‘Refinery’ ìlú Port Harcourt gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà nínú oṣù yìí gẹ́gẹ́ bíi ìlérí ìjọba àpapọ̀ – Afenifere

refinery

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ ọmọ Yoruba, Afenifere, ti ke si ijọba apapọ ko ri daju pe ileeṣẹ to n fọ epo bẹntiro to wa niluu Port Harcourt bẹrẹ iṣẹ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii.

Ẹgbẹ naa, ti Pa Reuben Fasoranti ko sọdi lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan lẹyin ipade to ṣe niluu Akure.

Afenifere ni ara yoo tu awọn ọmọ Naijiria ti ileeṣẹ naa ba bẹrẹ iṣẹ pada lẹyin ti ijọba apapọ yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro.

Ṣaaju ni minisita fun ọrọ epo bẹntiro, Heineken Lokpobiri, ti kọkọ ṣeleri ninu oṣu Kẹjọ pe ileeṣẹ naa yoo bẹrẹ iṣẹ pada ninu oṣu Kejila yii.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ naa jẹ ọkan lara awọn ọna ti ijọba apapọ n gba lati fopin si bo ṣe n ko epo bẹntiro wọle lati ilẹ okeere.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ni kete ti Aarẹ Bola Tinubu kede pe ijọba ko ni san owo iranwọ ori epo bẹntiro mọ ni owo jala epo kan fo soke lati N184 si nnkan bii N600 o le diẹ.

Ni bayii ti oṣu Kejila wọle de, Afenifere ti wa ke si Aarẹ Bola Tinubu ko mu ileri ijọba rẹ ṣẹ.

Atẹjade naa ni agbẹnusọ ẹgbẹ ọhun, Jare Ajayi, buwọlu.

Afenifere ni “ijọba apapọ gbọdọ ri daju pe oṣu Kejila to ṣeleri ko yẹ.”

“Fun apẹrẹ, ijọba gbọdọ ri daju pe oṣu Kejila to ṣeleri pe ileeṣẹ to n fọ epo ni Port Harcourt bẹrẹ iṣẹ pada.’”

“Ṣiṣe eyii yoo jẹ ki owo ti awọn araalu n ra epo ja walẹ eyii to mu ki ọwọngogo de gbogbo ọja kaakiri orilẹ-ede yii.”