APC, SDP nàka àléébù síra wọn lórí ìkọlù táwọn agbébọn ṣe sílé ọ̀gá àgbà àjọ INEC ní Kogi

Asia APC ati SDP

Oríṣun àwòrán, APC/SDP/FACEBOOK

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC àti Social Democratic Party, SDP ní ìpínlẹ̀ Kogi ti bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn lọrí ìkọlù tí àwọn kan ṣe sílé ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC, Dókítà Gabriel Longpet ní ìpínlẹ̀ náà.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ìgbìmọ̀ olùpolongo ìbò APC ní ìpínlẹ̀ náà nàka àléébù sí olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀hún lẹ́gbẹ́ òṣèlú SDP, Murtala Ajaka.

Agbẹnusọ ìgbìmọ̀ olùpolongo ìbò fún APC, Kingsley Fanwo ní ó yẹ kí àwọn ọlọ́pàá lọ nawọ́ gán Ajaka lórí ìkọlù náà ni.

Fanwo ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ajaka àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ti ń hu àwọn ìwà ìpáǹle àti pé àwọn ni wọ́n máa wà nìdí ìkọlù tó wáyé nílé ọ̀gá àgbà òṣìṣẹ́ INEC náà.

Ó ní láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni òun ti ń pariwo pé SDP ń gbèrò láti lo àwọn ọmọ gànfé láti fi ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ INEC.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn jàǹdùkú náà tún gbìyànjú láti ṣèkọlù sílé ìjọba àti ilé ẹgbẹ́ APC tó wà ní Lokoja àmọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tètè ká ipá wọn.

Àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP ti jiyàn àwọn ẹ̀sùn yìí.

Fanwo tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé SDP ń wá gbogbo ọ̀nà láti fi pa gbogbo èrú ìbò tí wọ́n ṣe ní ẹkùn ìlà oòrùn Kogi ìyẹn Kogi East rẹ̀ ni gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ẹ̀rí tó wà lọ́wọ́ INEC takò wọn ni wọ́n ń sáré àti parẹ́ kí àwọn tó gbé fún àwọn agbẹjọ́rò.

Ẹ̀wẹ̀ agbẹnusọ ìpolongo ìbò fún olùdíje SDP, David Ijele ní ẹgbẹ́ àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù tó wáyé nílé ọ̀gá àgbà INEC náà.

Ijele, nínu àtẹ̀jáde kan tó gbé síta ní àwọn bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà nítorí kò yẹ kí irú rẹ̀ tilẹ̀ wáyé rárá.

Ó ní ètò ìdìbò kò yẹ kó di ogun tàbí ohun tí ẹ̀mí ń lọ sí pàápàá tó bá lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ tí kò ní ìwà màgòmágó kankan nínú.

Ó ní àwọn kò mọ ìdí tí àwọn jàǹdùkú ṣe ń ṣe ìwọdé nítorí wọn kò fẹ́ kí àwọn tó fẹ́ tọpinpin ètò ìdìbò náà ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe yẹ.

Ó wá kan sáárá sí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe láti ri pé ọ̀gá INEC náà àtàwọn ẹbí rẹ̀ rí ààbò tó péye lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù náà.

Àwọn agbébọn kọlù ilé ọ̀gá àgbà àjọ INEC ní Kogi

Aworan dukia to bajẹ

Oríṣun àwòrán, inec

Awọn afurasi agbebọn kan kọlu ile ọga agba ajọ INEC ni ipinlẹ Kogi.

Iṣẹlẹ yii waye ni owurọ kutu ọjọ Ẹti, ọjọ kinni oṣu kejila ọdun 2023.

Alamojuto ọrọ araalu lajọ INEC Rotimi Oyekanmi ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti pe ọpọlọpọ dukia ni awọn oniṣẹ laabi naa bajẹ, ṣugbọn ko si ẹmi kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Aworan ọta ìbọn

Oríṣun àwòrán, inec

Oyekanmi ni awọn ẹsọ alabo koju awọn agbebọn naa, ti wọn si wọ iyaja fun nnkan bii ọgbọn isẹju.

"Ni owurọ kutu ọjọ Ẹti, ọjọ kinni oṣu Kejila ọdun 2023, ni dede ago mẹta abọ ni awọn agbebọn kọlu ile Kọmisọna wa ni ilu Lokoja.

"Awọn agbebọn yii ati awọn ẹsọ alabo wọ iyaja pẹlu ìbọn fun ọgbọn isẹju ki iranlọwọ to de.

"Ẹmi kankan ko ba iṣẹlẹ naa lọ sugbọn ọpọ dukia lo bajẹ lasiko ti ìbọn n dun."

Oyekanmi ni ikọ ileeṣẹ Ọlọpaa ti balẹ si ile Kọmisọna naa lati pese abo to peye.

Ajọ INEC tí wa pe fun iwadi to peye lati sawari awọn agbebọn naa, eyi ti yoo mu ọkan awọn araalu balẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post