Àwọn afurasí méjì tó ń jẹ́jọ́ lórí ikú ọ̀gá àgbà hòtẹ́ẹ̀lì n'Ilorin tún fojú ba'lé ẹjọ́

Awọn afurasí náà

Lọjọru ni igbẹjọ awon obinrin meji ti wọn furasi pe wọn seku pa Ọgbeni Adeniyi Ojo ti o jẹ ọga agba ile igbafẹ Water View ni iluu Ilọrin tun waye nile ẹjọ.

Ile ẹjọ Majisireeti ni wọn ti n jẹjọ naa. eyi si ni igba keji ti wọn yoo foju bale lẹyin igbẹjọ akọkọ waye lọjọ kẹjọ osu Kọkanla ọdun 2023.

Awon afurasi ọhun, Joy Adanma Joseph ti o jẹ ọmọ ọdun mejilelogun ati ọrẹẹ rẹ, David Favour Oreoluwa, tii se, ọmọ ọdun mẹtalelogun, ni wọn n jẹjọ niwaju Adajọ Monisola Kamson fun ẹsun ipaniyan ati idigunjale.

Awọn afurasi mejeeji n sunkun, ti wọn si n kanmi loju gidigidi ninu ile ẹjọ bi igbẹjọ wọn ṣe n waye.

Amọ igbẹjọ wọn ko lọ ni rẹpẹtẹ nitori Adajọ to n gbọ ẹjọ naa wa ni isinmi, (Leave), o si di inu ọdun tuntun ki o to pada sẹnu iṣẹ.

Ile ẹjọ ni ki wọn da wọn pada wa ni ọjọ kẹrindinlogun osu kinni ọdun 2024.

Lẹyin eyi ni awon agbofinro dawon pada si ahamo ọgba ẹwọn to w a ni Oke-Kura.

Ìgbéjọ́ àwọn ọmọbìnrin méjì tó ṣekú pa Ọ̀gá àgbà òtẹ́ẹ̀lì n'Ilorin ti bẹ̀rẹ̀ báyìí

Aworan Afurasi akẹkọọ obinrin

Oríṣun àwòrán, Others

Igbẹjọ awọn afurasi adigunjale obirin meji ti wọn fẹsun iseku pa Adari agba, ile igbafẹ Water View ni iluu Ilọrin, Ọgbẹni Adeniyi Ojo kan, ti bẹrẹ ni ile ẹjọ Majisireeti kan ni ilu naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awon mejeeji si ti wa ni ahamo ijọba, Oke-Kura bayii.

Awon afurasi ọhun, Joy Adanma Joseph ti o jẹ ẹni ọdun mejilelogun ati ọrẹ rẹ, David Favour Oreoluwa, tii se, ẹni ọdun mẹtalelogun, ni wọn wọ wa iwaju, Magistrate Monisola Kamson fun ẹsun ipaniyan ati idigunjale.

Gẹgẹ bi iwe ti awọn ọlọpaa fi lede ni ile ẹjọ lana, awọn obinrin meji yii wọ inu yara kan ni inu ile itura naa pẹlu Adeniyi Ojo sugbon lẹyin isẹju diẹ wọn jade laisi Ojo pẹlu wọn.

Iwe naa ka pe, awon afurasi yii parọ wi pe wọn fẹ lọ ra otii bullet ni inuu ọgba otẹẹli naa

Olugbalejo otẹẹli ọhun fura si wọn, o si gbera lati lọ wo ọgaa rẹ ninu yara naa, o kan ilẹkun sugbon ọga ko dahun lati si ilẹkun fun un.

Lẹyin ọpọlọpọ igbiyanju, wọn ja ilẹkun naa lati wọle, wọn si ba Ojo lori ibusun ti ọwọ ọ rẹ ati ẹsẹ ẹ rẹ mejeji wa ni dide, wọn si tun fi akisa bo o lẹnu.

Iwadi pada fihan pe awon afurasi obinrin naa, sa lọ pẹlu kọkọrọ yara ọhun lẹyin ti wọn ti ha Ojo mole.

Wọn gbee lọ si ile iwosan Anchormed fun ayẹwo nibi ti wọn ti kede wipe o ti ta teru nipa

Aworan iwe ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa

Pẹlu igbiyanju awọn ọlọpaa, ọwọ tẹ Joy ni ọfada Mowe ni ipinlẹ Ogun, wọn si mu ọrẹẹ rẹ, Oreoluwa ni agbegbe Berger ni ipinlẹ Eko.

Awon afurasi yii lọ pẹlu ẹrọ ibanisọrọ oloogbe naa, wọn si yọ simu kaadi rẹ sinu ẹrọ ti wọn lati wọ owo ni akantii rẹ sugbon gbogbo igbiyanju wọn jasi pabo.

Iwadi tun tanmolẹ sii pe, Joy ti o gbe ọbẹ lọwọ ati codoline syrup pẹlu oogun refnol lati kun Ojo lorun lo bo ẹnu rẹ nigbati Oreoluwa n gbiyanju lati si ẹrọ ibanisọrọọ rẹ pẹlu ojuu rẹ.

O pada gbe pillow lee loju titi ẹmi fi bọ lọrun un rẹ

Adanma di nkan omokunrin rẹ mu, o si halẹ wi pe oun yoo ge kuro ti ko ba sowọpọ pẹlu wọn koto di pe wọn fi pillow ran an lọ gbekurujẹ lọwọ ẹbọra.

Agbẹjọro ijọba Sanni Abdullahi sọ fun ile ẹjọ pe, ẹsẹ ti awọn afurasi ọdaran naa ṣẹ kii se ohun ti wọn le gba beeli rẹ ni wẹrẹ, o si rọ ile ẹjọ ki wọn sọ wọn si ahamo.

Ninu idajọ ranpẹ rẹ, Adajọ Monisola Kamson pasẹ ahamo fun awọn ọdaran afurasi ọhun.

O wa sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlọgbọn osu kọkanla ọdun ti a wa yii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others