Ìkọlù bẹ̀rẹ̀ padà láàrín Israel àti Hamas, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí gbèǹdéke ìdádúró ìjà parí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iro ibọn ati ado oloro ti bẹẹ si ni dun pada ni Gaza pẹlu biIsrael atiHamas ṣe bẹrẹ si ni koju araawọn tohun ti bi Israel ṣe ni Hamas lo kọkọ tapa si adehun idaduro ija tawọn ṣe.
Ọjọ meje ni wọn fi ṣe idaduro ija to n waye lati igba ti ikọlu ti bẹrẹ.
Lasiko idaduro yi, awọn ọmọ ile Israel ọgọrun le mẹwaa ti o wa ni igbekun Hamas ni wọn tu silẹ ti Israel naa si tu awọn eeyan Palestine ọjilenigba to wa lẹwọn ti wọn naa silẹ.
Ikọ ologun Israel Israel Defence Forces, IDF, sọ pe lọwọ lọwọ lawọn baalu ogun awọn n ju ado oloro lu awn aaye ibi ti Hamas wa ni Gaza.
Eyi n waye lẹyinbi ọgbọn iṣẹju ti Israel lawọn yoo bẹrẹ ija pẹlu Hamas pada toi pe Hamas tapa si adehun idawọduro ija.
Lana alana yi ni Minisita fun ọrọ ilẹ okere America, Anthony Blinken, to n ṣe abẹwo silẹ larubawa lọwọ yi sọ pe, awọn ọga ologun Israel ni bo pẹ boya awọn yoo bẹrẹ ikọlu ologun pada.
Amọ ti wọn yoo ba ṣe bẹ, Blinken rọ wọn lati se awọn nkan meloo kan:
- Ipese eto idaabo to peye fawọn araalu ṣaaju ki wọn to pada sẹnu ogun
- Yiyago fun ikọlu eleyi ti yoo mu iṣipo pada ba awọn araalu
- Yiyago fun ṣiṣe ikọlu sawọn ohun amaiyedẹrun bii ile iwosan, ileeṣẹ mọnamọna ati awọn ileeṣẹ ipese omi faraalu
Ijiroro ṣi n tẹsiwaju lati fi kun iye ọjọ idawọduro ogun
BBC ti rii gbọ wi pe awọn apẹtusaawọ ṣi n jiroro lori bi wọn yoo ṣe fẹnu alaafia ko laarin awọn ikọ mejeeji tohun ti bi ikọlu ti tun bẹrẹ.
Amọ ba ṣe n sọrọ yi gbendeke idawọduro ija laarin Israel ati Hamas ti dopin.
A ko ti gburo nkankan nipa pe wọn yoo sunjọ siwaju lori gbendeke yi.
America, Egypt,ati Qatar ni wọn wa nidi ijiroro yi.
Ọjọ mẹrin ni wọn kọkọ kede idawọduro ija amọ wọn sun siwaju lẹẹmeeji ọtọọt.
Ẹyin igba naa wa ni idawọduro ọlọjọ meje tigbendeke rẹ pari bayii waye.
Ikọlu ti Hamas ṣe si Israel lọjọ Keje oṣu Kẹwaa ṣekupa eeyan to le ni ẹgbẹrun kan.
Lati igba naa ileeṣẹ ilera ti Gaza n ṣakoso rẹ sọ pe o sunmọ eeyan ẹgbẹrun mẹẹdogun Palestine ti wọn kagbako iku ninu ikọlu ti Israel ṣe lati gbẹsan pada.
Ninu awọn to ku wọnyi ni ọmọde ẹgbẹrun mẹfa wa.












