MC Oluomo di alága NURTW Eko fún sáà tuntun

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ẹgbẹ́ onímọ́tò ìyẹn National Union of Road Transport Workers, NURTW tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko ti dìbò yan Alhaji Musiliu Akinsanya tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí MC Oluomo gẹ́gẹ́ bí alága fún sáà mìíràn.
MC Oluomo àti igbákejì rẹ̀, Alhaji Sulyman Ojora, akápò ẹgbẹ́ náà, Alhaji Mustapha Adekunle tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sego àtàwọn méjìdínlọ́gbọ̀n mìíràn ni wọ́n dìbò yàn lọ́jọ́bọ̀ níbi àpérò ẹgbẹ́ náà tó wáyé ní ìlú Eko.
Gbogbo àwọn tó díje náà ni kò ní alátakò kankan tó báwọn dupò.
Lẹ́yìn ètò ìdìbò náà ni agbẹjọ́rò kan, Adejare Kembi búra wọlé fún ìgbìmọ̀ aláṣẹ tuntun náà.
MC Oluomo dúpẹ́ lọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu àtàwọn adarí ẹgbẹ́ náà lápapọ̀ fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún-un.
Bákan náà ló ṣèlérí láti mú àyípadà ọ̀tun bá ẹgbẹ́ awakọ̀ náà.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, gómìnà Babajide Sanwo-Olu kan sáárá sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà fún bí ètò ìdìbò náà ṣe lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ láì fa wàhálà kankan.
Sanwo-Olu, ẹni tí adarí kan nílé iṣẹ́ ètò ìrìnnà ní ìpínlẹ̀ Eko, Lateef Tiamiyu ṣojú fún ní láyé ìgbà kan ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW máa fa jàgídíjàgan nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan àwọn adarí tuntun.
Ó ní àyípadà yìí náà gbọdọ̀ máa jẹyọ nínú bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí ṣe ń ṣe ní àwọn òpópónà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni adelé ààrẹ àpapọ̀ NURTW gbóríyìn fún ìyànsípò Akinsanya.
Ó ní àwọn adarí ẹgbẹ́ àtàwọn alátìlẹyìn wọn gbọ́dọ̀ máa sa ipá wọn láti mú ìlọsíwájú bá ẹgbẹ́ náà.















