Ìjọba Ondo fọwọ́ sí àfikún owó oṣù ₦35k fáwọn òṣìṣẹ́, Osun fi ₦15k kún tiwọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ondo ni yoo dunnu ni klete ti owo oṣu yii ba wọle sinu asunwọn wọn.
Eyi ko ṣẹyin afikun ẹgbẹrun marundinlogoji ti ijọba ipinlẹ naa kede lati san fun gbogbo oṣiṣẹ bii owo iranwọ fun iṣoro ti ọwọn gogo epo bẹntiroo ko ba wọn.
Owo yii ni awọn oṣiṣẹ naa yoo gba fun oṣu mẹfa gbako, lai fi ti ipo ti wọn wa lẹnu iṣẹ ṣe.
Olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa, Kayode Ogundele, lo sọ eleyi nibi ipade awọn aṣoju ijọba ati aṣoju awọn oṣiṣẹ to maa n waye lẹyin ti ipinlẹ naa gba owo ijọba lati ilu Abuja loṣooṣu.
Ogundele wi pe owo naa ni awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ sii gba bi wọn ba ṣe gba owo oṣu kọkanla.
O fikun pe ijọba ipinlẹ naa lo ti n san afikun ẹgbẹrun mẹwa naira fun awọn oṣiṣẹfẹyinti lati ṣe iranwọ fun awọn naa lori inira ti ọwọn gogo owo epo bẹntiro n ko ba wọn.
Awọn ti Osun naa o gbẹyin, bi ko tiẹ to ti Ondo
Ijọba ipinlẹ Osun naa loti kede ekunwo ẹgbẹrun mẹẹdogun fun awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii ọna lati mu adinku ba inira ti wọn doju kọ latari ayọkoru owo iranwọ ori epo.
Ninu atẹjade kan, akọwe iroyin gomina ipinlẹ naa, Olawale Rasheed, wi pe eyi jẹ lara ipinnu gomina Adeleke lati mayedẹrun fawọn oṣiṣẹ.
Rasheed ni “lẹyin idunadura ijọba atawọn oṣiṣẹ nipinlẹ Osun, to fi mọ aṣoju egbẹ awon oṣiṣẹfẹyinti, Gomina Ademola Jackson Nurudeen Adeleke ti buwọ lu sisan ẹgbẹrun mẹẹdogun loṣu fawọn oṣiṣẹ ati ẹgbẹrun mẹwa fawọn oṣiṣẹfẹyinti lati lee mu adinku ba inira ti wọn n dojukọ latari bi ijọba apapọ ṣe yọ owo iranwọ epo bẹntiroo.
“Owo yii ni wọn yoo bẹrẹ sii san loṣu kejila odun 2023, ti wọn yoo si san fun oṣu mẹfa pere”.
Adeleke waa gboriyin fawọn oṣiṣẹ ijọba ati oṣiṣẹfẹyinti nipinlẹ naa fun ifọwọsowọpọ wọn lati lee mu ki ijọba o ṣeto idẹkun fun wọn.
Atẹjade naa fikun pe “a nigbagbọ pe igbesẹ ijọba yii yoo jẹ moriya fun awọn oṣiṣẹ lati lee tẹra mọ iṣẹ wọn”.












