Àjọ̀dùn Kérésì di ìbánújẹ́ ní Plateau, àwọn agbébọn tún ṣekúpa èèyàn 115

Oríṣun àwòrán, JONATHAN BENJOE/FACEBOOK
O le ni eeyan marundinlọgọfa ti awọn agbebọn tun ṣekupa lasiko ikọlu kan to waye ni ipinlẹ Plateau lọjọ aisun ọdun Keresimesi>
Gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang ṣalaye lori eto ileeṣẹ Mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria, Channels lowurọ ọjọ Iṣẹgun pe ko tii si ẹni le sọ ni pato awọn agbebọn to ṣe iṣẹ ibi yii.
Gomina Mutfwang wi pe “gẹlẹ ti a pari gbogbo imura fun ajọyọ ọdun Keresimesi ni awọn kan ti ko sẹni to tọ wọn nija dede kọlu awọn eeyan wa".
Mutfwang, ti oju rẹ kọrẹ lọwọ, ṣalaye bi awọn oniṣẹ ibi naa ṣe ṣakọlu silu bii mẹẹdogun nijọba ibilẹ Bokkos ati Barkin-Ladi lọjọ Aiku, to jẹ ọjọ aisun ọdun.
Ọpọ ile ni wọn dana sun ti wọn ti wọn si tu ji ọpọlọpọ ire oko ni bi wọn ṣe n kun awọn eeya bi ẹni n kun ẹran.
Mutfwang wi pe “bi mo ṣe n sọrọ yii, a ti sinku awọn mẹẹdogun nijọba ibilẹ Mangu nikan. Laarọ yii, a ti ka oku to le ni ọgọrun nijọba ibilẹ Bokkos, lai ti darukọ ti Barkin-Ladi”.
Gomina naa to ni irufẹ akọlu yii ko waye ri to si kọja afẹnusọ, wi pe awọn eeyan oun ko nii gba ki akọlu naa ko irẹwẹsi ọkan ba wọn, nitori ohun ti awọn to wa nidi akọlu naa n fẹ niyẹn.
Gomina Mutfwang to ni akoko idahun awọn ẹṣo alaabo, paapaa julọ awọn ologun lee ya ju bi wọn ṣe dahun lọjọ naa lo, waa rọ awọn ẹṣọ alaabo naa lati ri pe wọn fi panpẹ ọba mu awọn to wa nidi ọrọ naa.












