Gbogbo àwọn ọmọ wa ni omíyalé ti ṣekúpa, aráàlú pariwo síta

Isẹlẹ omiyale to waye lọsẹ to kọja lorilẹede Tanzania sekupa ọpọ eeyan, ti ọpọ mọlẹbi ṣi wa ninu irora ati ibanujẹ ọkan.
Marieta Banga sọ fun BBC pe eeyan mẹjọ ninu mọlẹbi rẹ lo padanu ẹmi wọn sinu isẹlẹ omiyale to waye ni apa ariwa orilẹede naa.
Banga ni, “A kan gbọ ariwo nla , nigba ti a sa si ita gbangba, a ri agbara nla.
“Nigba ti ojo yii da, a ri pe a o ni ile mọ, ko si nkankan mọ, gbogbo awọn ọmọ wa ti poora.
“Awọn ọmọ ẹgbọn mi , awọn mẹfa ati iya wọn ti lọ. Mọlẹbi mii to n gbe pẹlu wa naa ti lọ.”
Eeyan marundinlaadọrin lo ti padanu ẹmi wọn nibi isẹlẹ omiyale yii, to si tun le ni ọgọrun un eeyan to farapa yanayana.
Christina Bura, olugbe agbegbe naa to padanu ọmọ rẹ ninu isẹlẹ naa ni oun taji lasiko ti omi ati ẹrẹ ti gba gbogbo ile rẹ.
“Nnkan bi ago mẹfa idaji, mo n sun lọwọ nigba ti ọkọ mi tamiji, to si n bi mi pe se ki n se isẹlẹ ilẹ riri ree?
“Emi ati awọn ọmọ bere si ni ma lọ si ita sugbọn omi ti yi wa ka, to si n wọ wa lọ. A wa ni oju kan fun wakati kan, ti omi si n gbe awọn eeyan lọ ni ẹgbẹ wa.
“Ọpọ idile lo ti di ailanile lori bayii.
“Ni agbegbe wa, ko si ile gbe kankan mọ, ko si maalu kan mọ.”
Olori ile ijọsin, Esther Martin ni isẹlẹ wọ ile rẹ lọ ko to tun ba ile ijọsin jẹ
“Omi naa wọ mi, sọ ori mi mọ apata , igi fun bi kilo mita meji. Mo bẹrẹ si ni ma gba adura , pe mi ko gbọdọ ku , ti Ọlọrun si ran mi lọwọ.
“Mo rapala lọ mọ igi kan, ti mo si gun oke rẹ."
Omíyalé ṣekúpa èèyàn 63, ọ̀pọ̀ dúkìá bàjẹ́

O le ni eeyan mẹtalelọgọta to ti jẹ ipe ỌIọrun, ti ogunlọgọ eeyan si tun farapa yanayana lẹyin ti isẹlẹ omiyale ati Ilẹ riri waye ni apa ariwa Tanzania.
Ijọba ni awọn da awọn akọsẹmọsẹ to n dola ẹmi toto irinwo niye sita lati lọ dola ẹmi awọn eeyan to lugbadi isẹlẹ naa ni agbegbe Mount Hanang ni Manyara.
Lara awọn ikọ akọsẹmọsẹ to ti balẹ si agbegbe naa ni awọn eleto ilera ti wọn yoo pese itọju fun awọn eeyan to lugbadi isẹlẹ omiyale naa.
“A ni ikọ awọn dokita ati eleto ilera ti a ran lọ sibi isẹlẹ omiyale naa.
“Wọn ti bẹrẹ si ni pese itọju fun awọn eeyan, ti ọpọ si ti n daraya,” Dokita Godwin Mollel, Igbakeji minisita fun eto ilera Tanzania salaye.
Ọpọ ile gbe ati ohun idagbasoke ilu ni omiyale naa bajẹ.
Isẹlẹ omiyale jẹ ohun to waye lorekore, to si n ṣe ọpọ ijanba fun ogunlọgọ awọn araalu lọdọdun.
Apa ila oorun Afirika ni isẹlẹ omiyale ti ṣe ọpọlọpọ ijanba fun lọdun 2023.
Losun to kọja ni Tanzania, ọjọ arọrọda gba ọpọ ẹmi, to si tun ba dukia jẹ ni olu ilu Dares Salaam ati awọn agbegbe bi Kigoma, Kagera, Genita ati Zanziba.

Ẹ̀kún omi gbé èèyàn 110 lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá sì tún bàjẹ́

Oríṣun àwòrán, getty Images
Iye awọn to ti ku latari ẹkun omi to gba Somalia ti le ni aadọfa (110) bayii.
Ajọ United Nations to n ri si ọrọ ọmọniyan lagbaye, UN OCHA, lo fidi ọrọ naa mulẹ.
O ti le ni miliọnu kan araalu ti wọn ti di alairilegbe lẹyin iṣẹlẹ naa, eyii to kan nnkan bii miliọnu meji abọ awọn eyan lorilẹ-ede naa.
UN OCHA ti kilọ pe o ṣeeṣe ki arun to lagbara kan burẹkẹ nibẹ lẹyin ti aisan onigba meji ati igbẹ gbuuru bẹ silẹ ni ipinlẹ Hirshabelle ati Galmudug.
Ajọ naa fi kun pe ida ọgbọn awọn ti ọrọ naa kan ni ko tii ri iranwọ gba, amọ ọkọ oju omi mẹtadinlogoji ni wọn ti fi ranṣẹ lati lọ ko awọn to ha sibi ti omi naa gba.
Laarin ọsẹ diẹ ṣeyin ni Somalia ati Kenya to wa ni fẹgbẹkẹgbẹ ara wọn ti n dojukọ ojo arọrọda.
- Àwọn ọmọ Naijiria 180,000 tó fẹ́ wá sílẹ̀ wa la ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún lọ́dún yìí – Ìjọba Amẹrika
- Wo obìnrin àkọ́kọ́ ní South Africa tó jẹ́ olúkọ́ni nípa wíwẹ́ dé ìsàlẹ̀ odò
- Àdó olóró búrẹ́kẹ lásìkò ìjọsìn àwọn Kátólíìkì, èèyàn mẹ́rin kú, 42 farapa
- Wo ìdí tí wọ́n fi ń pe arábìnrin yìí ní Helen Paul Kòlénìyàn
Iroyin ni ojo arọrọda naa ni wọn ko tii ri iru rẹ ri ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin, eyii to ba ọpọ dukia jẹ, to si tun gbe awọn eeyan lọ.
Ikun omi naa ni awọn onimọ sọ pe o waye latari bii alagbalugbu omi okun Pacific Ocean ṣe n gbona, eyii ti wọn pe ni “El Niño weather phenomenon.”
Awọn onimọ sayẹnsi sọ pe irufẹ ikun omi bẹe yoo tẹsiwaju lati maa waye nitori ayipada oju ọjọ.
Ẹwẹ, ajọ United Nations ti sọ pe nnkan bii miliọnmu kan abọ eka oko ni ikun ẹkun omi naa yoo gbe lọ.














