Makinde ṣèdárò àwọn orí adé mẹ́ta tó jáde láyé nínú Ìjàmbá ọkọ̀ Oyo

Aworan Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti fi ẹdun ọkan rẹ sita lori ipapoda awọn ori ade mẹta lati ijọba ibilẹ Oriire, to jade laye ninu ijamba ọkọ to waye lọjọ Ẹti, ọjọ kinni oṣu kejila ọdun 2023.

Awọn ori ade naa ni, Olodogbp ti Odogbo, Onibowula ti Bowula ati Alayetoro ti Ayetoro ni wọn kọwọrin lọ si ode kan nigba ti ọkọ to n gbe wọn kọlu ọkọ akẹru nla kan.

Makinde sapejuwe iroyin iku awọn ori ade naa gẹgẹ bii ohun to ba ni lojiji, to si ba awọn mọlẹbi, ilu ati ilu Ogbomoso kẹdun lori ipapoda awọn oriade naa.

O wa gba ladura pe ki Ọba oke forijin awọn ladelade naa, ti Ọlọrun si tu awọn mọlẹbi wọn ninu, gbogbo ipinlẹ Oyo lapapọ.

“O ba ni lọkan jẹ pupọ. A n gba ladura pe ki Ọlọrun gbakoso, ko tun awọn mọlẹbi wọn ninu, awọn oloye ati gbogbo ipinlẹ Oyo pata lori ajalu nla yii.”

Ìjàmbá ọkọ̀ mú ẹ̀mí Ọba alayé mẹ́ta lọ ní ìpínlẹ̀ Oyo, èèyàn mẹ́sàn án míì farapa

Oyo Accident

Oríṣun àwòrán, @News247_Naija

Inu ibanujẹ ni awọn eeyan ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo wa bayii lẹyin ti ori ade mẹta lati ijọba ibilẹ naa jade laye ninu ijamba ọkọ kan lọjọ Ẹti.

Awọn ọba alaye naa padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọhun to kan ọkọ ayọkẹlẹ Benz E230 kan ati ọkọ akero Scania to ni nọmba idanimọ 301 XF.

Yatọ si awọn ọba alaye ti ijamba ọkọ yii mu lọ, ẹlọmiran tun ku, eyii to mu apapọ awọn to jade laye pe mẹrin, nigba ti nnkan bi eeyan mẹsan an mii tun farapa.

Meji lara awọn ori ade naa lo waja lẹsẹkẹsẹ lẹyin ijamba naa, nigba ti ẹkẹta wọn papoda lẹyin wakati diẹ nile iwosan Ladoke Akintola University Teaching Hospital.

A gbọ pe ero ọkọ mẹfa ni ijamba naa kan, ṣugbọn wọn ti n gba itọju lọwọ nile iwosan LAUTECH.

Ibi ayẹyẹ kan ni awọn ero ọkọ naa n lọ ki ijamba ọhun to waye.

Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn ori ade ti ọrọ naa kan ni Olodogbo ti ilu Odogbo, Onibowula ti ilu Bowula ati Alayetoto ti ilu Ayetoro ni ijọba ibilẹ Oriire.

Nigba to n fidi ijamba naa mulẹ, Joshua Adekanye to gba ẹnu ileeṣẹ ẹṣọ oju popo, FRSC sọrọ in ṣe ni ọkọ mejeji fori sọ ara wọn.

O ni awọn to farapa ti n gba itọju lọwọ nigba ti wọn ti ko oku awọn ti ẹmi wọn sọnu lọ sile igbokupamọsi.