'Wọ́n gba ìwé ìrìnnà mi, wọ́n sọ mí dí aṣẹ́wó'
Lọdọdun ni ọgọrun ọdọbinrin n ko sọwọ awọn to n lo wọn si asẹwo tabi isẹ ibalopọ, eyi to n fa ọpọlọpọ aburu fun wọn.
Lati aarin gbogbo Asia lọ si India, Nepal ni awọn eeyan kan ti mu awọn ọdọ yii, ti wọn si n fiya jẹ wọn, fi tipatipa mu wọn lọ oko ẹru ati sise isẹ asẹwo.
Ọkan lara awọn ọdọ ọmọbinrin to ba BBC sọrọ salaye pe awọn eeyan gba iwe irinna oun, ti wọn si sọ fun oun pe ki oun ma sise asẹwo.

Yatọ si sise ibalopọ, o ni ti oun ba kọ lati se ohun ti wọn fẹ, lilu ni wọn ma fi se oun lese.
“Torutoru ni wọn ma fi n ran mi ni isẹ, emi nikan n sin onibara mẹfa.
“Wọn mu mi lọsi ile kan [ni Delhi] nibi ti obinrin marun miiran wa.
“Lẹyin ọjọ meji, wọn ni ki n ṣiṣẹ naabi tipatipa.
“Ni igba ti mo kọ, wọn ni ki n ṣe tipatipa.
Ọrọ pọ lẹnu ọdọmọbinrin yii, ẹ wo fọnran yii lati mọ ohun ti awọn ọdọbinrin n la kọja.
















