa.














