Èṣù bá àwọn èèyàn rìn ní ìgboro, àwọn oníṣẹ̀ṣe gbé àrà wọ ìlú Akure

Awọn eeyan n ṣe ajọdun Esu ni ilu Akurẹ

Awọn oniṣẹṣe kan si igboro ilu Alukẹ lọjọ Aiku lati ṣe ajọdun ọdun Eṣu.

Lara afojusun ajọdun ti ọdun yii ni lati ṣe ilanilọye ati itaniji fun aralu nipa nnkan ti eṣu tumo si ati iyatọ to wa laarin Eṣu ọdara ti Yoruba ati Satani ti awọn ẹlẹsin kan mọ.

Akori ajọdun Eṣu ti ọdun yii ni 'A Walk with Èṣù ' ‘Irinajo pẹlu Eṣu’.

Aọ funfun lawọn oniṣẹṣe ko si nibi ajọdun naa pẹlu oriṣiriṣi akọle bii " Esu is not Satan" "Èṣù Ola Ilu" " Laalu Ogiri Òkò".

Awọn eeyan n ṣe ajọdun Esu ni ilu Akurẹ

Olori awo ilu Akure oloye Fayeye Fagbitẹ lo lewaju awon oniṣẹṣe oun lati lo bọ Eṣu ti Deji ti ilu Akure pelu lilo epo, iyo, ewurẹ, obi ati ọti lati bọ eṣu loriko naa.

Akọwe ajọ ẹsin ifa Lagbaye, Akomolafe Wande to ba BBC News Yoruba sọrọ, sọ pe ọpọlọpọ awọn ọmọ Yoruba ko mọ bi Eṣu ṣe jẹ tori pe nnkan ti wọn gbọ kii ṣe itan to jẹ otitọ.

O ni eyi waye latari igbiyanju awon akonileru lati maṣe fẹ ki ooto nipa Eṣu ṣe awon ọmọ yoruba lanfani.

Awọn eeyan n ṣe ajọdun Esu ni ilu Akurẹ

Ọgbẹni Akọmọlafẹ sọ siwaju pe Eṣu ni agbara lati tu awon eyan silẹ yatọ si igbagbọpọ lode oni.

"awon baba wa mọ bi wọn ṣe n lo eṣu lati ṣe ọpọlọpọ nnkan. Eyi wa mu ki awọn akonilẹru to wa pẹlu ẹsin miran gbiyanju lati yi ero awọn ọmọ Yoruba pada si eyi to n ri Eṣu gẹgẹ bi ẹni aburu.

" Eṣu je Iranse pataki fún eledumare to sì man jise fún eledumare to dàbí ilekun to ri lè tosí rita

Awọn eeyan n ṣe ajọdun Esu ni ilu Akurẹ

Akọwe ajọ ẹsin Ifa lagbaye naa tun tẹsiwaju lati ṣalaye pe Eṣu lon Pin ire ka gẹgẹ bi wọn ṣe n pe e ni ọla ilu, oun na lo maa n mu iṣododo wa.

Akomolafẹ wa parọwa fun awọn eeyan ki wọn tẹle iṣẹṣe ilẹ wa ki ilẹ Yoruba le bọ ni oko ẹru, ki idagbasoke si le sun awọn eeyan rẹ bọ.