Ìdí tí pásítọ̀ Adeboye fi jòkó sórí aga ọba tí orúkọ mi wà – Ọba Orile Igbon ṣàlàyé

Pastor Adeboye

Oríṣun àwòrán, X/rccg_pr

Onile Igbon ti Orile Igbon, Ọba Francis Alao ti sọrọ soke lori awuyewuye to waye lori bi alufa ijọ RCCG, Pasitọ E.A. Adeboye ṣe joko sori aga kan ti wọn kọ orukọ oriade naa si.

Ọba ọhun, to jẹ igbakeji alaga igbimọ awọn lọbalọba ati oloye nipinlẹ Oyo ṣalaye pe aga ti Adeboye joko si kii ṣe eyii to wa fun oun bii ọba.

Ninu atẹjade kan ni Onile Igbon ti ṣalaye pe ko si ootọ ninu iroyin to ni aga itẹ ọba to yẹ ki oun joko si gẹgẹ bii Ọba ni pasitọ ọhun joko si.

O ni “Mo ti gbọ nipa ọrọ ti awọn eeyan n sọ lori yelujara lori bi adari ijọ Redeemed Christian Church of God (RCCG), pasitọ Enoch Adejare Adeboye ṣe joko sori ọkan lara awọn aga aafin.

“Mo fẹ ko ye awọn eeyan pe iṣe iwaasu ihinrere ni Adeboye wa ṣe ni Orile-Igbon eyii to waye ni papa iṣere ile ẹkọ Olugbon High School.

“Ọkọ baalu rẹ balẹ si gbagede aarin aafin, lati ibẹ ni mo ti gbalejọ rẹ ninu yara igbalejo mi. A lo akoko diẹ lati sọrọ nipa Naiiria ati Orile-Igbon ki a to lọ si gbagede eto naa nibi ti ẹgbẹgbẹrun eeyan ti n duro.

“Mo darapọ mọ alufaa naa lọ si gbagede eto ọhun lati ṣatilẹyin fun un nitori ibukun ni eto naa yoo jẹ fun ilu wa, o si gbadura fun ilu wa ati gbogbo awọn to wa nibi eto ọhun.

“Lọna ati ṣe ayẹsi rẹ, mo yọnda ọkan lara awọn ijoko ori ade ti a ti ya sọtọ fun awọn eeyan pataki fun pasitọ naa lati lo lasiko eto naa.”

Ọba alaye naa ṣalaye pe ijọko ti Adeboye joko si kii ṣe eyi ti wọn ya sọtọ fun Olugbon nikan, eyii ti kii ba ẹlomiran pin nitori itan ati nkan iṣẹmbaye to rọ mọ ijoko naa.

O pari ọrọ rẹ pe ijoko ti ọba nikan, eyi to jẹ aga itẹ ọba, wa, bẹẹ ni ijoko awọn eeyan pataki tun wa ni aafin, nitori naa ki awọn eeyan dẹkun ati maa gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa ibi ti alufaa Adeboye joko si.

Ṣé lóòtọ́ ni pásítọ̀ Adeboye gba àga ìtẹ́ nídìi Ọbalayé kan ní ìpínlẹ̀ Oyo?

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni aworan adari agba ijọ RCCG, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye fa ori ayelujara ya nibi to ti joko sori aga Ọba Olugbon ti orile, Ọba Francis Olusola Alao.

Ọpọ araalu lo bu ẹnu atẹ lu aworan naa, ti wọ sin n sọ pe ni ṣe ni ojiṣẹ Ọlọrun naa le ọba alaye ọhun kuro lori aga rẹ, to si joko si i.

Lara awọn eeyan to n jẹ ọrọ naa lẹnu julọ loju opo X ni ọkunrin kan ti orukẹ rẹ n jẹ Arakunrin Alani

Alani sọ pe “Eredi ti a ṣe n sọ pe a ko fẹ ki ẹlẹsin igbagbọ tabi Musulumi jọba nilẹ Yoruba ree.

“Ẹ wo radarada yii, laipẹ yii ni a ri ti ọba kan n dọbalẹ fun pasitọ.

“Ijọ RCCG ni iṣẹ buburu kan ti wọn fẹ ṣe nilẹ Yoruba a ko si gbọdọ gba pasitọ Adeboye laaye ko to pẹ ju.

Ijọ RCCG fesi

Amọ lẹyin ti awọn eeyan bẹrẹ si n jẹ ọrọ naa lẹnu ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu pasitọ Adeboye ni ijọ RCCG funra ṣalaye bi aworan naa ṣe jẹ.

Ninu atẹjade kan ti ẹka ijọ naa to n ri si ọrọ iroyin, RCCG Publuc Relations, fi lede, o ni irọ ni iroyin to ni pasitọ Adeboye ni ki ọba didie kuro lori ijọko rẹ ki oun le joko sibẹ.

Atẹjade naa ni “Pasitọ E.A. Adeboye fẹ lọ waasu lori aga iwaasu, ijoko kan si wa nibẹ, eyii ti wọn ti pese fun un to si jẹ aga kan ṣoṣo to wa nibẹ.

RCCG

Oríṣun àwòrán, @RCCG_PR

“Ko si igba kankan lasiko iwaasu ọhun to sọ fun eyikeyi ninu awọn ọba to wa nibẹ pe ki wọn dide fun oun lati joko.

“O bọwọ fun awọn ọba, o si pọn wọn le pupọ, nitori naa ko le tabuku wọn rara.”

Atẹjade ọhun sọ siwaju si pe pasitọ Adeboye ko fi ara pe Ọlọrun, o si rọ awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiiri nipa ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa ki wọn dẹkun ati maa ṣe bẹẹ.

RCCG pari atẹjade naa pe “Ko sọ fun ẹnikẹni, ko si le sọ fun ẹnikẹni ko fi aga rẹ silẹ fun oun.

“E jọwọ ẹ kọkọ wadii odo ọrọ lati ọọfisi rẹ ki ẹ to maa sọrọ nipa ohunkohun to ni ṣe pẹlu pasitọ E.A. Adeboye”