Ṣíṣì, ẹ ò ní rí gbà, àfi tí kóòtù àgbà ní Nàìjíríà bá sọ bẹ́ẹ̀, Gómìnà Makinde fún àwọn alága káńsù tó yọ nípò lésì

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ fawọn alaga ijọba ibilẹ to yọ lẹnu iṣẹ lọdun 2019 wí pe wọn o le ri owo kankan gba lọwọ oun ayafi ti ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria ba paṣẹ bẹẹ loku.
Makinde sọrọ yii latari aṣẹ t'awọn alaga kansu naa nile ẹjọ giga ijọba apapọ l"Abuja lati gba owo ti ijọba ipinlẹ Oyo n jẹ wọn.
Adajọ A.O. Ebong gbe aṣẹ naa jade lọjọ kẹẹdọgun oṣu Kejila yii ninu eyi ti o ti darukọ akaunti owo ipinlẹ Oyo ni banki mẹwaa.
Awọn alaga yii lọ sile ẹjọ ki ile ẹjọ le pàṣẹ fun Makinde lati san gbogbo owo ati ẹtọ wọn fun wọn lẹyin to dawọn dúró lọjọ kọkandinlọgọn oṣu Karun un ọdun 2019.
Ẹwẹ, ile ẹjọ "Supreme" ti dajọ tẹlẹ lọjọ keje oṣu Karun un ọdun 2021 pe igbesẹ Makinde eleyii to fi dawọn alaga naa duro ko ba ofin mu.
Wọn si gba idajọ wí pe ki gomina Makinde san owo to din diẹ ni biliọnu marun un(N4,874,889,425.60) fun wọn.
N1.5bn ni ijọba ti san ninu owo ọhun, o si ku N3.5bn ti ijọba ko tii san.
Amọ, Makinde ti sọ pe awọn alaga ko le ko oun ni papa mọnra lati na owo ijọba.
O ni ilana to ba ofin mu nikan le fi san owo naa.
Makinde ni oun gbe igbesẹ lati yọ awọn alaga naa tori eto ibo to gbe wọn wọle ko ba ofin mu.
Bakan naa ni Makinde sọ pe aṣẹ ile ẹjọ giga ijọba apapọ l'Abuja tabuku eto igbẹjọ.
Gomina ipinlẹ Oyo ni ijọba to n tele ofin ni ijọba ti oun n dari, oun ko sí ni ṣe ohunkohun to lodi sofin.















