Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ wa ló ń kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ láti Japa nítorí ìyà tó ń jẹ wọ́n – ASUU

Oríṣun àwòrán, ASUU
Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU ti ke gbajare pe ọpọ awọn olukọ lo n kọwe fi ipo wọn silẹ ni Naijiria lati japa lọ silẹ mii.
Alaga ẹgbẹ naa ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ibadan, UI, Ọjọgbọn Ayo Akinwole lo sọ bẹẹ niluu Ibadan.
O ni ipo ti ọpọ fasiti wa ni Naijiria ko dara rara latari owo kereje ti awọn olukọ n gba, eyii ti ko to lati gbọ bukata wọn.
Ninu ọrọ rẹ “Ayafi ti Aarẹ Bola Tinubu ba tete wa ojutu si ọrọ awọn olukọ ati owo oṣu wọn, to fi mọ awọn ohun elo ẹkọ, ọpọ olukọ ni yoo maa kọwe fi iṣẹ wọn silẹ ti wọn yoo si maa salọ si oke okun.”
“O ṣeni laanu pe ijọba kan naa to kọ lati kowo si ẹka eto ẹkọ ni ile igbimọ aṣofin rẹ n gbero lati da fasiti mejilelọgbọn tuntun mii silẹ.”
Akinwole sọ pe dida awọn fasiti tuntun mii silẹ kọ ni yoo tan iṣoro ti eto ẹkọ n dojukọ ni Naijiria, amọ ijọba gbọdọ ro awọn fasiti to wa nilẹ lagbara ko le gba ọpọ akẹkọọ ju iye to n gba tẹlẹ lọ.
Alaga ASUU ọhun ni owo oṣu ti ko to nnkankan ti ko tun ṣe dede, awọn ajẹmọnu ti ijọba ko san, awọn ohun elo igbalode ti ko si atawọn iṣoro mii ti awọn olukọ fasiti n dojukọ lo jẹ ki wọn maa fi iṣẹ wọn silẹ lọ ilẹ mii.
O ni “Ẹgbẹ wa ti gbọ iroyin nipa bi awọn akẹgbẹ wa ṣe n kọwe fi ipo silẹ loṣoṣu nitori wọn ko ṣetọju awọn olukọ ni Naijiria.
“Awọn fasiti mii kaakiri agbaye lo n ja awọn olukọ wa to jẹ ọlọpọlọ pipe gba, ti ijọba ko ba tete wa nnkan ṣe si ọrọ yii, yoo ṣoro lati ni awọn olukọ to dangajia.
“Awọn olori fasiti nikan ko le da gba awọn olukọ mọ siṣẹ mọ, wọn ni lati kọkọ kan si Abuja lati gba aṣẹ, eyii to le gba oṣu mẹfa si ọdun kan tabi jubẹ lọ.
“Ki akoko naa to pe, awọn ọlọpọlọ pipe olukọ yoo ti gba awọn orilẹ-ede mii to mọ iyi eto ẹkọ lọ.”
Akinwole pari ọrọ rẹ pe o jẹ ohun ibanujẹ pe awọn alaṣe nileeṣẹ eto ẹkọ atawọn aṣofin lo fẹ maa paṣẹ fun awọn fasiti nipa irufẹ ẹni to yẹ ki wọn gba ati akoko to yẹ ki wọn gba olukọ siṣẹ.
A kò faramọ ètò ẹ̀yáwó tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ – ASUU

Oríṣun àwòrán, Campus Updates NG
Ẹgbẹ awọ olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU, ti sọ pe awọn ko faramọ eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ ti ijọba apapọ buwọlu laipẹ yii.
ASUU ni awọn to da fasiti aladani silẹ nikan ni eto naa yoo ṣe anfani fun.
Aarẹ ẹgbẹ ọhun Emmanuel Osodeke lo sọ sọ ọrọ naa ni fasiti Abubakar Tafawa Balewa, ATBU, to wa niluu Bauchi, lopin ọsẹ.
Osodeke sọ pe niwọn igba ti ijọba ba le ṣe eto naa, o n tumọ si pe o lagbara lati gbe owo kalẹ fun eto ẹkọ Naijiria.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 ni Aarẹ Tinubu kede pe oun ti buwọlu eto ẹyawo awọn akẹkọọ naa.
Afojusun eto naa ni lati ṣeranwọ fun awọn akẹkọọ lati ya owo fun eto ẹkọ wọn, eyii ti wọn yoo san pada gẹgẹ bo ṣe wa lawọn orilẹ-ede mii.
Osodeke, ti igbakeji rẹ, Christopher Piwuna ṣoju fun ṣalaye pe owo ti ko to ni ẹka eto ẹkọ Naijiria wa lara eredi ti ina rẹ ṣe n jo ajorẹyin.
O ni o san ki ijọba maa pese owo ti wọn ko ni san pada fun awọn akẹkọọ naa kaka ko maa ya wọn lowo, ati pe ijọba gbọdọ maa ko owo gọbọi si ẹka eto ẹkọ.
Aarẹ ASUU naa ṣo pe awọn ko faramọ eto ọhun rara nitori awọn oludasile fasiti aladani nikan ni yoo janfani rẹ.
Lẹyin naa lo ke si awọn obi lati fọwọsowọpọ pẹlu ASUU lati ri pe igba ọtun de ba eto ẹkọ ni Naijiria.
O ni “A gbagbọ pe ijọba Naijiria le kowo si ẹka eto ẹkọ to ba mọ ohun to n ṣe.”
“Awa ko faramọ eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ gẹgẹ bii ọna lati ran eto ẹkọ lọwọ, a gbagbọ pe apo awọn to n da fasiti silẹ amọ ti wọn ṣi wa ni ijọba lonii ni awọn owo naa yoo pada si.”














