Ẹ gbà wá o! àwọn olùkọ tí a rán lọ kàwé pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lókè òkun ń 'jápa' mọ wa lọ̀wọ̀ -Tetfund ké gbàjáre

Oríṣun àwòrán, Google
Ọga agba ajọ to n ṣakoso eto ẹkọ awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria 'Tetfund' ti ke gbajare lori bi awọn olukọ fasiti ti wọn n ran lọ kawe nilẹ okeere ṣe n gba ibẹ salọ mọ wọn lọwọ.
Akọwe agba ajọ naa, Sonny Echono sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ lati ri pe awọn olukọ yi da owo ti wọn fi ran wọn lọ kawe pada tabi ki wọn si wọ wọn pada sí Naijiria.
Lọjọ Aje lo fidi ọrọ yi mulẹ lasiko apero awọn l'ọga l'ọga ajọ naa to waye ni Makurdi.
O sọ pe awọn da aba yi lati ri pe ijiya wa fun awọn olukọ fasiti to sa mọ wọn lọwọ yi.
O ni "Mi o fẹ darukọ iye kan pato tori iye awọn to ja pa yi pọ, ohun ibanujẹ ni pe wọn ṣi anfaani ti wọn fun wọn yi lo."
Iṣiro iye wọn pọ tori pe ninu wọn la ti ri awọn to pada wa si'le ṣugbọn ti wọn kò sán owooya wọn tan ki wọn to pinnu lati japa kuro lọ silẹ okere"
"A ni akọsilẹ iye wọn ti a si maa n ṣe ayẹwo rẹ loore koore.Lootọ lo ṣoro lati mọ bi nkan ṣe ri fawọn kan ninu wọn tori pe kii ṣe pe wọn sa amọ wọn ti n lọ ju iye akoko to yẹ feto ẹkọ wọn "
O tẹsiwaju pe awọn ti fi ọrọ yi to awọn agbofinro leti t'awọn naa si n toju bọ ọrọ yi.
Lori awọn ijiya to l'awọn ni lati fi koju iru iwa yi, o sọ pe awọn ni ọna abayọ ti ko mu wahala lọwọ.
Ohun si ni pe "ki gbogbo awọn to gba owo eto ẹkọ ọfẹ ti ko si fẹ pada sile da gbogbo owo taa na lori wọn pada fun wa"
Ọna keji to la kalẹ to ni ko dẹrun si ni pe " a ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileeṣẹ aṣoju ijọba orileede wa to wa nilẹ okeere nibi t'awọn to japa yi ti n kawe ọfẹ"
O sọ pe ohun ṣe ipade pẹlu awọn ile ẹkọ giga to fẹ gba awọn olukọ yi sọdọ ti ohun di jẹ ko fi mimọ pe ẹni tó bá fẹ gba akẹkọ t'awọn yoo san owo ẹkọ rẹ gbọdọ jẹ kí awọn ni iroyin nipa akẹkọ eyikeyi ti ba pẹ kọja asiko to wa lori fisa rẹ.
O ni eyi tumọ si pe wọn ti n ru ofin pẹlu kikọja asiko yii t'awọn alaṣẹ si lé tori rẹ da wọn pada sile.
"A mọ wi pe wọn yoo ṣe ohun to yẹ lati da owo wa pada"
Lakotan, ọga Tetfund yi sọ pe awọn ti na to biliọnu irinwo fawọn ile ẹkọ giga Naijiria.












