Àtúpalẹ̀ ohun tí Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ogun sọ fún Azeez Ijaduade tí ọlọ́pàá kan yìnbọn bà rèé

Oríṣun àwòrán, OgunPoliceNG/Azeez Ijaduade
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiodun Alamutu, ti bu ẹnu atẹ lu bi ọlọpaa ṣe yinbọn lu oṣere tiata Yoruba, Azeez Ijaduade, nipinlẹ naa.
Ọkan lara awọn akẹgbẹ oṣere naa lo kọkọ ke gbajare nipa iṣẹlẹ ọhun loju opo Instagram rẹ bo tilẹ jẹ pe ko ṣlayae ohun to ṣẹlẹ ni pato.
Amọ ninu atẹjade kan ti Omolola Odutola, to jẹ alukoro ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi lede, o ni korofo ọta lasan lo ba oṣere ọhun lasiko ti ọlọpaa kan yinbọn soke nibi ayẹyẹ orikadun kan.
Asiko ti kọmiṣọna naa ṣabẹwo si oṣere Azeez lo bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ọhun.
Nigba to ba awọn akọroyi sọrọ, kọmiṣọna ọlọpaa naa sọ pe ọlọpaa to yinbọn to gbe Azeez dele iwosan yoo jiya to tọ labẹ ofin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, niṣe ni ọlọpaa naa yinbọn soke lati le awọn ọmọ ita kan to n yọ ọmọ orilẹ-ede China to n ṣọ lẹnu.
Alamutu ni ko tọ bi ọlọpaa naa ṣe yinbọn soke, ati pe inu oun dun pe alaafia ni oṣere Azeez wa lẹyin iṣẹlẹ ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe o ni lasiko igba mii, awọn ọlọpaa lẹtọọ lati yinbọn soke lati tu ọpọ ero ka, ṣugbọn kii ni irufẹ iṣẹlẹ bayii.
O fi kun pe iwa ti ọlọpaa naa wu ko bojumu, o si jẹ irufẹ iwa to le dojuti ileeṣẹ ọlọpaa, nitori naa yoo jẹ iya to tọ labẹ ofin.
Lẹyin naa lo ni ki awọn ololufẹ oṣere naa lọ fi ọkan wọn balẹ nitori ara oṣere ọhun ti n balẹ, o si ti n gbadun.
Azeez Ijaduade ti ń gba ìtọ́jú, ara rẹ̀ sì ti ń balẹ̀ lẹ́yìn tí ìbọn ọlọ́pàá bà á – Ẹgbẹ́ àwọn òṣèrè

Oríṣun àwòrán, Azeez Ijaduade
Awọn akẹgbẹ oṣere tiata Yoruba ti iroyin sọ pe ọlọpaa yinbọn lu nipinlẹ Ogun, Azeez Ijaduade ti sọ pe alaafia lo wa.
Ninu fidio kan ti ọkan lara wọn, Abiodun Adebanjo, fi lede lo ti sọrọ naa.
O ni “A kan fẹ ki gbogbo ayẹ mọ ni pe Alaafia ni Azeez wa, wọn n tọju rẹ lọwọ, ara rẹ si ti n balẹ.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“Alaafia ni Azeez wa o, a ko nilo ki ẹnikẹni maa da owo jọ fun wa lasiko yii.
“Awọn akẹgbẹ wa ti de ibi ti a wa yii, igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa ti wa si bibi, bẹẹ naa ni Aarẹ ẹgbẹ wa, Mr Latin naa ti yọju sibi, a ko nilo owo kankan lasiko yii, ko si ewu kankan.”
Lẹyin ti Adeiofun sọrọ naa tan ni Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, TAMPAN, Mr Latin naa dupẹ lọwọ awọn araalu fun akitiyan wọn.
Lẹyin naa lo ni ko si wahala kankan ati pe ara oṣere ọhun ti n balẹ.
Kòròfo ọta ìbon ló ba Azeez Ijaduade níbi ayẹyẹ ‘end of year party’ – Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, kingzeez1/Nigeria police
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọrọ lẹyin iroyin to ni ọkan lara oṣiṣẹ rẹ yinbọn lu oṣere tiata Yoruba, Azeez Ololade Ijaduade, niluu Iperu.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi lede loju opo Twitter ni alukoro rẹ Odutola Omolola ti ni kii ṣe pe ọlọpaa naa mọọmọ yinbo lu oṣere ọhun, amọ korofo ọta ibọn lo ṣeṣi ba a.
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, ibi ti wọn ti n ṣajọyọ opin ọdun ‘end of year party’ ileeṣẹ kan ni iṣẹlẹ naa ti waye.
O ni “Ọkunrin kan, Fakoya Adewale to jẹ alakoso ile itura Napoli sọ fun ọlọpaa pe lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ orikadun ileeṣẹ Bramaj nile itura naa ni ọlọpaa to n ṣọ ọmọ orilẹ-de China kan yinbọ soke, ti korofo ọta ibọn naa si ba Azeez Ijaduade lọrun.
“Wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan fun itọju, ara rẹ si ti n balẹ bayii.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
“Adari awọn ọlọpaa Mopol 16 ti kan si oṣere naa, wọn si ti ṣabẹwo si nile iwosan, yoo si kuro nile iwosan naa lọ sile rẹ laipẹ yii.
“Ọlọpaa ni yoo si san gbogbo owo itoju rẹ nile iwosan ọhun.”
Odutola pari ọrọ rẹ pe awọn ti ṣawari ọlọpaa to yinbọn naa, iwadii si ti bẹrẹ.
Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ṣíná ìbọn fún òṣèré tíátà Yoruba, Azeez Ijaduade?

Oríṣun àwòrán, alaodc21/kingzeez1
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọlọpaa kan ti dana ibọn ya oṣere tiata Yoruba, Azeez Ololade Ijaduade, lagbegbe Iperu, nipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oṣerẹ naa, to tun jẹ oludari fiimu ti wa nile ẹkọ ẹkọṣe iṣegun Babcock University Teaching Hospital niluu Ilishan-Remo, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ, Abiodun Adebanjo lo fi ọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ ni afẹmọju ọjọ Aiku.
Atẹjade naa ni “Ẹ jọwọ a nilo iranlọwọ niluu Iperu.
“Ọlọpaa ti yinbọn fun oludaru fiimi mi, Azeez Ijaduade, o si ti wa ni Babcock University Teaching Hospital bayii fun itọju.

Oríṣun àwòrán, Abiodun Adebanjo
“Ẹ jọwọ ki ẹnikẹni to ba ni nọmba ọga agba ọlọpaa patapata tabi ti kọmiṣọna fi ṣọwọ si wa.”
Ẹwẹ, ojugba rẹ mii nidi iṣẹ tiata, Rotimi Salami ti sọ pe ara Ijaduade ti n bale nile iwosan to wa.
Ọpọ awọn ololufẹ oṣere naa lo si ti n fi adura ranṣe si i.
A ko tii le sọ ohun to ṣẹlẹ ni pato ati bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Oríṣun àwòrán, Salami Rotimi
Bẹẹ naa ni Abiodun Adebanjo to fi ọrọ ọhun lede ko ṣalaye ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ati ibi ti ọrọ de duro.
Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola lati tan imọle si ọrọ ọhun lo ja si pabo lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.














